caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Mursalaat المرسلات

50 verses · Mecca · revelation order 33

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلْمُرْسَلَٰتِ عُرْفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْعَٰصِفَٰتِ عَصْفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.

See all translations of this verse →

وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْفَٰرِقَٰتِ فَرْقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْمُلْقِيَٰتِ ذِكْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.

See all translations of this verse →

عُذْرًا أَوْ نُذْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.

See all translations of this verse →

فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلْجِبَالُ نُسِفَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,

See all translations of this verse →

وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),

See all translations of this verse →

لِأَىِّ يَوْمٍ أُجِّلَتْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?

See all translations of this verse →

لِيَوْمِ ٱلْفَصْلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

أَلَمْ نُهْلِكِ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?

See all translations of this verse →

ثُمَّ نُتْبِعُهُمُ ٱلْـَٔاخِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).

See all translations of this verse →

كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِٱلْمُجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

أَلَمْ نَخْلُقكُّم مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?

See all translations of this verse →

فَجَعَلْنَٰهُ فِى قَرَارٍ مَّكِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

See all translations of this verse →

إِلَىٰ قَدَرٍ مَّعْلُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltítí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).

See all translations of this verse →

فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ ٱلْقَٰدِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

أَلَمْ نَجْعَلِ ٱلْأَرْضَ كِفَاتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;

See all translations of this verse →

أَحْيَآءً وَأَمْوَٰتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ شَٰمِخَٰتٍ وَأَسْقَيْنَٰكُم مَّآءً فُرَاتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.

See all translations of this verse →

ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ ظِلٍّ ذِى ثَلَٰثِ شُعَبٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.

See all translations of this verse →

لَّا ظَلِيلٍ وَلَا يُغْنِى مِنَ ٱللَّهَبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.

See all translations of this verse →

إِنَّهَا تَرْمِى بِشَرَرٍ كَٱلْقَصْرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.

See all translations of this verse →

كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٌ صُفْرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

See all translations of this verse →

هَٰذَا يَوْمُ لَا يَنطِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَا يُؤْذَنُ لَهُمْ فَيَعْتَذِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

هَٰذَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ جَمَعْنَٰكُمْ وَٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.

See all translations of this verse →

فَإِن كَانَ لَكُمْ كَيْدٌ فَكِيدُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى ظِلَٰلٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,

See all translations of this verse →

وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشْتَهُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.

See all translations of this verse →

كُلُوا۟ وَٱشْرَبُوا۟ هَنِيٓـًٔۢا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْمُحْسِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

كُلُوا۟ وَتَمَتَّعُوا۟ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجْرِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرْكَعُوا۟ لَا يَرْكَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.

See all translations of this verse →

وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈgbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

See all translations of this verse →

فَبِأَىِّ حَدِيثٍۭ بَعْدَهُۥ يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70