Súrà Al-Balad البلد
20 verses · Mecca · revelation order 35
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ لَآ أُقْسِمُ بِهَٰذَا ٱلْبَلَدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.
See all translations of this verse →
وَأَنتَ حِلٌّۢ بِهَٰذَا ٱلْبَلَدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]
See all translations of this verse →
وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
See all translations of this verse →
لَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ فِى كَبَدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
See all translations of this verse →
أَيَحْسَبُ أَن لَّن يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
See all translations of this verse →
يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُّبَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
See all translations of this verse →
أَيَحْسَبُ أَن لَّمْ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
See all translations of this verse →
أَلَمْ نَجْعَل لَّهُۥ عَيْنَيْنِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé A kò ṣe ojú méjì fún un?
See all translations of this verse →
وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
See all translations of this verse →
وَهَدَيْنَٰهُ ٱلنَّجْدَيْنِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
See all translations of this verse →
فَلَا ٱقْتَحَمَ ٱلْعَقَبَةَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
See all translations of this verse →
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْعَقَبَةُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
See all translations of this verse →
فَكُّ رَقَبَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
See all translations of this verse →
أَوْ إِطْعَٰمٌ فِى يَوْمٍ ذِى مَسْغَبَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
See all translations of this verse →
يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
See all translations of this verse →
أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
See all translations of this verse →
ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلْمَرْحَمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
See all translations of this verse →
أُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا هُمْ أَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.[1]
See all translations of this verse →
عَلَيْهِمْ نَارٌ مُّؤْصَدَةٌۢ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→