Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà At-Tur
Súrà At-Tur الطور
49 verses · Mecca · revelation order 76
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلطُّورِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu fi àpáta Tūr búra.
See all translations of this verse →
وَكِتَٰبٍ مَّسْطُورٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó tún fi Tírà tí wọ́n kọ n̄ǹkan sínú rẹ̀ búra .
See all translations of this verse →
فِى رَقٍّ مَّنشُورٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọ́n kọ̀ ọ́) sínú n̄ǹkan ìkọ̀wé tí wọ́n tẹ́ ojú rẹ̀ sílẹ̀.
See all translations of this verse →
وَٱلْبَيْتِ ٱلْمَعْمُورِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu fi Ilé tí àwọn mọlāika ń wọnú rẹ̀ ní ojoojúmọ́ nínú sánmọ̀ búra.
See all translations of this verse →
وَٱلسَّقْفِ ٱلْمَرْفُوعِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó tún fi àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀) búra.
See all translations of this verse →
وَٱلْبَحْرِ ٱلْمَسْجُورِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó tún fi agbami odò tí wọ́n máa mú iná jáde nínú rẹ̀ búra.
See all translations of this verse →
إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ لَوَٰقِعٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.
See all translations of this verse →
مَّا لَهُۥ مِن دَافِعٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò sí ẹni tí ó máa dènà rẹ̀.
See all translations of this verse →
يَوْمَ تَمُورُ ٱلسَّمَآءُ مَوْرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.
See all translations of this verse →
وَتَسِيرُ ٱلْجِبَالُ سَيْرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àpáta sì máa rìn lọ dànù.
See all translations of this verse →
فَوَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn tó pe òdodo ní irọ́,
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ هُمْ فِى خَوْضٍ يَلْعَبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.
See all translations of this verse →
يَوْمَ يُدَعُّونَ إِلَىٰ نَارِ جَهَنَّمَ دَعًّا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò máa tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.
See all translations of this verse →
هَٰذِهِ ٱلنَّارُ ٱلَّتِى كُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
See all translations of this verse →
أَفَسِحْرٌ هَٰذَآ أَمْ أَنتُمْ لَا تُبْصِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ̀yin kò ríran?
See all translations of this verse →
ٱصْلَوْهَا فَٱصْبِرُوٓا۟ أَوْ لَا تَصْبِرُوا۟ سَوَآءٌ عَلَيْكُمْ إِنَّمَا تُجْزَوْنَ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ kò fara dà á, bákan náà ni fún yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى جَنَّٰتٍ وَنَعِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.
See all translations of this verse →
فَٰكِهِينَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمْ رَبُّهُمْ وَوَقَىٰهُمْ رَبُّهُمْ عَذَابَ ٱلْجَحِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn kúrò níbi ìyà iná Jẹhīm.
See all translations of this verse →
كُلُوا۟ وَٱشْرَبُوا۟ هَنِيٓـًٔۢا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
مُتَّكِـِٔينَ عَلَىٰ سُرُرٍ مَّصْفُوفَةٍ وَزَوَّجْنَٰهُم بِحُورٍ عِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَٱتَّبَعَتْهُمْ ذُرِّيَّتُهُم بِإِيمَٰنٍ أَلْحَقْنَا بِهِمْ ذُرِّيَّتَهُمْ وَمَآ أَلَتْنَٰهُم مِّنْ عَمَلِهِم مِّن شَىْءٍ كُلُّ ٱمْرِئٍۭ بِمَا كَسَبَ رَهِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A kò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa dúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَأَمْدَدْنَٰهُم بِفَٰكِهَةٍ وَلَحْمٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.
See all translations of this verse →
يَتَنَٰزَعُونَ فِيهَا كَأْسًا لَّا لَغْوٌ فِيهَا وَلَا تَأْثِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
See all translations of this verse →
وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ غِلْمَانٌ لَّهُمْ كَأَنَّهُمْ لُؤْلُؤٌ مَّكْنُونٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَآءَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.
See all translations of this verse →
قَالُوٓا۟ إِنَّا كُنَّا قَبْلُ فِىٓ أَهْلِنَا مُشْفِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa máa ń páyà láààrin àwọn ènìyàn wa.
See all translations of this verse →
فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيْنَا وَوَقَىٰنَا عَذَابَ ٱلسَّمُومِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá kúrò níbi ìyà Iná.
See all translations of this verse →
إِنَّا كُنَّا مِن قَبْلُ نَدْعُوهُ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْبَرُّ ٱلرَّحِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
See all translations of this verse →
فَذَكِّرْ فَمَآ أَنتَ بِنِعْمَتِ رَبِّكَ بِكَاهِنٍ وَلَا مَجْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
See all translations of this verse →
أَمْ يَقُولُونَ شَاعِرٌ نَّتَرَبَّصُ بِهِۦ رَيْبَ ٱلْمَنُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ń wí pé: “Eléwì kan tí à ń retí àpadàsí aburú fún ni.”
See all translations of this verse →
قُلْ تَرَبَّصُوا۟ فَإِنِّى مَعَكُم مِّنَ ٱلْمُتَرَبِّصِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.
See all translations of this verse →
أَمْ تَأْمُرُهُمْ أَحْلَٰمُهُم بِهَٰذَآ أَمْ هُمْ قَوْمٌ طَاغُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí ọpọlọ wọn ló ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
See all translations of this verse →
أَمْ يَقُولُونَ تَقَوَّلَهُۥ بَل لَّا يُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
See all translations of this verse →
فَلْيَأْتُوا۟ بِحَدِيثٍ مِّثْلِهِۦٓ إِن كَانُوا۟ صَٰدِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
See all translations of this verse →
أَمْ خُلِقُوا۟ مِنْ غَيْرِ شَىْءٍ أَمْ هُمُ ٱلْخَٰلِقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
See all translations of this verse →
أَمْ خَلَقُوا۟ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بَل لَّا يُوقِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
See all translations of this verse →
أَمْ عِندَهُمْ خَزَآئِنُ رَبِّكَ أَمْ هُمُ ٱلْمُصَۣيْطِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn ilé ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
See all translations of this verse →
أَمْ لَهُمْ سُلَّمٌ يَسْتَمِعُونَ فِيهِ فَلْيَأْتِ مُسْتَمِعُهُم بِسُلْطَٰنٍ مُّبِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ní àkàbà kan tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀)? Kí ẹni tí ó ń bá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mú ẹ̀rí tó yanjú wá?
See all translations of this verse →
أَمْ لَهُ ٱلْبَنَٰتُ وَلَكُمُ ٱلْبَنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
See all translations of this verse →
أَمْ تَسْـَٔلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
See all translations of this verse →
أَمْ عِندَهُمُ ٱلْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
See all translations of this verse →
أَمْ يُرِيدُونَ كَيْدًا فَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ هُمُ ٱلْمَكِيدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète náà.
See all translations of this verse →
أَمْ لَهُمْ إِلَٰهٌ غَيْرُ ٱللَّهِ سُبْحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
See all translations of this verse →
وَإِن يَرَوْا۟ كِسْفًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ سَاقِطًا يَقُولُوا۟ سَحَابٌ مَّرْكُومٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí wọ́n bá rí apá kan nínú sánmọ̀ tó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́).”
See all translations of this verse →
فَذَرْهُمْ حَتَّىٰ يُلَٰقُوا۟ يَوْمَهُمُ ٱلَّذِى فِيهِ يُصْعَقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
See all translations of this verse →
يَوْمَ لَا يُغْنِى عَنْهُمْ كَيْدُهُمْ شَيْـًٔا وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
See all translations of this verse →
وَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ عَذَابًا دُونَ ذَٰلِكَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn tó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
See all translations of this verse →
وَٱصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعْيُنِنَا وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.[1]
See all translations of this verse →
وَمِنَ ٱلَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَإِدْبَٰرَ ٱلنُّجُومِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán[1], ṣàfọ̀mọ́ fún Un.
See all translations of this verse →
← Súrà Adh-Dhaariyat
Súrà An-Najm →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.