caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Mulk الملك

30 verses · Mecca · revelation order 77

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ تَبَٰرَكَ ٱلَّذِى بِيَدِهِ ٱلْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌbùkún ni fún Ẹni tí gbogbo ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلْمَوْتَ وَٱلْحَيَوٰةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْغَفُورُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى خَلَقَ سَبْعَ سَمَٰوَٰتٍ طِبَاقًا مَّا تَرَىٰ فِى خَلْقِ ٱلرَّحْمَٰنِ مِن تَفَٰوُتٍ فَٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?

See all translations of this verse →

ثُمَّ ٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ ٱلْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنْيَا بِمَصَٰبِيحَ وَجَعَلْنَٰهَا رُجُومًا لِّلشَّيَٰطِينِ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ ٱلسَّعِيرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ tó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n. A sì pèsè ìyà Iná tó ń jó sílẹ̀ dè wọ́n.

See all translations of this verse →

وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.

See all translations of this verse →

إِذَآ أُلْقُوا۟ فِيهَا سَمِعُوا۟ لَهَا شَهِيقًا وَهِىَ تَفُورُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí yó sì máa ru sókè.

See all translations of this verse →

تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ ٱلْغَيْظِ كُلَّمَآ أُلْقِىَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَآ أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínu[1]́. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: “Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ بَلَىٰ قَدْ جَآءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ مِن شَىْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِى ضَلَٰلٍ كَبِيرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà tó tóbi.”

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِىٓ أَصْحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n tún wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná tó ń jó.”

See all translations of this verse →

فَٱعْتَرَفُوا۟ بِذَنۢبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná tó ń jó.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِٱلْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

See all translations of this verse →

وَأَسِرُّوا۟ قَوْلَكُمْ أَوِ ٱجْهَرُوا۟ بِهِۦٓ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلْخَبِيرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?[1] Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

See all translations of this verse →

هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ ذَلُولًا فَٱمْشُوا۟ فِى مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا۟ مِن رِّزْقِهِۦ وَإِلَيْهِ ٱلنُّشُورُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.

See all translations of this verse →

ءَأَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ ٱلْأَرْضَ فَإِذَا هِىَ تَمُورُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.

See all translations of this verse →

أَمْ أَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.[1]

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo ní irọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَى ٱلطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَٰٓفَّٰتٍ وَيَقْبِضْنَ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا ٱلرَّحْمَٰنُ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَىْءٍۭ بَصِيرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

أَمَّنْ هَٰذَا ٱلَّذِى هُوَ جُندٌ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ ٱلرَّحْمَٰنِ إِنِ ٱلْكَٰفِرُونَ إِلَّا فِى غُرُورٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTa ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fún yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.

See all translations of this verse →

أَمَّنْ هَٰذَا ٱلَّذِى يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُۥ بَل لَّجُّوا۟ فِى عُتُوٍّ وَنُفُورٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTa ni ẹni tí ó máa pèsè fún yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.

See all translations of this verse →

أَفَمَن يَمْشِى مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِۦٓ أَهْدَىٰٓ أَمَّن يَمْشِى سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni tó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?

See all translations of this verse →

قُلْ هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.”

See all translations of this verse →

قُلْ هُوَ ٱلَّذِى ذَرَأَكُمْ فِى ٱلْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí.”

See all translations of this verse →

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

See all translations of this verse →

قُلْ إِنَّمَا ٱلْعِلْمُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni.”

See all translations of this verse →

فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةً سِيٓـَٔتْ وُجُوهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَقِيلَ هَٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تَدَّعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá rí i tó súnmọ́, ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè.”

See all translations of this verse →

قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِىَ ٱللَّهُ وَمَن مَّعِىَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ ٱلْكَٰفِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

See all translations of this verse →

قُلْ هُوَ ٱلرَّحْمَٰنُ ءَامَنَّا بِهِۦ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِى ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَآؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَآءٍ مَّعِينٍۭ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi tó ń ṣàn wá fún yín?”[1]

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70