Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà An-Nahl
Súrà An-Nahl النحل
128 verses · Mecca · revelation order 70
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ أَتَىٰٓ أَمْرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسْتَعْجِلُوهُ سُبْحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
See all translations of this verse →
يُنَزِّلُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنْ أَمْرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنْ عِبَادِهِۦٓ أَنْ أَنذِرُوٓا۟ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”
See all translations of this verse →
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِٱلْحَقِّ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
See all translations of this verse →
خَلَقَ ٱلْإِنسَٰنَ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde).
See all translations of this verse →
وَٱلْأَنْعَٰمَ خَلَقَهَا لَكُمْ فِيهَا دِفْءٌ وَمَنَٰفِعُ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn (fún yín). Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fún yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn.
See all translations of this verse →
وَلَكُمْ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسْرَحُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fún yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko.[1]
See all translations of this verse →
وَتَحْمِلُ أَثْقَالَكُمْ إِلَىٰ بَلَدٍ لَّمْ تَكُونُوا۟ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلْأَنفُسِ إِنَّ رَبَّكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín tó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ kò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
See all translations of this verse →
وَٱلْخَيْلَ وَٱلْبِغَالَ وَٱلْحَمِيرَ لِتَرْكَبُوهَا وَزِينَةً وَيَخْلُقُ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ kò mọ̀.
See all translations of this verse →
وَعَلَى ٱللَّهِ قَصْدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنْهَا جَآئِرٌ وَلَوْ شَآءَ لَهَدَىٰكُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀)[1]. Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām).
See all translations of this verse →
هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً لَّكُم مِّنْهُ شَرَابٌ وَمِنْهُ شَجَرٌ فِيهِ تُسِيمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ (fún yín) láti sánmọ̀. Mímu wà fún yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀, tí ẹ fi ń bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn.
See all translations of this verse →
يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرْعَ وَٱلزَّيْتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلْأَعْنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fún yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
See all translations of this verse →
وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتٌۢ بِأَمْرِهِۦٓ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
See all translations of this verse →
وَمَا ذَرَأَ لَكُمْ فِى ٱلْأَرْضِ مُخْتَلِفًا أَلْوَٰنُهُۥٓ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَذَّكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fún yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń lo ìrántí.
See all translations of this verse →
وَهُوَ ٱلَّذِى سَخَّرَ ٱلْبَحْرَ لِتَأْكُلُوا۟ مِنْهُ لَحْمًا طَرِيًّا وَتَسْتَخْرِجُوا۟ مِنْهُ حِلْيَةً تَلْبَسُونَهَا وَتَرَى ٱلْفُلْكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا۟ مِن فَضْلِهِۦ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òun ni Ẹni tí Ó rọ odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - o sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ - àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn oore àjùlọ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
See all translations of this verse →
وَأَلْقَىٰ فِى ٱلْأَرْضِ رَوَٰسِىَ أَن تَمِيدَ بِكُمْ وَأَنْهَٰرًا وَسُبُلًا لَّعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má baà mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀;
See all translations of this verse →
وَعَلَٰمَٰتٍ وَبِٱلنَّجْمِ هُمْ يَهْتَدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́).[1]
See all translations of this verse →
أَفَمَن يَخْلُقُ كَمَن لَّا يَخْلُقُ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
See all translations of this verse →
وَإِن تَعُدُّوا۟ نِعْمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحْصُوهَآ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعْلِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخْلُقُونَ شَيْـًٔا وَهُمْ يُخْلَقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
See all translations of this verse →
أَمْوَٰتٌ غَيْرُ أَحْيَآءٍ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.[1] Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò jí wọn dìde (nínú sàréè).
See all translations of this verse →
إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَٰحِدٌ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱلْـَٔاخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٌ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga.
See all translations of this verse →
لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلْمُسْتَكْبِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
See all translations of this verse →
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمْ قَالُوٓا۟ أَسَٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
See all translations of this verse →
لِيَحْمِلُوٓا۟ أَوْزَارَهُمْ كَامِلَةً يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ وَمِنْ أَوْزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيْرِ عِلْمٍ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú.[1]
See all translations of this verse →
قَدْ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنْيَٰنَهُم مِّنَ ٱلْقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيْهِمُ ٱلسَّقْفُ مِن فَوْقِهِمْ وَأَتَىٰهُمُ ٱلْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó látibi àwọn òpó ilé. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
See all translations of this verse →
ثُمَّ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ يُخْزِيهِمْ وَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَآءِىَ ٱلَّذِينَ كُنتُمْ تُشَٰٓقُّونَ فِيهِمْ قَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْعِلْمَ إِنَّ ٱلْخِزْىَ ٱلْيَوْمَ وَٱلسُّوٓءَ عَلَى ٱلْكَٰفِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tìtorí wọn yapa (ọ̀rọ̀ Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِىٓ أَنفُسِهِمْ فَأَلْقَوُا۟ ٱلسَّلَمَ مَا كُنَّا نَعْمَلُ مِن سُوٓءٍۭ بَلَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Bẹ́ẹ̀ ni (irọ́ lẹ́pa)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
فَٱدْخُلُوٓا۟ أَبْوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَا فَلَبِئْسَ مَثْوَى ٱلْمُتَكَبِّرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
See all translations of this verse →
وَقِيلَ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ مَاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمْ قَالُوا۟ خَيْرًا لِّلَّذِينَ أَحْسَنُوا۟ فِى هَٰذِهِ ٱلدُّنْيَا حَسَنَةٌ وَلَدَارُ ٱلْـَٔاخِرَةِ خَيْرٌ وَلَنِعْمَ دَارُ ٱلْمُتَّقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára.
See all translations of this verse →
جَنَّٰتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ لَهُمْ فِيهَا مَا يَشَآءُونَ كَذَٰلِكَ يَجْزِى ٱللَّهُ ٱلْمُتَّقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra 'Adn ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَٰمٌ عَلَيْكُمُ ٱدْخُلُوا۟ ٱلْجَنَّةَ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fún yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
See all translations of this verse →
هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأْتِيَهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ أَوْ يَأْتِىَ أَمْرُ رَبِّكَ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
See all translations of this verse →
فَأَصَابَهُمْ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُوا۟ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
See all translations of this verse →
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أَشْرَكُوا۟ لَوْ شَآءَ ٱللَّهُ مَا عَبَدْنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَىْءٍ نَّحْنُ وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمْنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَىْءٍ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَهَلْ عَلَى ٱلرُّسُلِ إِلَّا ٱلْبَلَٰغُ ٱلْمُبِينُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِى كُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولًا أَنِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَٱجْتَنِبُوا۟ ٱلطَّٰغُوتَ فَمِنْهُم مَّنْ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنْهُم مَّنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ ٱلضَّلَٰلَةُ فَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَٱنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلْمُكَذِّبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn tó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí?
See all translations of this verse →
إِن تَحْرِصْ عَلَىٰ هُدَىٰهُمْ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى مَن يُضِلُّ وَمَا لَهُم مِّن نَّٰصِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, dájúdájú Allāhu, ẹni tí Ó bá ṣì lọ́nà, kò níí mọ̀nà,[1] kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn.
See all translations of this verse →
وَأَقْسَمُوا۟ بِٱللَّهِ جَهْدَ أَيْمَٰنِهِمْ لَا يَبْعَثُ ٱللَّهُ مَن يَمُوتُ بَلَىٰ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Bẹ́ẹ̀ ni, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀.
See all translations of this verse →
لِيُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِى يَخْتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعْلَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَنَّهُمْ كَانُوا۟ كَٰذِبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́.
See all translations of this verse →
إِنَّمَا قَوْلُنَا لِشَىْءٍ إِذَآ أَرَدْنَٰهُ أَن نَّقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُوا۟ فِى ٱللَّهِ مِنۢ بَعْدِ مَا ظُلِمُوا۟ لَنُبَوِّئَنَّهُمْ فِى ٱلدُّنْيَا حَسَنَةً وَلَأَجْرُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَكْبَرُ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀ ni.
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ صَبَرُوا۟ وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
See all translations of this verse →
وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِىٓ إِلَيْهِمْ فَسْـَٔلُوٓا۟ أَهْلَ ٱلذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.[1]
See all translations of this verse →
بِٱلْبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِ وَأَنزَلْنَآ إِلَيْكَ ٱلذِّكْرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيْهِمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (A fi) àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn[1] àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
See all translations of this verse →
أَفَأَمِنَ ٱلَّذِينَ مَكَرُوا۟ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَخْسِفَ ٱللَّهُ بِهِمُ ٱلْأَرْضَ أَوْ يَأْتِيَهُمُ ٱلْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé àwọn tó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura?
See all translations of this verse →
أَوْ يَأْخُذَهُمْ فِى تَقَلُّبِهِمْ فَمَا هُم بِمُعْجِزِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́.
See all translations of this verse →
أَوْ يَأْخُذَهُمْ عَلَىٰ تَخَوُّفٍ فَإِنَّ رَبَّكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni?[1] Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
See all translations of this verse →
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَىْءٍ يَتَفَيَّؤُا۟ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلْيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدًا لِّلَّهِ وَهُمْ دَٰخِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé ṣé wọn kò wòye sí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì[1] tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)?
See all translations of this verse →
وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ مِن دَآبَّةٍ وَٱلْمَلَٰٓئِكَةُ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga.[1]
See all translations of this verse →
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوْقِهِمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n ń páyà Olúwa wọn tó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn.[1]
See all translations of this verse →
وَقَالَ ٱللَّهُ لَا تَتَّخِذُوٓا۟ إِلَٰهَيْنِ ٱثْنَيْنِ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٌ وَٰحِدٌ فَإِيَّٰىَ فَٱرْهَبُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”
See all translations of this verse →
وَلَهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَلَهُ ٱلدِّينُ وَاصِبًا أَفَغَيْرَ ٱللَّهِ تَتَّقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael TiRẹ̀ sì ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni (àfọ̀mọ́) ẹ̀sìn títí láéláé[1] Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni?
See all translations of this verse →
وَمَا بِكُم مِّن نِّعْمَةٍ فَمِنَ ٱللَّهِ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فَإِلَيْهِ تَجْـَٔرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni ẹ̀ ń ké pè (fún ìdáǹdè.)
See all translations of this verse →
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ ٱلضُّرَّ عَنكُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِّنكُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá mú ìnira náà kúrò fún yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
See all translations of this verse →
لِيَكْفُرُوا۟ بِمَآ ءَاتَيْنَٰهُمْ فَتَمَتَّعُوا۟ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
See all translations of this verse →
وَيَجْعَلُونَ لِمَا لَا يَعْلَمُونَ نَصِيبًا مِّمَّا رَزَقْنَٰهُمْ تَٱللَّهِ لَتُسْـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمْ تَفْتَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò nímọ̀ nípa rẹ̀.[1] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
See all translations of this verse →
وَيَجْعَلُونَ لِلَّهِ ٱلْبَنَٰتِ سُبْحَٰنَهُۥ وَلَهُم مَّا يَشْتَهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). - Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
See all translations of this verse →
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِٱلْأُنثَىٰ ظَلَّ وَجْهُهُۥ مُسْوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò di dúdú fún ìbànújẹ́, tí ó sì máa pa á mọ́ra.
See all translations of this verse →
يَتَوَٰرَىٰ مِنَ ٱلْقَوْمِ مِن سُوٓءِ مَا بُشِّرَ بِهِۦٓ أَيُمْسِكُهُۥ عَلَىٰ هُونٍ أَمْ يَدُسُّهُۥ فِى ٱلتُّرَابِ أَلَا سَآءَ مَا يَحْكُمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà a mú ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú!
See all translations of this verse →
لِلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱلْـَٔاخِرَةِ مَثَلُ ٱلسَّوْءِ وَلِلَّهِ ٱلْمَثَلُ ٱلْأَعْلَىٰ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé tó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
See all translations of this verse →
وَلَوْ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِظُلْمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيْهَا مِن دَآبَّةٍ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمْ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمْ لَا يَسْتَـْٔخِرُونَ سَاعَةً وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí lè sún un sẹ́yìn di àkókò kan, wọn kò sì níí lè sún un síwájú.”[1]
See all translations of this verse →
وَيَجْعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكْرَهُونَ وَتَصِفُ أَلْسِنَتُهُمُ ٱلْكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ ٱلْحُسْنَىٰ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ ٱلنَّارَ وَأَنَّهُم مُّفْرَطُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) - n̄ǹkan tí wọn kórira - lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
See all translations of this verse →
تَٱللَّهِ لَقَدْ أَرْسَلْنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٍ مِّن قَبْلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيْطَٰنُ أَعْمَٰلَهُمْ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ ٱلْيَوْمَ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu fi ara Rẹ̀ búra,[1] dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn ní òní. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
See all translations of this verse →
وَمَآ أَنزَلْنَا عَلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِى ٱخْتَلَفُوا۟ فِيهِ وَهُدًى وَرَحْمَةً لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí;[1] ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَحْيَا بِهِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَآ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
See all translations of this verse →
وَإِنَّ لَكُمْ فِى ٱلْأَنْعَٰمِ لَعِبْرَةً نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِى بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَّبَنًا خَالِصًا سَآئِغًا لِّلشَّٰرِبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fún yín mu nínú n̄ǹkan tó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ tó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn tó ń mu ún.
See all translations of this verse →
وَمِن ثَمَرَٰتِ ٱلنَّخِيلِ وَٱلْأَعْنَٰبِ تَتَّخِذُونَ مِنْهُ سَكَرًا وَرِزْقًا حَسَنًا إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí[1] àti n̄ǹkan jíjẹ-mímu tó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
See all translations of this verse →
وَأَوْحَىٰ رَبُّكَ إِلَى ٱلنَّحْلِ أَنِ ٱتَّخِذِى مِنَ ٱلْجِبَالِ بُيُوتًا وَمِنَ ٱلشَّجَرِ وَمِمَّا يَعْرِشُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Olúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: “Mu ilé sínú àpáta, (mú un sínú) igi, (kí ó sì mú un) sínú ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga.
See all translations of this verse →
ثُمَّ كُلِى مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ فَٱسْلُكِى سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلًا يَخْرُجُ مِنۢ بُطُونِهَا شَرَابٌ مُّخْتَلِفٌ أَلْوَٰنُهُۥ فِيهِ شِفَآءٌ لِّلنَّاسِ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba.” Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمْ ثُمَّ يَتَوَفَّىٰكُمْ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرْذَلِ ٱلْعُمُرِ لِكَىْ لَا يَعْلَمَ بَعْدَ عِلْمٍ شَيْـًٔا إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ قَدِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعْضَكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ فِى ٱلرِّزْقِ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُوا۟ بِرَآدِّى رِزْقِهِمْ عَلَىٰ مَا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُهُمْ فَهُمْ فِيهِ سَوَآءٌ أَفَبِنِعْمَةِ ٱللَّهِ يَجْحَدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Bẹ́ẹ̀, àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, wọn kì í fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, nítorí kí wọ́n má baà wà ní dọ́gban̄dọ́gba pẹ̀lú wọn níbi arísìkí![1] Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَٰجًا وَجَعَلَ لَكُم مِّنْ أَزْوَٰجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةً وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ أَفَبِٱلْبَٰطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَتِ ٱللَّهِ هُمْ يَكْفُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fún yín láti ara yín. Ó fún yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yó sì máa ṣàì moore sí?
See all translations of this verse →
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَمْلِكُ لَهُمْ رِزْقًا مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ شَيْـًٔا وَلَا يَسْتَطِيعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
See all translations of this verse →
فَلَا تَضْرِبُوا۟ لِلَّهِ ٱلْأَمْثَالَ إِنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn aláfijọ kan lélẹ̀ pé wọ́n jọ Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
See all translations of this verse →
ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا عَبْدًا مَّمْلُوكًا لَّا يَقْدِرُ عَلَىٰ شَىْءٍ وَمَن رَّزَقْنَٰهُ مِنَّا رِزْقًا حَسَنًا فَهُوَ يُنفِقُ مِنْهُ سِرًّا وَجَهْرًا هَلْ يَسْتَوُۥنَ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí tó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí?[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
See all translations of this verse →
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا رَّجُلَيْنِ أَحَدُهُمَآ أَبْكَمُ لَا يَقْدِرُ عَلَىٰ شَىْءٍ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوْلَىٰهُ أَيْنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأْتِ بِخَيْرٍ هَلْ يَسْتَوِى هُوَ وَمَن يَأْمُرُ بِٱلْعَدْلِ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà?[1]
See all translations of this verse →
وَلِلَّهِ غَيْبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَآ أَمْرُ ٱلسَّاعَةِ إِلَّا كَلَمْحِ ٱلْبَصَرِ أَوْ هُوَ أَقْرَبُ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ أَخْرَجَكُم مِّنۢ بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمْ لَا تَعْلَمُونَ شَيْـًٔا وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
See all translations of this verse →
أَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَى ٱلطَّيْرِ مُسَخَّرَٰتٍ فِى جَوِّ ٱلسَّمَآءِ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا ٱللَّهُ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni tó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمْ سَكَنًا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلْأَنْعَٰمِ بُيُوتًا تَسْتَخِفُّونَهَا يَوْمَ ظَعْنِكُمْ وَيَوْمَ إِقَامَتِكُمْ وَمِنْ أَصْوَافِهَا وَأَوْبَارِهَا وَأَشْعَارِهَآ أَثَٰثًا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ṣe ibùsinmi fún yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan tó fúyẹ́ fún yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn,[1] irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلًا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلْجِبَالِ أَكْنَٰنًا وَجَعَلَ لَكُمْ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلْحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأْسَكُمْ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعْمَتَهُۥ عَلَيْكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْلِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ṣe àwọn ibòji fún yín láti ara àwọn n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fún yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fún yín tó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ tó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín.[1] Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí.
See all translations of this verse →
فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَإِنَّمَا عَلَيْكَ ٱلْبَلَٰغُ ٱلْمُبِينُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe tìrẹ.
See all translations of this verse →
يَعْرِفُونَ نِعْمَتَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكْثَرُهُمُ ٱلْكَٰفِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore.
See all translations of this verse →
وَيَوْمَ نَبْعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا ثُمَّ لَا يُؤْذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
See all translations of this verse →
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ ٱلْعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí àwọn tó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí lọ́ wọn lára láti wọ (inú Iná).
See all translations of this verse →
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ أَشْرَكُوا۟ شُرَكَآءَهُمْ قَالُوا۟ رَبَّنَا هَٰٓؤُلَآءِ شُرَكَآؤُنَا ٱلَّذِينَ كُنَّا نَدْعُوا۟ مِن دُونِكَ فَأَلْقَوْا۟ إِلَيْهِمُ ٱلْقَوْلَ إِنَّكُمْ لَكَٰذِبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí àwọn tó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”
See all translations of this verse →
وَأَلْقَوْا۟ إِلَى ٱللَّهِ يَوْمَئِذٍ ٱلسَّلَمَ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1]
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ زِدْنَٰهُمْ عَذَابًا فَوْقَ ٱلْعَذَابِ بِمَا كَانُوا۟ يُفْسِدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn ni nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
See all translations of this verse →
وَيَوْمَ نَبْعَثُ فِى كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا عَلَيْهِم مِّنْ أَنفُسِهِمْ وَجِئْنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ تِبْيَٰنًا لِّكُلِّ شَىْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً وَبُشْرَىٰ لِلْمُسْلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan,[1] ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱللَّهَ يَأْمُرُ بِٱلْعَدْلِ وَٱلْإِحْسَٰنِ وَإِيتَآئِ ذِى ٱلْقُرْبَىٰ وَيَنْهَىٰ عَنِ ٱلْفَحْشَآءِ وَٱلْمُنكَرِ وَٱلْبَغْىِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
See all translations of this verse →
وَأَوْفُوا۟ بِعَهْدِ ٱللَّهِ إِذَا عَٰهَدتُّمْ وَلَا تَنقُضُوا۟ ٱلْأَيْمَٰنَ بَعْدَ تَوْكِيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ ٱللَّهَ عَلَيْكُمْ كَفِيلًا إِنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَلَا تَكُونُوا۟ كَٱلَّتِى نَقَضَتْ غَزْلَهَا مِنۢ بَعْدِ قُوَّةٍ أَنكَٰثًا تَتَّخِذُونَ أَيْمَٰنَكُمْ دَخَلًۢا بَيْنَكُمْ أَن تَكُونَ أُمَّةٌ هِىَ أَرْبَىٰ مِنْ أُمَّةٍ إِنَّمَا يَبْلُوكُمُ ٱللَّهُ بِهِۦ وَلَيُبَيِّنَنَّ لَكُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ مَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fún yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
See all translations of this verse →
وَلَوْ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَٰحِدَةً وَلَٰكِن يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ وَلَتُسْـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَلَا تَتَّخِذُوٓا۟ أَيْمَٰنَكُمْ دَخَلًۢا بَيْنَكُمْ فَتَزِلَّ قَدَمٌۢ بَعْدَ ثُبُوتِهَا وَتَذُوقُوا۟ ٱلسُّوٓءَ بِمَا صَدَدتُّمْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَكُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fún yín.
See all translations of this verse →
وَلَا تَشْتَرُوا۟ بِعَهْدِ ٱللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا إِنَّمَا عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
See all translations of this verse →
مَا عِندَكُمْ يَنفَدُ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ بَاقٍ وَلَنَجْزِيَنَّ ٱلَّذِينَ صَبَرُوٓا۟ أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun tó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa san àwọn tó ṣe sùúrù ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
مَنْ عَمِلَ صَٰلِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَنُحْيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةً طَيِّبَةً وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
فَإِذَا قَرَأْتَ ٱلْقُرْءَانَ فَٱسْتَعِذْ بِٱللَّهِ مِنَ ٱلشَّيْطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ لَيْسَ لَهُۥ سُلْطَٰنٌ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn tó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
See all translations of this verse →
إِنَّمَا سُلْطَٰنُهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَوَلَّوْنَهُۥ وَٱلَّذِينَ هُم بِهِۦ مُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹni tí (aṣ-Ṣaetọ̄n) lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn tó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn tó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu.
See all translations of this verse →
وَإِذَا بَدَّلْنَآ ءَايَةً مَّكَانَ ءَايَةٍ وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُنَزِّلُ قَالُوٓا۟ إِنَّمَآ أَنتَ مُفْتَرٍۭ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.
See all translations of this verse →
قُلْ نَزَّلَهُۥ رُوحُ ٱلْقُدُسِ مِن رَّبِّكَ بِٱلْحَقِّ لِيُثَبِّتَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَهُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُسْلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ló sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ pẹ̀lú òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّهُمْ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُۥ بَشَرٌ لِّسَانُ ٱلَّذِى يُلْحِدُونَ إِلَيْهِ أَعْجَمِىٌّ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِىٌّ مُّبِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan ló ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń darí al-Ƙur’ān kọ ní ọ̀nà òdì (pé ó ń kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí.[1]
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَا يَهْدِيهِمُ ٱللَّهُ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
See all translations of this verse →
إِنَّمَا يَفْتَرِى ٱلْكَذِبَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْكَٰذِبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu ló ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni òpùrọ́.
See all translations of this verse →
مَن كَفَرَ بِٱللَّهِ مِنۢ بَعْدِ إِيمَٰنِهِۦٓ إِلَّا مَنْ أُكْرِهَ وَقَلْبُهُۥ مُطْمَئِنٌّۢ بِٱلْإِيمَٰنِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِٱلْكُفْرِ صَدْرًا فَعَلَيْهِمْ غَضَبٌ مِّنَ ٱللَّهِ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣí igbá-àyà rẹ̀ sílẹ̀ fún àìgbàgbọ́, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
See all translations of this verse →
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱسْتَحَبُّوا۟ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا عَلَى ٱلْـَٔاخِرَةِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْكَٰفِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
See all translations of this verse →
أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَسَمْعِهِمْ وَأَبْصَٰرِهِمْ وَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْغَٰفِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni afọ́núfọ́ra.
See all translations of this verse →
لَا جَرَمَ أَنَّهُمْ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ هُمُ ٱلْخَٰسِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run.
See all translations of this verse →
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُوا۟ مِنۢ بَعْدِ مَا فُتِنُوا۟ ثُمَّ جَٰهَدُوا۟ وَصَبَرُوٓا۟ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́).
See all translations of this verse →
يَوْمَ تَأْتِى كُلُّ نَفْسٍ تُجَٰدِلُ عَن نَّفْسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé tí yóò máa rojọ́ gbe ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
See all translations of this verse →
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا قَرْيَةً كَانَتْ ءَامِنَةً مُّطْمَئِنَّةً يَأْتِيهَا رِزْقُهَا رَغَدًا مِّن كُلِّ مَكَانٍ فَكَفَرَتْ بِأَنْعُمِ ٱللَّهِ فَأَذَٰقَهَا ٱللَّهُ لِبَاسَ ٱلْجُوعِ وَٱلْخَوْفِ بِمَا كَانُوا۟ يَصْنَعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ جَآءَهُمْ رَسُولٌ مِّنْهُمْ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ ٱلْعَذَابُ وَهُمْ ظَٰلِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n.
See all translations of this verse →
فَكُلُوا۟ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلًا طَيِّبًا وَٱشْكُرُوا۟ نِعْمَتَ ٱللَّهِ إِن كُنتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, tó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
See all translations of this verse →
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيْكُمُ ٱلْمَيْتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحْمَ ٱلْخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيْرِ ٱللَّهِ بِهِۦ فَمَنِ ٱضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tó yàtọ́ sí “Allāhu”. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
See all translations of this verse →
وَلَا تَقُولُوا۟ لِمَا تَصِفُ أَلْسِنَتُكُمُ ٱلْكَذِبَ هَٰذَا حَلَٰلٌ وَهَٰذَا حَرَامٌ لِّتَفْتَرُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ لَا يُفْلِحُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.
See all translations of this verse →
مَتَٰعٌ قَلِيلٌ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run).
See all translations of this verse →
وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُوا۟ حَرَّمْنَا مَا قَصَصْنَا عَلَيْكَ مِن قَبْلُ وَمَا ظَلَمْنَٰهُمْ وَلَٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.[1] A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
See all translations of this verse →
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ عَمِلُوا۟ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٍ ثُمَّ تَابُوا۟ مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوٓا۟ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe - lẹ́yìn rẹ̀ (lẹ́yìn ìronú-pìwàdà) dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
See all translations of this verse →
إِنَّ إِبْرَٰهِيمَ كَانَ أُمَّةً قَانِتًا لِّلَّهِ حَنِيفًا وَلَمْ يَكُ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
See all translations of this verse →
شَاكِرًا لِّأَنْعُمِهِ ٱجْتَبَىٰهُ وَهَدَىٰهُ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
See all translations of this verse →
وَءَاتَيْنَٰهُ فِى ٱلدُّنْيَا حَسَنَةً وَإِنَّهُۥ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere.
See all translations of this verse →
ثُمَّ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ أَنِ ٱتَّبِعْ مِلَّةَ إِبْرَٰهِيمَ حَنِيفًا وَمَا كَانَ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.
See all translations of this verse →
إِنَّمَا جُعِلَ ٱلسَّبْتُ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱخْتَلَفُوا۟ فِيهِ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحْكُمُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀.[1] Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
See all translations of this verse →
ٱدْعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِٱلْحِكْمَةِ وَٱلْمَوْعِظَةِ ٱلْحَسَنَةِ وَجَٰدِلْهُم بِٱلَّتِى هِىَ أَحْسَنُ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعْلَمُ بِٱلْمُهْتَدِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí tó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Òun l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí).
See all translations of this verse →
وَإِنْ عَاقَبْتُمْ فَعَاقِبُوا۟ بِمِثْلِ مَا عُوقِبْتُم بِهِۦ وَلَئِن صَبَرْتُمْ لَهُوَ خَيْرٌ لِّلصَّٰبِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, òhun ló mà lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù.
See all translations of this verse →
وَٱصْبِرْ وَمَا صَبْرُكَ إِلَّا بِٱللَّهِ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَلَا تَكُ فِى ضَيْقٍ مِّمَّا يَمْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète.
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوا۟ وَّٱلَّذِينَ هُم مُّحْسِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn tó ń ṣe rere.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Hijr
Súrà Al-Israa →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.