caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Mutaffifin المطففين

36 verses · Mecca · revelation order 86

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَيْلٌ لِّلْمُطَفِّفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكْتَالُوا۟ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسْتَوْفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,[1] wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,

See all translations of this verse →

وَإِذَا كَالُوهُمْ أَو وَّزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.

See all translations of this verse →

أَلَا يَظُنُّ أُو۟لَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبْعُوثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde

See all translations of this verse →

لِيَوْمٍ عَظِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelní Ọjọ́ ńlá kan?

See all translations of this verse →

يَوْمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلْفُجَّارِ لَفِى سِجِّينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا سِجِّينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!

See all translations of this verse →

كِتَٰبٌ مَّرْقُومٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

See all translations of this verse →

وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”

See all translations of this verse →

كَلَّا بَلْ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّهُمْ عَن رَّبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّمَحْجُوبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.

See all translations of this verse →

ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُوا۟ ٱلْجَحِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.

See all translations of this verse →

ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلْأَبْرَارِ لَفِى عِلِّيِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!

See all translations of this verse →

كِتَٰبٌ مَّرْقُومٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).

See all translations of this verse →

يَشْهَدُهُ ٱلْمُقَرَّبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.

See all translations of this verse →

عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

See all translations of this verse →

تَعْرِفُ فِى وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ ٱلنَّعِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.

See all translations of this verse →

يُسْقَوْنَ مِن رَّحِيقٍ مَّخْتُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.

See all translations of this verse →

خِتَٰمُهُۥ مِسْكٌ وَفِى ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ ٱلْمُتَنَٰفِسُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.

See all translations of this verse →

وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسْنِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).

See all translations of this verse →

عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا ٱلْمُقَرَّبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجْرَمُوا۟ كَانُوا۟ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يَضْحَكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.

See all translations of this verse →

وَإِذَا مَرُّوا۟ بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَهْلِهِمُ ٱنقَلَبُوا۟ فَكِهِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.

See all translations of this verse →

وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوٓا۟ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”

See all translations of this verse →

وَمَآ أُرْسِلُوا۟ عَلَيْهِمْ حَٰفِظِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.

See all translations of this verse →

فَٱلْيَوْمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنَ ٱلْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.

See all translations of this verse →

عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

See all translations of this verse →

هَلْ ثُوِّبَ ٱلْكُفَّارُ مَا كَانُوا۟ يَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70