caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Fajr الفجر

30 verses · Mecca · revelation order 10

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلْفَجْرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.

See all translations of this verse →

وَلَيَالٍ عَشْرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn òru mẹ́wàá kan búra.

See all translations of this verse →

وَٱلشَّفْعِ وَٱلْوَتْرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi n̄ǹkan tí eéjì ń pín geerege àti n̄ǹkan tí eéjì kò pín geerege búra.

See all translations of this verse →

وَٱلَّيْلِ إِذَا يَسْرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi òru nígbà tí ó bá dé búra.

See all translations of this verse →

هَلْ فِى ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِّذِى حِجْرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ كَيْفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,

See all translations of this verse →

إِرَمَ ذَاتِ ٱلْعِمَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,

See all translations of this verse →

ٱلَّتِى لَمْ يُخْلَقْ مِثْلُهَا فِى ٱلْبِلَٰدِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tí A kò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?

See all translations of this verse →

وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُوا۟ ٱلصَّخْرَ بِٱلْوَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonúfojì,

See all translations of this verse →

وَفِرْعَوْنَ ذِى ٱلْأَوْتَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ طَغَوْا۟ فِى ٱلْبِلَٰدِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn tó tayọ ẹnu-ààlà nínú ìlú.

See all translations of this verse →

فَأَكْثَرُوا۟ فِيهَا ٱلْفَسَادَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

فَصَبَّ عَلَيْهِمْ رَبُّكَ سَوْطَ عَذَابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.

See all translations of this verse →

إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلْمِرْصَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).

See all translations of this verse →

فَأَمَّا ٱلْإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبْتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكْرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّىٓ أَكْرَمَنِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti pọ́n mi lé.”

See all translations of this verse →

وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبْتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيْهِ رِزْقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّىٓ أَهَٰنَنِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi.”

See all translations of this verse →

كَلَّا بَل لَّا تُكْرِمُونَ ٱلْيَتِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.

See all translations of this verse →

وَلَا تَحَٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلْمِسْكِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.

See all translations of this verse →

وَتَأْكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكْلًا لَّمًّا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.

See all translations of this verse →

وَتُحِبُّونَ ٱلْمَالَ حُبًّا جَمًّا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِذَا دُكَّتِ ٱلْأَرْضُ دَكًّا دَكًّا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (tó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),

See all translations of this verse →

وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلْمَلَكُ صَفًّا صَفًّا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,

See all translations of this verse →

وَجِا۟ىٓءَ يَوْمَئِذٍۭ بِجَهَنَّمَ يَوْمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ ٱلْإِنسَٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!

See all translations of this verse →

يَقُولُ يَٰلَيْتَنِى قَدَّمْتُ لِحَيَاتِى

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa wí pé: “Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi.”

See all translations of this verse →

فَيَوْمَئِذٍ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).

See all translations of this verse →

وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفْسُ ٱلْمُطْمَئِنَّةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,

See all translations of this verse →

ٱرْجِعِىٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَّرْضِيَّةً

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelpadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.

See all translations of this verse →

فَٱدْخُلِى فِى عِبَٰدِى

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.

See all translations of this verse →

وَٱدْخُلِى جَنَّتِى

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70