Súrà Al-Muddaththir المدثر
56 verses · Mecca · revelation order 4
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمُدَّثِّرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ olùdaṣọbora.
See all translations of this verse →
قُمْ فَأَنذِرْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDìde kí o ṣèkìlọ̀.
See all translations of this verse →
وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
See all translations of this verse →
وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
See all translations of this verse →
وَٱلرُّجْزَ فَٱهْجُرْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒrìṣà ni kí o jìnnà sí.
See all translations of this verse →
وَلَا تَمْنُن تَسْتَكْثِرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
See all translations of this verse →
وَلِرَبِّكَ فَٱصْبِرْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
See all translations of this verse →
فَإِذَا نُقِرَ فِى ٱلنَّاقُورِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
See all translations of this verse →
فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
See all translations of this verse →
عَلَى ٱلْكَٰفِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
See all translations of this verse →
ذَرْنِى وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).
See all translations of this verse →
وَجَعَلْتُ لَهُۥ مَالًا مَّمْدُودًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
See all translations of this verse →
وَبَنِينَ شُهُودًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمْهِيدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa.
See all translations of this verse →
ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
See all translations of this verse →
كَلَّآ إِنَّهُۥ كَانَ لِـَٔايَٰتِنَا عَنِيدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
See all translations of this verse →
سَأُرْهِقُهُۥ صَعُودًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)[1].
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
See all translations of this verse →
فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
See all translations of this verse →
ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
See all translations of this verse →
ثُمَّ نَظَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó wò sùn.
See all translations of this verse →
ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
See all translations of this verse →
ثُمَّ أَدْبَرَ وَٱسْتَكْبَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.
See all translations of this verse →
فَقَالَ إِنْ هَٰذَآ إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
See all translations of this verse →
إِنْ هَٰذَآ إِلَّا قَوْلُ ٱلْبَشَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara”
See all translations of this verse →
سَأُصْلِيهِ سَقَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
See all translations of this verse →
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا سَقَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?
See all translations of this verse →
لَا تُبْقِى وَلَا تَذَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.[1]
See all translations of this verse →
لَوَّاحَةٌ لِّلْبَشَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa jó awọ ara di dúdú.
See all translations of this verse →
عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَمَا جَعَلْنَآ أَصْحَٰبَ ٱلنَّارِ إِلَّا مَلَٰٓئِكَةً وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِيَسْتَيْقِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ وَيَزْدَادَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِيمَٰنًا وَلَا يَرْتَابَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ وَٱلْمُؤْمِنُونَ وَلِيَقُولَ ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَٱلْكَٰفِرُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ وَمَا هِىَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
See all translations of this verse →
كَلَّا وَٱلْقَمَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra.
See all translations of this verse →
وَٱلَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.
See all translations of this verse →
وَٱلصُّبْحِ إِذَآ أَسْفَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.
See all translations of this verse →
إِنَّهَا لَإِحْدَى ٱلْكُبَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.
See all translations of this verse →
نَذِيرًا لِّلْبَشَرِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
See all translations of this verse →
لِمَن شَآءَ مِنكُمْ أَن يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).
See all translations of this verse →
كُلُّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
إِلَّآ أَصْحَٰبَ ٱلْيَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
See all translations of this verse →
فِى جَنَّٰتٍ يَتَسَآءَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
See all translations of this verse →
عَنِ ٱلْمُجْرِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
See all translations of this verse →
مَا سَلَكَكُمْ فِى سَقَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael“Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?”
See all translations of this verse →
قَالُوا۟ لَمْ نَكُ مِنَ ٱلْمُصَلِّينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
See all translations of this verse →
وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ ٱلْمِسْكِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
See all translations of this verse →
وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ ٱلْخَآئِضِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
See all translations of this verse →
وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́
See all translations of this verse →
حَتَّىٰٓ أَتَىٰنَا ٱلْيَقِينُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltítí ikú fi dé bá wa.”
See all translations of this verse →
فَمَا تَنفَعُهُمْ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
See all translations of this verse →
فَمَا لَهُمْ عَنِ ٱلتَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
See all translations of this verse →
كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُّسْتَنفِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelbí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,
See all translations of this verse →
فَرَّتْ مِن قَسْوَرَةٍۭ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltó sá fún kìnìhún?
See all translations of this verse →
بَلْ يُرِيدُ كُلُّ ٱمْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
See all translations of this verse →
كَلَّا بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلْـَٔاخِرَةَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
See all translations of this verse →
كَلَّآ إِنَّهُۥ تَذْكِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
See all translations of this verse →
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ هُوَ أَهْلُ ٱلتَّقْوَىٰ وَأَهْلُ ٱلْمَغْفِرَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→