Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Muzzammil
Súrà Al-Muzzammil المزمل
20 verses · Mecca · revelation order 3
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمُزَّمِّلُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìwọ olùdaṣọbora.
See all translations of this verse →
قُمِ ٱلَّيْلَ إِلَّا قَلِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀ (ni kí o fi sùn nínú òru rẹ).
See all translations of this verse →
نِّصْفَهُۥٓ أَوِ ٱنقُصْ مِنْهُ قَلِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀.
See all translations of this verse →
أَوْ زِدْ عَلَيْهِ وَرَتِّلِ ٱلْقُرْءَانَ تَرْتِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.[1]
See all translations of this verse →
إِنَّا سَنُلْقِى عَلَيْكَ قَوْلًا ثَقِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ tó lágbára fún ọ.
See all translations of this verse →
إِنَّ نَاشِئَةَ ٱلَّيْلِ هِىَ أَشَدُّ وَطْـًٔا وَأَقْوَمُ قِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān).
See all translations of this verse →
إِنَّ لَكَ فِى ٱلنَّهَارِ سَبْحًا طَوِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán.
See all translations of this verse →
وَٱذْكُرِ ٱسْمَ رَبِّكَ وَتَبَتَّلْ إِلَيْهِ تَبْتِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Rántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá.
See all translations of this verse →
رَّبُّ ٱلْمَشْرِقِ وَٱلْمَغْرِبِ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱتَّخِذْهُ وَكِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Olúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì.
See all translations of this verse →
وَٱصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱهْجُرْهُمْ هَجْرًا جَمِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì tó rẹwà.
See all translations of this verse →
وَذَرْنِى وَٱلْمُكَذِّبِينَ أُو۟لِى ٱلنَّعْمَةِ وَمَهِّلْهُمْ قَلِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Fi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ لَدَيْنَآ أَنكَالًا وَجَحِيمًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa.
See all translations of this verse →
وَطَعَامًا ذَا غُصَّةٍ وَعَذَابًا أَلِيمًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Oúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn).
See all translations of this verse →
يَوْمَ تَرْجُفُ ٱلْأَرْضُ وَٱلْجِبَالُ وَكَانَتِ ٱلْجِبَالُ كَثِيبًا مَّهِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká.
See all translations of this verse →
إِنَّآ أَرْسَلْنَآ إِلَيْكُمْ رَسُولًا شَٰهِدًا عَلَيْكُمْ كَمَآ أَرْسَلْنَآ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ رَسُولًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon.
See all translations of this verse →
فَعَصَىٰ فِرْعَوْنُ ٱلرَّسُولَ فَأَخَذْنَٰهُ أَخْذًا وَبِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle.
See all translations of this verse →
فَكَيْفَ تَتَّقُونَ إِن كَفَرْتُمْ يَوْمًا يَجْعَلُ ٱلْوِلْدَٰنَ شِيبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan tó máa mú àwọn ọmọdé hewú?
See all translations of this verse →
ٱلسَّمَآءُ مُنفَطِرٌۢ بِهِۦ كَانَ وَعْدُهُۥ مَفْعُولًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ.
See all translations of this verse →
إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذْكِرَةٌ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ رَبَّكَ يَعْلَمُ أَنَّكَ تَقُومُ أَدْنَىٰ مِن ثُلُثَىِ ٱلَّيْلِ وَنِصْفَهُۥ وَثُلُثَهُۥ وَطَآئِفَةٌ مِّنَ ٱلَّذِينَ مَعَكَ وَٱللَّهُ يُقَدِّرُ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ عَلِمَ أَن لَّن تُحْصُوهُ فَتَابَ عَلَيْكُمْ فَٱقْرَءُوا۟ مَا تَيَسَّرَ مِنَ ٱلْقُرْءَانِ عَلِمَ أَن سَيَكُونُ مِنكُم مَّرْضَىٰ وَءَاخَرُونَ يَضْرِبُونَ فِى ٱلْأَرْضِ يَبْتَغُونَ مِن فَضْلِ ٱللَّهِ وَءَاخَرُونَ يُقَٰتِلُونَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَٱقْرَءُوا۟ مَا تَيَسَّرَ مِنْهُ وَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَقْرِضُوا۟ ٱللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا وَمَا تُقَدِّمُوا۟ لِأَنفُسِكُم مِّنْ خَيْرٍ تَجِدُوهُ عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيْرًا وَأَعْظَمَ أَجْرًا وَٱسْتَغْفِرُوا۟ ٱللَّهَ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌۢ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun tó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ.1 Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fún yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Jinn
Súrà Al-Muddaththir →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.