Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Jinn
Súrà Al-Jinn الجن
28 verses · Mecca · revelation order 40
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ قُلْ أُوحِىَ إِلَىَّ أَنَّهُ ٱسْتَمَعَ نَفَرٌ مِّنَ ٱلْجِنِّ فَقَالُوٓا۟ إِنَّا سَمِعْنَا قُرْءَانًا عَجَبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé, dájúdájú ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú tẹ́tí (sí al-Ƙur’ān).” Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa gbọ́ al-Ƙur’ān ìyanu.
See all translations of this verse →
يَهْدِىٓ إِلَى ٱلرُّشْدِ فَـَٔامَنَّا بِهِۦ وَلَن نُّشْرِكَ بِرَبِّنَآ أَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ń ṣètọ́sọ́nà síbi ìmọ̀nà. Nítorí náà, a gbà á gbọ́. Àwa kò sì níí fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa wa (àwa kò níí ṣẹbọ).
See all translations of this verse →
وَأَنَّهُۥ تَعَٰلَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا ٱتَّخَذَ صَٰحِبَةً وَلَا وَلَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé dájúdájú títóbi Olúwa wa ga. Kò fi ẹnì kan kan ṣe aya àti ọmọ.
See all translations of this verse →
وَأَنَّهُۥ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى ٱللَّهِ شَطَطًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú òmùgọ̀ nínú wa máa ń sọ ìsọkúsọ nípa Allāhu.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا ظَنَنَّآ أَن لَّن تَقُولَ ٱلْإِنسُ وَٱلْجِنُّ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa sì ń rò pé ènìyàn àti àlùjànnú kò níí pa irọ́ mọ́ Allāhu ni.
See all translations of this verse →
وَأَنَّهُۥ كَانَ رِجَالٌ مِّنَ ٱلْإِنسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٍ مِّنَ ٱلْجِنِّ فَزَادُوهُمْ رَهَقًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé dájúdájú àwọn ọkùnrin kan nínú ènìyàn máa ń fi àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn àlùjànnú wá ààbò. Àwọn àlùjànnú sì ṣe àlékún aburú fún wọn.
See all translations of this verse →
وَأَنَّهُمْ ظَنُّوا۟ كَمَا ظَنَنتُمْ أَن لَّن يَبْعَثَ ٱللَّهُ أَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn àlùjànnú lérò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ènìyàn náà ṣe lérò pé, Allāhu kò níí gbé ẹnì kan kan dìde (lẹ́yìn ikú).
See all translations of this verse →
وَأَنَّا لَمَسْنَا ٱلسَّمَآءَ فَوَجَدْنَٰهَا مُلِئَتْ حَرَسًا شَدِيدًا وَشُهُبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa wá (ọ̀rọ̀ àyọ́gbọ́) wá sí sánmọ̀, a sì bá a tí ó ti kún fún àwọn ẹ̀ṣọ́ tó lágbára àti àwọn ògúnná.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا كُنَّا نَقْعُدُ مِنْهَا مَقَٰعِدَ لِلسَّمْعِ فَمَن يَسْتَمِعِ ٱلْـَٔانَ يَجِدْ لَهُۥ شِهَابًا رَّصَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa máa ń jókòó síbẹ̀ ní àwọn ibùdó kan fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá jọ́rọ̀ gbọ́ lásìkò yìí, ó máa rí ògúnná tó ti lúgọ dè é.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا لَا نَدْرِىٓ أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَن فِى ٱلْأَرْضِ أَمْ أَرَادَ بِهِمْ رَبُّهُمْ رَشَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa kò sì mọ̀ bóyá aburú ni wọ́n gbàlérò pẹ̀lú àwọn tó wà lórí ilẹ̀ tàbí Olúwa wọn gbèrò ìmọ̀nà fún wọn.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا مِنَّا ٱلصَّٰلِحُونَ وَمِنَّا دُونَ ذَٰلِكَ كُنَّا طَرَآئِقَ قِدَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn ẹni rere wà nínú wa. Àwọn mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn tún wà nínú wa. A wà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا ظَنَنَّآ أَن لَّن نُّعْجِزَ ٱللَّهَ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَن نُّعْجِزَهُۥ هَرَبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwa mọ àmọ̀dájú pé àwa kò lè mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Àwa kò sì lè sá mọ́ Ọn lọ́wọ́.
See all translations of this verse →
وَأَنَّا لَمَّا سَمِعْنَا ٱلْهُدَىٰٓ ءَامَنَّا بِهِۦ فَمَن يُؤْمِنۢ بِرَبِّهِۦ فَلَا يَخَافُ بَخْسًا وَلَا رَهَقًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú nígbà tí a gbọ́ nípa ìmọ̀nà (láti inú al-Ƙur’ān), a gbà á gbọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo nínú Olúwa rẹ̀, kí ó má bẹ̀rù àdínkù(nínú ẹ̀san rere) àti (àlékún) aburú.[1]
See all translations of this verse →
وَأَنَّا مِنَّا ٱلْمُسْلِمُونَ وَمِنَّا ٱلْقَٰسِطُونَ فَمَنْ أَسْلَمَ فَأُو۟لَٰٓئِكَ تَحَرَّوْا۟ رَشَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ’Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà.”
See all translations of this verse →
وَأَمَّا ٱلْقَٰسِطُونَ فَكَانُوا۟ لِجَهَنَّمَ حَطَبًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ.”
See all translations of this verse →
وَأَلَّوِ ٱسْتَقَٰمُوا۟ عَلَى ٱلطَّرِيقَةِ لَأَسْقَيْنَٰهُم مَّآءً غَدَقًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà (’Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu.
See all translations of this verse →
لِّنَفْتِنَهُمْ فِيهِ وَمَن يُعْرِضْ عَن ذِكْرِ رَبِّهِۦ يَسْلُكْهُ عَذَابًا صَعَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Allāhu máa mú un wọ inú ìyà ìnira.
See all translations of this verse →
وَأَنَّ ٱلْمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا۟ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu.[1] Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.
See all translations of this verse →
وَأَنَّهُۥ لَمَّا قَامَ عَبْدُ ٱللَّهِ يَدْعُوهُ كَادُوا۟ يَكُونُونَ عَلَيْهِ لِبَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró tó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur’ān).
See all translations of this verse →
قُلْ إِنَّمَآ أَدْعُوا۟ رَبِّى وَلَآ أُشْرِكُ بِهِۦٓ أَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un.”
See all translations of this verse →
قُلْ إِنِّى لَآ أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا رَشَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fún yín.”
See all translations of this verse →
قُلْ إِنِّى لَن يُجِيرَنِى مِنَ ٱللَّهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلْتَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan tó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀.
See all translations of this verse →
إِلَّا بَلَٰغًا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِسَٰلَٰتِهِۦ وَمَن يَعْصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَإِنَّ لَهُۥ نَارَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé ẹ̀sìn (tó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti pé (kí n̄g sì jẹ́) àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t’Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé.
See all translations of this verse →
حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوْا۟ مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ أَضْعَفُ نَاصِرًا وَأَقَلُّ عَدَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà.
See all translations of this verse →
قُلْ إِنْ أَدْرِىٓ أَقَرِيبٌ مَّا تُوعَدُونَ أَمْ يَجْعَلُ لَهُۥ رَبِّىٓ أَمَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò tó jìnnà.
See all translations of this verse →
عَٰلِمُ ٱلْغَيْبِ فَلَا يُظْهِرُ عَلَىٰ غَيْبِهِۦٓ أَحَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan
See all translations of this verse →
إِلَّا مَنِ ٱرْتَضَىٰ مِن رَّسُولٍ فَإِنَّهُۥ يَسْلُكُ مِنۢ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِۦ رَصَدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà tí ó jẹ́ Òjísẹ́.[1] Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀
See all translations of this verse →
لِّيَعْلَمَ أَن قَدْ أَبْلَغُوا۟ رِسَٰلَٰتِ رَبِّهِمْ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيْهِمْ وَأَحْصَىٰ كُلَّ شَىْءٍ عَدَدًۢا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn dé ògòńgó. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan.
See all translations of this verse →
← Súrà Nooh
Súrà Al-Muzzammil →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.