Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Qalam
Súrà Al-Qalam القلم
52 verses · Mecca · revelation order 2
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ نٓ وَٱلْقَلَمِ وَمَا يَسْطُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nūn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.)[1] Allāhu fi gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀ búra.
See all translations of this verse →
مَآ أَنتَ بِنِعْمَةِ رَبِّكَ بِمَجْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
See all translations of this verse →
وَإِنَّ لَكَ لَأَجْرًا غَيْرَ مَمْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
See all translations of this verse →
وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà ńlá (ìwà alápọ̀n-ọ́nlé).
See all translations of this verse →
فَسَتُبْصِرُ وَيُبْصِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
See all translations of this verse →
بِأَييِّكُمُ ٱلْمَفْتُونُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael èwo nínú yín ni aládàn-ánwò (wèrè)?
See all translations of this verse →
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعْلَمُ بِٱلْمُهْتَدِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
See all translations of this verse →
فَلَا تُطِعِ ٱلْمُكَذِّبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
See all translations of this verse →
وَدُّوا۟ لَوْ تُدْهِنُ فَيُدْهِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
See all translations of this verse →
وَلَا تُطِعْ كُلَّ حَلَّافٍ مَّهِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
See all translations of this verse →
هَمَّازٍ مَّشَّآءٍۭ بِنَمِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael abúni, alárìnká tó ń sòfófó kiri,
See all translations of this verse →
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
See all translations of this verse →
عُتُلٍّۭ بَعْدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, ògbólógbòó ẹni ibi (àsáwọ̀[1], ọmọ zina) ni.
See all translations of this verse →
أَن كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
See all translations of this verse →
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”.
See all translations of this verse →
سَنَسِمُهُۥ عَلَى ٱلْخُرْطُومِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
See all translations of this verse →
إِنَّا بَلَوْنَٰهُمْ كَمَا بَلَوْنَآ أَصْحَٰبَ ٱلْجَنَّةِ إِذْ أَقْسَمُوا۟ لَيَصْرِمُنَّهَا مُصْبِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé, dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
See all translations of this verse →
وَلَا يَسْتَثْنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn kò sì ṣe àyàfi pé, “tí Allāhu bá fẹ́”.
See all translations of this verse →
فَطَافَ عَلَيْهَا طَآئِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمْ نَآئِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àdánwò tó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
See all translations of this verse →
فَأَصْبَحَتْ كَٱلصَّرِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
See all translations of this verse →
فَتَنَادَوْا۟ مُصْبِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
See all translations of this verse →
أَنِ ٱغْدُوا۟ عَلَىٰ حَرْثِكُمْ إِن كُنتُمْ صَٰرِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
See all translations of this verse →
فَٱنطَلَقُوا۟ وَهُمْ يَتَخَٰفَتُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
See all translations of this verse →
أَن لَّا يَدْخُلَنَّهَا ٱلْيَوْمَ عَلَيْكُم مِّسْكِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
See all translations of this verse →
وَغَدَوْا۟ عَلَىٰ حَرْدٍ قَٰدِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n jí lọ (sí oko wọn) lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
See all translations of this verse →
فَلَمَّا رَأَوْهَا قَالُوٓا۟ إِنَّا لَضَآلُّونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
See all translations of this verse →
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni.”
See all translations of this verse →
قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹni tó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: “Ṣé èmi kò sọ fún yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé “a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu.)”?
See all translations of this verse →
قَالُوا۟ سُبْحَٰنَ رَبِّنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
See all translations of this verse →
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَلَٰوَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
See all translations of this verse →
قَالُوا۟ يَٰوَيْلَنَآ إِنَّا كُنَّا طَٰغِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu ààlà.
See all translations of this verse →
عَسَىٰ رَبُّنَآ أَن يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِّنْهَآ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا رَٰغِبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí tó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí.”
See all translations of this verse →
كَذَٰلِكَ ٱلْعَذَابُ وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَكْبَرُ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
See all translations of this verse →
أَفَنَجْعَلُ ٱلْمُسْلِمِينَ كَٱلْمُجْرِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
See all translations of this verse →
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?[1]
See all translations of this verse →
أَمْ لَكُمْ كِتَٰبٌ فِيهِ تَدْرُسُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí tírà kan wà fún yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
See all translations of this verse →
إِنَّ لَكُمْ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
See all translations of this verse →
أَمْ لَكُمْ أَيْمَٰنٌ عَلَيْنَا بَٰلِغَةٌ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَٰمَةِ إِنَّ لَكُمْ لَمَا تَحْكُمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: “Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá.”?
See all translations of this verse →
سَلْهُمْ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
See all translations of this verse →
أَمْ لَهُمْ شُرَكَآءُ فَلْيَأْتُوا۟ بِشُرَكَآئِهِمْ إِن كَانُوا۟ صَٰدِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ní (àwọn òrìṣà kan) tí wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Wa? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
See all translations of this verse →
يَوْمَ يُكْشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
See all translations of this verse →
خَٰشِعَةً أَبْصَٰرُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ وَقَدْ كَانُوا۟ يُدْعَوْنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ وَهُمْ سَٰلِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
See all translations of this verse →
فَذَرْنِى وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا ٱلْحَدِيثِ سَنَسْتَدْرِجُهُم مِّنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni tó ń pe ọ̀rọ̀ yìí ní irọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
See all translations of this verse →
وَأُمْلِى لَهُمْ إِنَّ كَيْدِى مَتِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.[1]
See all translations of this verse →
أَمْ تَسْـَٔلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
See all translations of this verse →
أَمْ عِندَهُمُ ٱلْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
See all translations of this verse →
فَٱصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ ٱلْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ مَكْظُومٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
See all translations of this verse →
لَّوْلَآ أَن تَدَٰرَكَهُۥ نِعْمَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ لَنُبِذَ بِٱلْعَرَآءِ وَهُوَ مَذْمُومٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
See all translations of this verse →
فَٱجْتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَجَعَلَهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
See all translations of this verse →
وَإِن يَكَادُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَيُزْلِقُونَكَ بِأَبْصَٰرِهِمْ لَمَّا سَمِعُوا۟ ٱلذِّكْرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُۥ لَمَجْنُونٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: “Dájúdájú wèrè mà ni.”
See all translations of this verse →
وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Mulk
Súrà Al-Haaqqa →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.