Súrà Al-Qiyaama القيامة
40 verses · Mecca · revelation order 31
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ لَآ أُقْسِمُ بِيَوْمِ ٱلْقِيَٰمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.
See all translations of this verse →
وَلَآ أُقْسِمُ بِٱلنَّفْسِ ٱللَّوَّامَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.
See all translations of this verse →
أَيَحْسَبُ ٱلْإِنسَٰنُ أَلَّن نَّجْمَعَ عِظَامَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?
See all translations of this verse →
بَلَىٰ قَٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّىَ بَنَانَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.
See all translations of this verse →
بَلْ يُرِيدُ ٱلْإِنسَٰنُ لِيَفْجُرَ أَمَامَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀
See all translations of this verse →
يَسْـَٔلُ أَيَّانَ يَوْمُ ٱلْقِيَٰمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”
See all translations of this verse →
فَإِذَا بَرِقَ ٱلْبَصَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,
See all translations of this verse →
وَخَسَفَ ٱلْقَمَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,
See all translations of this verse →
وَجُمِعَ ٱلشَّمْسُ وَٱلْقَمَرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,
See all translations of this verse →
يَقُولُ ٱلْإِنسَٰنُ يَوْمَئِذٍ أَيْنَ ٱلْمَفَرُّ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”
See all translations of this verse →
كَلَّا لَا وَزَرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, kò sí ibùsásí.
See all translations of this verse →
إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ ٱلْمُسْتَقَرُّ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.
See all translations of this verse →
يُنَبَّؤُا۟ ٱلْإِنسَٰنُ يَوْمَئِذٍۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
See all translations of this verse →
بَلِ ٱلْإِنسَٰنُ عَلَىٰ نَفْسِهِۦ بَصِيرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,
See all translations of this verse →
وَلَوْ أَلْقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.
See all translations of this verse →
لَا تُحَرِّكْ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعْجَلَ بِهِۦٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.
See all translations of this verse →
إِنَّ عَلَيْنَا جَمْعَهُۥ وَقُرْءَانَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.
See all translations of this verse →
فَإِذَا قَرَأْنَٰهُ فَٱتَّبِعْ قُرْءَانَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.
See all translations of this verse →
ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا بَيَانَهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.
See all translations of this verse →
كَلَّا بَلْ تُحِبُّونَ ٱلْعَاجِلَةَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.
See all translations of this verse →
وَتَذَرُونَ ٱلْـَٔاخِرَةَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.
See all translations of this verse →
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاضِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).
See all translations of this verse →
إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa wọn ni wọn yóò máa wò.
See all translations of this verse →
وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍۭ بَاسِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.
See all translations of this verse →
تَظُنُّ أَن يُفْعَلَ بِهَا فَاقِرَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.
See all translations of this verse →
كَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِىَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.
See all translations of this verse →
وَقِيلَ مَنْ رَاقٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?
See all translations of this verse →
وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلْفِرَاقُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.
See all translations of this verse →
وَٱلْتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOjúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.
See all translations of this verse →
إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ ٱلْمَسَاقُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.
See all translations of this verse →
فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.
See all translations of this verse →
وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.
See all translations of this verse →
ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.
See all translations of this verse →
أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
See all translations of this verse →
ثُمَّ أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ.
See all translations of this verse →
أَيَحْسَبُ ٱلْإِنسَٰنُ أَن يُتْرَكَ سُدًى
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?
See all translations of this verse →
أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِّن مَّنِىٍّ يُمْنَىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?
See all translations of this verse →
ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.
See all translations of this verse →
فَجَعَلَ مِنْهُ ٱلزَّوْجَيْنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلْأُنثَىٰٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.
See all translations of this verse →
أَلَيْسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحْـِۧىَ ٱلْمَوْتَىٰ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→