caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Haaqqa الحاقة

52 verses · Mecca · revelation order 78

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱلْحَآقَّةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!

See all translations of this verse →

مَا ٱلْحَآقَّةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْحَآقَّةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ ثَمُودُ وَعَادٌۢ بِٱلْقَارِعَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.[1]

See all translations of this verse →

فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهْلِكُوا۟ بِٱلطَّاغِيَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

See all translations of this verse →

وَأَمَّا عَادٌ فَأُهْلِكُوا۟ بِرِيحٍ صَرْصَرٍ عَاتِيَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

See all translations of this verse →

سَخَّرَهَا عَلَيْهِمْ سَبْعَ لَيَالٍ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومًا فَتَرَى ٱلْقَوْمَ فِيهَا صَرْعَىٰ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ خَاوِيَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.[1]

See all translations of this verse →

فَهَلْ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?

See all translations of this verse →

وَجَآءَ فِرْعَوْنُ وَمَن قَبْلَهُۥ وَٱلْمُؤْتَفِكَٰتُ بِٱلْخَاطِئَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.

See all translations of this verse →

فَعَصَوْا۟ رَسُولَ رَبِّهِمْ فَأَخَذَهُمْ أَخْذَةً رَّابِيَةً

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.

See all translations of this verse →

إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلْمَآءُ حَمَلْنَٰكُمْ فِى ٱلْجَارِيَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.

See all translations of this verse →

لِنَجْعَلَهَا لَكُمْ تَذْكِرَةً وَتَعِيَهَآ أُذُنٌ وَٰعِيَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.

See all translations of this verse →

فَإِذَا نُفِخَ فِى ٱلصُّورِ نَفْخَةٌ وَٰحِدَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,

See all translations of this verse →

وَحُمِلَتِ ٱلْأَرْضُ وَٱلْجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةً وَٰحِدَةً

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,

See all translations of this verse →

فَيَوْمَئِذٍ وَقَعَتِ ٱلْوَاقِعَةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.

See all translations of this verse →

وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِىَ يَوْمَئِذٍ وَاهِيَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.

See all translations of this verse →

وَٱلْمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرْجَآئِهَا وَيَحْمِلُ عَرْشَ رَبِّكَ فَوْقَهُمْ يَوْمَئِذٍ ثَمَٰنِيَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.

See all translations of this verse →

يَوْمَئِذٍ تُعْرَضُونَ لَا تَخْفَىٰ مِنكُمْ خَافِيَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).

See all translations of this verse →

فَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقْرَءُوا۟ كِتَٰبِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.

See all translations of this verse →

إِنِّى ظَنَنتُ أَنِّى مُلَٰقٍ حِسَابِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”

See all translations of this verse →

فَهُوَ فِى عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí

See all translations of this verse →

فِى جَنَّةٍ عَالِيَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.

See all translations of this verse →

قُطُوفُهَا دَانِيَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.

See all translations of this verse →

كُلُوا۟ وَٱشْرَبُوا۟ هَنِيٓـًٔۢا بِمَآ أَسْلَفْتُمْ فِى ٱلْأَيَّامِ ٱلْخَالِيَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.

See all translations of this verse →

وَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيْتَنِى لَمْ أُوتَ كِتَٰبِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi![1]

See all translations of this verse →

وَلَمْ أَدْرِ مَا حِسَابِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.

See all translations of this verse →

يَٰلَيْتَهَا كَانَتِ ٱلْقَاضِيَةَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelHáà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).

See all translations of this verse →

مَآ أَغْنَىٰ عَنِّى مَالِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

هَلَكَ عَنِّى سُلْطَٰنِيَهْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAgbára mi sì ti parun.”

See all translations of this verse →

خُذُوهُ فَغُلُّوهُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.

See all translations of this verse →

ثُمَّ ٱلْجَحِيمَ صَلُّوهُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.

See all translations of this verse →

ثُمَّ فِى سِلْسِلَةٍ ذَرْعُهَا سَبْعُونَ ذِرَاعًا فَٱسْلُكُوهُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u[1] ni kí ẹ kì í sí.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.

See all translations of this verse →

وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلْمِسْكِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.

See all translations of this verse →

فَلَيْسَ لَهُ ٱلْيَوْمَ هَٰهُنَا حَمِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.

See all translations of this verse →

وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنْ غِسْلِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.

See all translations of this verse →

لَّا يَأْكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلْخَٰطِـُٔونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

فَلَآ أُقْسِمُ بِمَا تُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra

See all translations of this verse →

وَمَا لَا تُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ohun tí ẹ ò fojú rí.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.[1]

See all translations of this verse →

وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَاعِرٍ قَلِيلًا مَّا تُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَا بِقَوْلِ كَاهِنٍ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

See all translations of this verse →

تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

وَلَوْ تَقَوَّلَ عَلَيْنَا بَعْضَ ٱلْأَقَاوِيلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,

See all translations of this verse →

لَأَخَذْنَا مِنْهُ بِٱلْيَمِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.

See all translations of this verse →

ثُمَّ لَقَطَعْنَا مِنْهُ ٱلْوَتِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.

See all translations of this verse →

فَمَا مِنكُم مِّنْ أَحَدٍ عَنْهُ حَٰجِزِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَتَذْكِرَةٌ لِّلْمُتَّقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

وَإِنَّا لَنَعْلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَحَسْرَةٌ عَلَى ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلْيَقِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.

See all translations of this verse →

فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70