caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Infitaar الإنفطار

19 verses · Mecca · revelation order 82

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,[1]

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلْكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلْبِحَارُ فُجِّرَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلْقُبُورُ بُعْثِرَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

See all translations of this verse →

عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلْكَرِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

See all translations of this verse →

فِىٓ أَىِّ صُورَةٍ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

See all translations of this verse →

كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَٰفِظِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

See all translations of this verse →

كِرَامًا كَٰتِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ ٱلْفُجَّارَ لَفِى جَحِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

See all translations of this verse →

يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

See all translations of this verse →

وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَآئِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

See all translations of this verse →

ثُمَّ مَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

See all translations of this verse →

يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِّنَفْسٍ شَيْـًٔا وَٱلْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70