caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Insaan الانسان

31 verses · Medina · revelation order 98

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ هَلْ أَتَىٰ عَلَى ٱلْإِنسَٰنِ حِينٌ مِّنَ ٱلدَّهْرِ لَمْ يَكُن شَيْـًٔا مَّذْكُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢebí àkókò kan nínú ìgbà ti ré kọjá lórí ènìyàn tí (ènìyàn) kò jẹ́ kiní kan tí wọ́n ń dárúkọ?

See all translations of this verse →

إِنَّا خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ مِن نُّطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَّبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَٰهُ سَمِيعًۢا بَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara àtọ̀ tó ròpọ̀ mọ́ra wọn (láti ara ọkùnrin àti obìnrin), A sì máa dán an wò.[1] A sì ṣe é ní olùgbọ́, olùríran.

See all translations of this verse →

إِنَّا هَدَيْنَٰهُ ٱلسَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرًا وَإِمَّا كَفُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n; Ó lè jẹ́ olùdúpẹ́, ó sì lè jẹ́ aláìmoore.

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَعْتَدْنَا لِلْكَٰفِرِينَ سَلَٰسِلَا۟ وَأَغْلَٰلًا وَسَعِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa pèsè àwọn ẹ̀wọ̀n, àjàgà àti Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ يَشْرَبُونَ مِن كَأْسٍ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹni rere, wọn yóò máa mu omi kan nínú ife. Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (omi náà) ni káfúrà.

See all translations of this verse →

عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا عِبَادُ ٱللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفْجِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOmi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (ní ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ẹ).

See all translations of this verse →

يُوفُونَ بِٱلنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُۥ مُسْتَطِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an.

See all translations of this verse →

وَيُطْعِمُونَ ٱلطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ.

See all translations of this verse →

إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمْ جَزَآءً وَلَا شُكُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Wọ́n sì ń sọ pé:) “Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ jẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín.

See all translations of this verse →

إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوْمًا عَبُوسًا قَمْطَرِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwa ń páyà ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa.”

See all translations of this verse →

فَوَقَىٰهُمُ ٱللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ ٱلْيَوْمِ وَلَقَّىٰهُمْ نَضْرَةً وَسُرُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú.

See all translations of this verse →

وَجَزَىٰهُم بِمَا صَبَرُوا۟ جَنَّةً وَحَرِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlàárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù.

See all translations of this verse →

مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ لَا يَرَوْنَ فِيهَا شَمْسًا وَلَا زَمْهَرِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù.

See all translations of this verse →

وَدَانِيَةً عَلَيْهِمْ ظِلَٰلُهَا وَذُلِّلَتْ قُطُوفُهَا تَذْلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ibòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́.

See all translations of this verse →

وَيُطَافُ عَلَيْهِم بِـَٔانِيَةٍ مِّن فِضَّةٍ وَأَكْوَابٍ كَانَتْ قَوَارِيرَا۠

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.

See all translations of this verse →

قَوَارِيرَا۟ مِن فِضَّةٍ قَدَّرُوهَا تَقْدِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIfe aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n- níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu).

See all translations of this verse →

وَيُسْقَوْنَ فِيهَا كَأْسًا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀.

See all translations of this verse →

عَيْنًا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلْسَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl.

See all translations of this verse →

وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيْتَهُمْ حَسِبْتَهُمْ لُؤْلُؤًا مَّنثُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n fọ́n kalẹ̀.

See all translations of this verse →

وَإِذَا رَأَيْتَ ثَمَّ رَأَيْتَ نَعِيمًا وَمُلْكًا كَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá tó tóbi.

See all translations of this verse →

عَٰلِيَهُمْ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضْرٌ وَإِسْتَبْرَقٌ وَحُلُّوٓا۟ أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٍ وَسَقَىٰهُمْ رَبُّهُمْ شَرَابًا طَهُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAṣọ àlàárì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ àlàárì tó nípọn máa wà lókè wọn (àti lára wọn). A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمْ جَزَآءً وَكَانَ سَعْيُكُم مَّشْكُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Wọ́n sì máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ yín fun yín.

See all translations of this verse →

إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ ٱلْقُرْءَانَ تَنزِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀ díẹ̀.[1]

See all translations of this verse →

فَٱصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعْ مِنْهُمْ ءَاثِمًا أَوْ كَفُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn.

See all translations of this verse →

وَٱذْكُرِ ٱسْمَ رَبِّكَ بُكْرَةً وَأَصِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

See all translations of this verse →

وَمِنَ ٱلَّيْلِ فَٱسْجُدْ لَهُۥ وَسَبِّحْهُ لَيْلًا طَوِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti ní òru, forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní òru fún ìgbà pípẹ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ يُحِبُّونَ ٱلْعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَآءَهُمْ يَوْمًا ثَقِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn wọ̀nyí fẹ́ràn ayé. Wọ́n sì ń pa ọjọ́ tó wúwo tì sẹ́yìn wọn.

See all translations of this verse →

نَّحْنُ خَلَقْنَٰهُمْ وَشَدَدْنَآ أَسْرَهُمْ وَإِذَا شِئْنَا بَدَّلْنَآ أَمْثَٰلَهُمْ تَبْدِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa l’A ṣẹ̀dá wọn. A sì ṣe ìṣẹ̀dá wọn dáradára. Nígbà tí A bá sì fẹ́, A óò fi irú wọn pààrọ̀ wọn ní ti ìpààrọ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذْكِرَةٌ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà tọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.[1]

See all translations of this verse →

يُدْخِلُ مَن يَشَآءُ فِى رَحْمَتِهِۦ وَٱلظَّٰلِمِينَ أَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ rẹ̀. (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70