caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Adh-Dhaariyat الذاريات

60 verses · Mecca · revelation order 67

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلذَّٰرِيَٰتِ ذَرْوًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْحَٰمِلَٰتِ وِقْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْجَٰرِيَٰتِ يُسْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْمُقَسِّمَٰتِ أَمْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra.

See all translations of this verse →

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ ٱلدِّينَ لَوَٰقِعٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀.

See all translations of this verse →

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلْحُبُكِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra.

See all translations of this verse →

إِنَّكُمْ لَفِى قَوْلٍ مُّخْتَلِفٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).

See all translations of this verse →

يُؤْفَكُ عَنْهُ مَنْ أُفِكَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).

See all translations of this verse →

قُتِلَ ٱلْخَرَّٰصُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni fún àwọn òpùrọ́;

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ هُمْ فِى غَمْرَةٍ سَاهُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra.

See all translations of this verse →

يَسْـَٔلُونَ أَيَّانَ يَوْمُ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.

See all translations of this verse →

يَوْمَ هُمْ عَلَى ٱلنَّارِ يُفْتَنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.

See all translations of this verse →

ذُوقُوا۟ فِتْنَتَكُمْ هَٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تَسْتَعْجِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

See all translations of this verse →

ءَاخِذِينَ مَآ ءَاتَىٰهُمْ رَبُّهُمْ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَبْلَ ذَٰلِكَ مُحْسِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.

See all translations of this verse →

كَانُوا۟ قَلِيلًا مِّنَ ٱلَّيْلِ مَا يَهْجَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.

See all translations of this verse →

وَبِٱلْأَسْحَارِ هُمْ يَسْتَغْفِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

See all translations of this verse →

وَفِىٓ أَمْوَٰلِهِمْ حَقٌّ لِّلسَّآئِلِ وَٱلْمَحْرُومِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.

See all translations of this verse →

وَفِى ٱلْأَرْضِ ءَايَٰتٌ لِّلْمُوقِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.

See all translations of this verse →

وَفِىٓ أَنفُسِكُمْ أَفَلَا تُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni?

See all translations of this verse →

وَفِى ٱلسَّمَآءِ رِزْقُكُمْ وَمَا تُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelArísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀.

See all translations of this verse →

فَوَرَبِّ ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ إِنَّهُۥ لَحَقٌّ مِّثْلَ مَآ أَنَّكُمْ تَنطِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.

See all translations of this verse →

هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ضَيْفِ إِبْرَٰهِيمَ ٱلْمُكْرَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

See all translations of this verse →

إِذْ دَخَلُوا۟ عَلَيْهِ فَقَالُوا۟ سَلَٰمًا قَالَ سَلَٰمٌ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Òun náà sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn.”

See all translations of this verse →

فَرَاغَ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ فَجَآءَ بِعِجْلٍ سَمِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ).

See all translations of this verse →

فَقَرَّبَهُۥٓ إِلَيْهِمْ قَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?”

See all translations of this verse →

فَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً قَالُوا۟ لَا تَخَفْ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un.[1]. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe páyà.” Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.

See all translations of this verse →

فَأَقْبَلَتِ ٱمْرَأَتُهُۥ فِى صَرَّةٍ فَصَكَّتْ وَجْهَهَا وَقَالَتْ عَجُوزٌ عَقِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: “Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْحَكِيمُ ٱلْعَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا ٱلْمُرْسَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ إِنَّآ أُرْسِلْنَآ إِلَىٰ قَوْمٍ مُّجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

See all translations of this verse →

لِنُرْسِلَ عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِّن طِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.

See all translations of this verse →

مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلْمُسْرِفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ.”

See all translations of this verse →

فَأَخْرَجْنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).

See all translations of this verse →

فَمَا وَجَدْنَا فِيهَا غَيْرَ بَيْتٍ مِّنَ ٱلْمُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.

See all translations of this verse →

وَتَرَكْنَا فِيهَآ ءَايَةً لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ ٱلْعَذَابَ ٱلْأَلِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

See all translations of this verse →

وَفِى مُوسَىٰٓ إِذْ أَرْسَلْنَٰهُ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ بِسُلْطَٰنٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.

See all translations of this verse →

فَتَوَلَّىٰ بِرُكْنِهِۦ وَقَالَ سَٰحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí).”

See all translations of this verse →

فَأَخَذْنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذْنَٰهُمْ فِى ٱلْيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.

See all translations of this verse →

وَفِى عَادٍ إِذْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمُ ٱلرِّيحَ ٱلْعَقِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn.

See all translations of this verse →

مَا تَذَرُ مِن شَىْءٍ أَتَتْ عَلَيْهِ إِلَّا جَعَلَتْهُ كَٱلرَّمِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.[1]

See all translations of this verse →

وَفِى ثَمُودَ إِذْ قِيلَ لَهُمْ تَمَتَّعُوا۟ حَتَّىٰ حِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná.”

See all translations of this verse →

فَعَتَوْا۟ عَنْ أَمْرِ رَبِّهِمْ فَأَخَذَتْهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَهُمْ يَنظُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.

See all translations of this verse →

فَمَا ٱسْتَطَٰعُوا۟ مِن قِيَامٍ وَمَا كَانُوا۟ مُنتَصِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.

See all translations of this verse →

وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَوْمًا فَٰسِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin.

See all translations of this verse →

وَٱلسَّمَآءَ بَنَيْنَٰهَا بِأَيْي۟دٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi).

See all translations of this verse →

وَٱلْأَرْضَ فَرَشْنَٰهَا فَنِعْمَ ٱلْمَٰهِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára.

See all translations of this verse →

وَمِن كُلِّ شَىْءٍ خَلَقْنَا زَوْجَيْنِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.[1]

See all translations of this verse →

فَفِرُّوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ إِنِّى لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَا تَجْعَلُوا۟ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ إِنِّى لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

كَذَٰلِكَ مَآ أَتَى ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُوا۟ سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè ni.”

See all translations of this verse →

أَتَوَاصَوْا۟ بِهِۦ بَلْ هُمْ قَوْمٌ طَاغُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni.

See all translations of this verse →

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ فَمَآ أَنتَ بِمَلُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí.

See all translations of this verse →

وَذَكِّرْ فَإِنَّ ٱلذِّكْرَىٰ تَنفَعُ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَمَا خَلَقْتُ ٱلْجِنَّ وَٱلْإِنسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.

See all translations of this verse →

مَآ أُرِيدُ مِنْهُم مِّن رِّزْقٍ وَمَآ أُرِيدُ أَن يُطْعِمُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلرَّزَّاقُ ذُو ٱلْقُوَّةِ ٱلْمَتِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.

See all translations of this verse →

فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ ذَنُوبًا مِّثْلَ ذَنُوبِ أَصْحَٰبِهِمْ فَلَا يَسْتَعْجِلُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).

See all translations of this verse →

فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِن يَوْمِهِمُ ٱلَّذِى يُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70