Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Inshiqaaq
Súrà Al-Inshiqaaq الإنشقاق
25 verses · Mecca · revelation order 83
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنشَقَّتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
See all translations of this verse →
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀[1] -
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْأَرْضُ مُدَّتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
See all translations of this verse →
وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
See all translations of this verse →
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
See all translations of this verse →
يَٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَٰنُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَٰقِيهِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
See all translations of this verse →
فَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
See all translations of this verse →
فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
See all translations of this verse →
وَيَنقَلِبُ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
See all translations of this verse →
وَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ وَرَآءَ ظَهْرِهِۦ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,[1]
See all translations of this verse →
فَسَوْفَ يَدْعُوا۟ ثُبُورًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
See all translations of this verse →
وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ كَانَ فِىٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
See all translations of this verse →
بَلَىٰٓ إِنَّ رَبَّهُۥ كَانَ بِهِۦ بَصِيرًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
See all translations of this verse →
فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلشَّفَقِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.
See all translations of this verse →
وَٱلَّيْلِ وَمَا وَسَقَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.
See all translations of this verse →
وَٱلْقَمَرِ إِذَا ٱتَّسَقَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.
See all translations of this verse →
لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
See all translations of this verse →
فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
See all translations of this verse →
وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ ٱلْقُرْءَانُ لَا يَسْجُدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
See all translations of this verse →
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُكَذِّبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.
See all translations of this verse →
وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
See all translations of this verse →
فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
See all translations of this verse →
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍۭ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin[1] ń bẹ fún wọn.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Mutaffifin
Súrà Al-Burooj →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.