caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Hijr الحجر

99 verses · Mecca · revelation order 54

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ الٓر تِلْكَ ءَايَٰتُ ٱلْكِتَٰبِ وَقُرْءَانٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

رُّبَمَا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْ كَانُوا۟ مُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).

See all translations of this verse →

ذَرْهُمْ يَأْكُلُوا۟ وَيَتَمَتَّعُوا۟ وَيُلْهِهِمُ ٱلْأَمَلُ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَّعْلُومٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.

See all translations of this verse →

مَّا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَـْٔخِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِى نُزِّلَ عَلَيْهِ ٱلذِّكْرُ إِنَّكَ لَمَجْنُونٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ìwọ tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ọ́.

See all translations of this verse →

لَّوْ مَا تَأْتِينَا بِٱلْمَلَٰٓئِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”

See all translations of this verse →

مَا نُنَزِّلُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةَ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَمَا كَانُوٓا۟ إِذًا مُّنظَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).

See all translations of this verse →

إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا ٱلذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ فِى شِيَعِ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

See all translations of this verse →

وَمَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

See all translations of this verse →

كَذَٰلِكَ نَسْلُكُهُۥ فِى قُلُوبِ ٱلْمُجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn náà ni A ṣe máa fi (àìsàn pípe al-Ƙur'ān nírọ́) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (nínú ìjọ tìrẹ náà).

See all translations of this verse →

لَا يُؤْمِنُونَ بِهِۦ وَقَدْ خَلَتْ سُنَّةُ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò níí gbà á gbọ́; ìṣe (Allāhu[1] lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.

See all translations of this verse →

وَلَوْ فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَظَلُّوا۟ فِيهِ يَعْرُجُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),

See all translations of this verse →

لَقَالُوٓا۟ إِنَّمَا سُكِّرَتْ أَبْصَٰرُنَا بَلْ نَحْنُ قَوْمٌ مَّسْحُورُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kan fi n̄ǹkan bo ojú wa ni. Rárá, ènìyàn tí wọ́n ń dan ni àwa sẹ́.”

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ جَعَلْنَا فِى ٱلسَّمَآءِ بُرُوجًا وَزَيَّنَّٰهَا لِلنَّٰظِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.

See all translations of this verse →

وَحَفِظْنَٰهَا مِن كُلِّ شَيْطَٰنٍ رَّجِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ṣọ́ ọ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.[1]

See all translations of this verse →

إِلَّا مَنِ ٱسْتَرَقَ ٱلسَّمْعَ فَأَتْبَعَهُۥ شِهَابٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀfi (ṣaetọ̄n) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.

See all translations of this verse →

وَٱلْأَرْضَ مَدَدْنَٰهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ وَأَنۢبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَىْءٍ مَّوْزُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIlẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا لَكُمْ فِيهَا مَعَٰيِشَ وَمَن لَّسْتُمْ لَهُۥ بِرَٰزِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.

See all translations of this verse →

وَإِن مِّن شَىْءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَآئِنُهُۥ وَمَا نُنَزِّلُهُۥٓ إِلَّا بِقَدَرٍ مَّعْلُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.

See all translations of this verse →

وَأَرْسَلْنَا ٱلرِّيَٰحَ لَوَٰقِحَ فَأَنزَلْنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَسْقَيْنَٰكُمُوهُ وَمَآ أَنتُمْ لَهُۥ بِخَٰزِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A rán àwọn atẹ́gùn láti kó àwọn ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fún yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).

See all translations of this verse →

وَإِنَّا لَنَحْنُ نُحْىِۦ وَنُمِيتُ وَنَحْنُ ٱلْوَٰرِثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa, Àwa ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ عَلِمْنَا ٱلْمُسْتَقْدِمِينَ مِنكُمْ وَلَقَدْ عَلِمْنَا ٱلْمُسْتَـْٔخِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحْشُرُهُمْ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ مِن صَلْصَٰلٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.

See all translations of this verse →

وَٱلْجَآنَّ خَلَقْنَٰهُ مِن قَبْلُ مِن نَّارِ ٱلسَّمُومِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.

See all translations of this verse →

وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّى خَٰلِقٌۢ بَشَرًا مِّن صَلْصَٰلٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.

See all translations of this verse →

فَإِذَا سَوَّيْتُهُۥ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِى فَقَعُوا۟ لَهُۥ سَٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí Mo bá ṣe é tó gún régétán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni.”[1]

See all translations of this verse →

فَسَجَدَ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.

See all translations of this verse →

إِلَّآ إِبْلِيسَ أَبَىٰٓ أَن يَكُونَ مَعَ ٱلسَّٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni náà.

See all translations of this verse →

قَالَ يَٰٓإِبْلِيسُ مَا لَكَ أَلَّا تَكُونَ مَعَ ٱلسَّٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí ló dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni?”

See all translations of this verse →

قَالَ لَمْ أَكُن لِّأَسْجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقْتَهُۥ مِن صَلْصَٰلٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wí pé: “Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَٱخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ عَلَيْكَ ٱللَّعْنَةَ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِىٓ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ tí wọ́n máa gbé ẹ̀dá dìde.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلْمُنظَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára

See all translations of this verse →

إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْوَقْتِ ٱلْمَعْلُومِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltítí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ.”[1]

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ بِمَآ أَغْوَيْتَنِى لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wí pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù

See all translations of this verse →

إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ ٱلْمُخْلَصِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàfi àwọn ẹrúsìn Rẹ nínú wọn, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”[1]

See all translations of this verse →

قَالَ هَٰذَا صِرَٰطٌ عَلَىَّ مُسْتَقِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Mi.”

See all translations of this verse →

إِنَّ عِبَادِى لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَٰنٌ إِلَّا مَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلْغَاوِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوْعِدُهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.

See all translations of this verse →

لَهَا سَبْعَةُ أَبْوَٰبٍ لِّكُلِّ بَابٍ مِّنْهُمْ جُزْءٌ مَّقْسُومٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).

See all translations of this verse →

ٱدْخُلُوهَا بِسَلَٰمٍ ءَامِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”

See all translations of this verse →

وَنَزَعْنَا مَا فِى صُدُورِهِم مِّنْ غِلٍّ إِخْوَٰنًا عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَٰبِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn tó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.

See all translations of this verse →

لَا يَمَسُّهُمْ فِيهَا نَصَبٌ وَمَا هُم مِّنْهَا بِمُخْرَجِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

نَبِّئْ عِبَادِىٓ أَنِّىٓ أَنَا ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَأَنَّ عَذَابِى هُوَ ٱلْعَذَابُ ٱلْأَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

See all translations of this verse →

وَنَبِّئْهُمْ عَن ضَيْفِ إِبْرَٰهِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.

See all translations of this verse →

إِذْ دَخَلُوا۟ عَلَيْهِ فَقَالُوا۟ سَلَٰمًا قَالَ إِنَّا مِنكُمْ وَجِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ لَا تَوْجَلْ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ أَبَشَّرْتُمُونِى عَلَىٰٓ أَن مَّسَّنِىَ ٱلْكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ بَشَّرْنَٰكَ بِٱلْحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلْقَٰنِطِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”

See all translations of this verse →

قَالَ وَمَن يَقْنَطُ مِن رَّحْمَةِ رَبِّهِۦٓ إِلَّا ٱلضَّآلُّونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا ٱلْمُرْسَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ إِنَّآ أُرْسِلْنَآ إِلَىٰ قَوْمٍ مُّجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.

See all translations of this verse →

إِلَّآ ءَالَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱمْرَأَتَهُۥ قَدَّرْنَآ إِنَّهَا لَمِنَ ٱلْغَٰبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَ ءَالَ لُوطٍ ٱلْمُرْسَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,

See all translations of this verse →

قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ بَلْ جِئْنَٰكَ بِمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَمْتَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَأَتَيْنَٰكَ بِٱلْحَقِّ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.

See all translations of this verse →

فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِّنَ ٱلَّيْلِ وَٱتَّبِعْ أَدْبَٰرَهُمْ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنكُمْ أَحَدٌ وَٱمْضُوا۟ حَيْثُ تُؤْمَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fún yín.”

See all translations of this verse →

وَقَضَيْنَآ إِلَيْهِ ذَٰلِكَ ٱلْأَمْرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰٓؤُلَآءِ مَقْطُوعٌ مُّصْبِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.

See all translations of this verse →

وَجَآءَ أَهْلُ ٱلْمَدِينَةِ يَسْتَبْشِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.

See all translations of this verse →

قَالَ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ ضَيْفِى فَلَا تَفْضَحُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.

See all translations of this verse →

وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَلَا تُخْزُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ أَوَلَمْ نَنْهَكَ عَنِ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”

See all translations of this verse →

قَالَ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِىٓ إِن كُنتُمْ فَٰعِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”[1]

See all translations of this verse →

لَعَمْرُكَ إِنَّهُمْ لَفِى سَكْرَتِهِمْ يَعْمَهُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra;[1] dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìṣìnà àti àìmọ̀kan wọn, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”

See all translations of this verse →

فَأَخَذَتْهُمُ ٱلصَّيْحَةُ مُشْرِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.

See all translations of this verse →

فَجَعَلْنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِّن سِجِّيلٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّلْمُتَوَسِّمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٍ مُّقِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِن كَانَ أَصْحَٰبُ ٱلْأَيْكَةِ لَظَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ará ’Aekah[1] náà jẹ́ alábòsí.

See all translations of this verse →

فَٱنتَقَمْنَا مِنْهُمْ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì ló kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ كَذَّبَ أَصْحَٰبُ ٱلْحِجْرِ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

وَءَاتَيْنَٰهُمْ ءَايَٰتِنَا فَكَانُوا۟ عَنْهَا مُعْرِضِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.

See all translations of this verse →

وَكَانُوا۟ يَنْحِتُونَ مِنَ ٱلْجِبَالِ بُيُوتًا ءَامِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.

See all translations of this verse →

فَأَخَذَتْهُمُ ٱلصَّيْحَةُ مُصْبِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.

See all translations of this verse →

فَمَآ أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

See all translations of this verse →

وَمَا خَلَقْنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَإِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَـَٔاتِيَةٌ فَٱصْفَحِ ٱلصَّفْحَ ٱلْجَمِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò tó rẹwà.

See all translations of this verse →

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلْخَلَّٰقُ ٱلْعَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَٰكَ سَبْعًا مِّنَ ٱلْمَثَانِى وَٱلْقُرْءَانَ ٱلْعَظِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān Ńlá.

See all translations of this verse →

لَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِۦٓ أَزْوَٰجًا مِّنْهُمْ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَٱخْفِضْ جَنَاحَكَ لِلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ méjèèjì wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé fún oríṣiríṣi àwọn kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَقُلْ إِنِّىٓ أَنَا ٱلنَّذِيرُ ٱلْمُبِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

كَمَآ أَنزَلْنَا عَلَى ٱلْمُقْتَسِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn tó ń pín òdodo mọ́ irọ́;

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ جَعَلُوا۟ ٱلْقُرْءَانَ عِضِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,[1]

See all translations of this verse →

فَوَرَبِّكَ لَنَسْـَٔلَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè

See all translations of this verse →

عَمَّا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

فَٱصْدَعْ بِمَا تُؤْمَرُ وَأَعْرِضْ عَنِ ٱلْمُشْرِكِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.

See all translations of this verse →

إِنَّا كَفَيْنَٰكَ ٱلْمُسْتَهْزِءِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَجْعَلُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدْرُكَ بِمَا يَقُولُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.

See all translations of this verse →

فَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ وَكُن مِّنَ ٱلسَّٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ.[1] Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).

See all translations of this verse →

وَٱعْبُدْ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأْتِيَكَ ٱلْيَقِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelJọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70