caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Najm النجم

62 verses · Mecca · revelation order 23

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلنَّجْمِ إِذَا هَوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.[1]

See all translations of this verse →

مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمْ وَمَا غَوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.[1]

See all translations of this verse →

وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلْهَوَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.

See all translations of this verse →

إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْىٌ يُوحَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.[1]

See all translations of this verse →

عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلْقُوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAlágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).

See all translations of this verse →

ذُو مِرَّةٍ فَٱسْتَوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ní àlàáfíà tó péye, ó sì dúró wámúwámú,

See all translations of this verse →

وَهُوَ بِٱلْأُفُقِ ٱلْأَعْلَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.

See all translations of this verse →

ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).

See all translations of this verse →

فَكَانَ قَابَ قَوْسَيْنِ أَوْ أَدْنَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).[1]

See all translations of this verse →

فَأَوْحَىٰٓ إِلَىٰ عَبْدِهِۦ مَآ أَوْحَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí tó fún un.

See all translations of this verse →

مَا كَذَبَ ٱلْفُؤَادُ مَا رَأَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌkàn (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kò parọ́ ohun tó rí.

See all translations of this verse →

أَفَتُمَٰرُونَهُۥ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun tó rí ni?

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ رَءَاهُ نَزْلَةً أُخْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì[1]

See all translations of this verse →

عِندَ سِدْرَةِ ٱلْمُنتَهَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelníbi igi sidirah al-Muntahā,

See all translations of this verse →

عِندَهَا جَنَّةُ ٱلْمَأْوَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.

See all translations of this verse →

إِذْ يَغْشَى ٱلسِّدْرَةَ مَا يَغْشَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí ohun tó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.

See all translations of this verse →

مَا زَاغَ ٱلْبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOjú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-ààlà.

See all translations of this verse →

لَقَدْ رَأَىٰ مِنْ ءَايَٰتِ رَبِّهِ ٱلْكُبْرَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, tó tóbi.

See all translations of this verse →

أَفَرَءَيْتُمُ ٱللَّٰتَ وَٱلْعُزَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,

See all translations of this verse →

وَمَنَوٰةَ ٱلثَّالِثَةَ ٱلْأُخْرَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.[1]

See all translations of this verse →

أَلَكُمُ ٱلذَّكَرُ وَلَهُ ٱلْأُنثَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?

See all translations of this verse →

تِلْكَ إِذًا قِسْمَةٌ ضِيزَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.

See all translations of this verse →

إِنْ هِىَ إِلَّآ أَسْمَآءٌ سَمَّيْتُمُوهَآ أَنتُمْ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلْطَٰنٍ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَمَا تَهْوَى ٱلْأَنفُسُ وَلَقَدْ جَآءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ ٱلْهُدَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́ (ìfẹ́-inú). Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

See all translations of this verse →

أَمْ لِلْإِنسَٰنِ مَا تَمَنَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan tó bá ń fẹ́!

See all translations of this verse →

فَلِلَّهِ ٱلْـَٔاخِرَةُ وَٱلْأُولَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.

See all translations of this verse →

وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ لَا تُغْنِى شَفَٰعَتُهُمْ شَيْـًٔا إِلَّا مِنۢ بَعْدِ أَن يَأْذَنَ ٱللَّهُ لِمَن يَشَآءُ وَيَرْضَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika tó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱلْـَٔاخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلْمَلَٰٓئِكَةَ تَسْمِيَةَ ٱلْأُنثَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.

See all translations of this verse →

وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنْ عِلْمٍ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغْنِى مِنَ ٱلْحَقِّ شَيْـًٔا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Dájúdájú àbá dídá kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.

See all translations of this verse →

فَأَعْرِضْ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُم مِّنَ ٱلْعِلْمِ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ ٱهْتَدَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn ni ohun tí wọ́n wọ̀n nínú ìmọ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó mọ̀nà.

See all translations of this verse →

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ لِيَجْزِىَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔوا۟ بِمَا عَمِلُوا۟ وَيَجْزِىَ ٱلَّذِينَ أَحْسَنُوا۟ بِٱلْحُسْنَى

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلْإِثْمِ وَٱلْفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلْمَغْفِرَةِ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلْأَرْضِ وَإِذْ أَنتُمْ أَجِنَّةٌ فِى بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمْ فَلَا تُزَكُّوٓا۟ أَنفُسَكُمْ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́.[1] Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).

See all translations of this verse →

أَفَرَءَيْتَ ٱلَّذِى تَوَلَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ fún mi nípa ẹni tó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),

See all translations of this verse →

وَأَعْطَىٰ قَلِيلًا وَأَكْدَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!

See all translations of this verse →

أَعِندَهُۥ عِلْمُ ٱلْغَيْبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?

See all translations of this verse →

أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِى صُحُفِ مُوسَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọn kò fún un ní ìró ohun tó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,

See all translations of this verse →

وَإِبْرَٰهِيمَ ٱلَّذِى وَفَّىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni tó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,

See all translations of this verse →

أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelpé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.[1]

See all translations of this verse →

وَأَن لَّيْسَ لِلْإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun tó ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَأَنَّ سَعْيَهُۥ سَوْفَ يُرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.

See all translations of this verse →

ثُمَّ يُجْزَىٰهُ ٱلْجَزَآءَ ٱلْأَوْفَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san tó kún jùlọ.

See all translations of this verse →

وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلْمُنتَهَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضْحَكَ وَأَبْكَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحْيَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥ خَلَقَ ٱلزَّوْجَيْنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلْأُنثَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,[1]

See all translations of this verse →

مِن نُّطْفَةٍ إِذَا تُمْنَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelláti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.

See all translations of this verse →

وَأَنَّ عَلَيْهِ ٱلنَّشْأَةَ ٱلْأُخْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥ هُوَ أَغْنَىٰ وَأَقْنَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó ń fún ẹ̀dá ní ọrọ̀ dúkìá, Ó sì ń ta ẹ̀dá ní òṣì.

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥ هُوَ رَبُّ ٱلشِّعْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُۥٓ أَهْلَكَ عَادًا ٱلْأُولَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;

See all translations of this verse →

وَثَمُودَا۟ فَمَآ أَبْقَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;

See all translations of this verse →

وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ìjọ Nūh tó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-ààlà jùlọ;

See all translations of this verse →

وَٱلْمُؤْتَفِكَةَ أَهْوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ìlú tó dojú bolẹ̀ (ìlú Ànábì Lūt), Allāhu ló yẹ̀ ẹ́ lulẹ̀ (láti òkè).

See all translations of this verse →

فَغَشَّىٰهَا مَا غَشَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

See all translations of this verse →

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?

See all translations of this verse →

هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ ٱلنُّذُرِ ٱلْأُولَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.

See all translations of this verse →

أَزِفَتِ ٱلْـَٔازِفَةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tó súnmọ́[1] súnmọ́.

See all translations of this verse →

لَيْسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ كَاشِفَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè tú gbèdéke Àkókò náà jáde.[1]

See all translations of this verse →

أَفَمِنْ هَٰذَا ٱلْحَدِيثِ تَعْجَبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?

See all translations of this verse →

وَتَضْحَكُونَ وَلَا تَبْكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ kò sì sunkún!

See all translations of this verse →

وَأَنتُمْ سَٰمِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAfọ́nú-fọ́ra ni yín.

See all translations of this verse →

فَٱسْجُدُوا۟ لِلَّهِ وَٱعْبُدُوا۟

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70