caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Naba النبإ

40 verses · Mecca · revelation order 80

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?

See all translations of this verse →

عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى هُمْ فِيهِ مُخْتَلِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelèyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

See all translations of this verse →

كَلَّا سَيَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.

See all translations of this verse →

ثُمَّ كَلَّا سَيَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.

See all translations of this verse →

أَلَمْ نَجْعَلِ ٱلْأَرْضَ مِهَٰدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí,

See all translations of this verse →

وَٱلْجِبَالَ أَوْتَادًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?

See all translations of this verse →

وَخَلَقْنَٰكُمْ أَزْوَٰجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا نَوْمَكُمْ سُبَاتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ṣe oorun yín ní ìsinmi.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا ٱلَّيْلَ لِبَاسًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún ṣe alẹ́ ní ìbora.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.

See all translations of this verse →

وَبَنَيْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعًا شِدَادًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا سِرَاجًا وَهَّاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà.

See all translations of this verse →

وَأَنزَلْنَا مِنَ ٱلْمُعْصِرَٰتِ مَآءً ثَجَّاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò

See all translations of this verse →

لِّنُخْرِجَ بِهِۦ حَبًّا وَنَبَاتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde

See all translations of this verse →

وَجَنَّٰتٍ أَلْفَافًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelpẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko.

See all translations of this verse →

إِنَّ يَوْمَ ٱلْفَصْلِ كَانَ مِيقَٰتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.

See all translations of this verse →

يَوْمَ يُنفَخُ فِى ٱلصُّورِ فَتَأْتُونَ أَفْوَاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.

See all translations of this verse →

وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتْ أَبْوَٰبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.

See all translations of this verse →

وَسُيِّرَتِ ٱلْجِبَالُ فَكَانَتْ سَرَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.

See all translations of this verse →

إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتْ مِرْصَادًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.

See all translations of this verse →

لِّلطَّٰغِينَ مَـَٔابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.

See all translations of this verse →

لَّٰبِثِينَ فِيهَآ أَحْقَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.

See all translations of this verse →

لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرْدًا وَلَا شَرَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,

See all translations of this verse →

إِلَّا حَمِيمًا وَغَسَّاقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.

See all translations of this verse →

جَزَآءً وِفَاقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).

See all translations of this verse →

إِنَّهُمْ كَانُوا۟ لَا يَرْجُونَ حِسَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا كِذَّابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an.

See all translations of this verse →

وَكُلَّ شَىْءٍ أَحْصَيْنَٰهُ كِتَٰبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.

See all translations of this verse →

فَذُوقُوا۟ فَلَن نَّزِيدَكُمْ إِلَّا عَذَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà.

See all translations of this verse →

إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ مَفَازًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

حَدَآئِقَ وَأَعْنَٰبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ọgbà oko àti èso àjàrà,

See all translations of this verse →

وَكَوَاعِبَ أَتْرَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,

See all translations of this verse →

وَكَأْسًا دِهَاقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ife ọtí tó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).

See all translations of this verse →

لَّا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا كِذَّٰبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

جَزَآءً مِّن رَّبِّكَ عَطَآءً حِسَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).

See all translations of this verse →

رَّبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ٱلرَّحْمَٰنِ لَا يَمْلِكُونَ مِنْهُ خِطَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun tó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

يَوْمَ يَقُومُ ٱلرُّوحُ وَٱلْمَلَٰٓئِكَةُ صَفًّا لَّا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحْمَٰنُ وَقَالَ صَوَابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ tó máa ṣe wẹ́kú.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ ٱلْيَوْمُ ٱلْحَقُّ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ مَـَٔابًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَنذَرْنَٰكُمْ عَذَابًا قَرِيبًا يَوْمَ يَنظُرُ ٱلْمَرْءُ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ وَيَقُولُ ٱلْكَافِرُ يَٰلَيْتَنِى كُنتُ تُرَٰبًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fi ìyà tó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà).”

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70