Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Qaaf
Súrà Qaaf ق
45 verses · Mecca · revelation order 34
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ قٓ وَٱلْقُرْءَانِ ٱلْمَجِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] (Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra.
See all translations of this verse →
بَلْ عَجِبُوٓا۟ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ فَقَالَ ٱلْكَٰفِرُونَ هَٰذَا شَىْءٌ عَجِيبٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni ohun ìyanu.”
See all translations of this verse →
أَءِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا ذَٰلِكَ رَجْعٌۢ بَعِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀).
See all translations of this verse →
قَدْ عَلِمْنَا مَا تَنقُصُ ٱلْأَرْضُ مِنْهُمْ وَعِندَنَا كِتَٰبٌ حَفِيظٌۢ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
See all translations of this verse →
بَلْ كَذَّبُوا۟ بِٱلْحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمْ فَهُمْ فِىٓ أَمْرٍ مَّرِيجٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú.
See all translations of this verse →
أَفَلَمْ يَنظُرُوٓا۟ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَوْقَهُمْ كَيْفَ بَنَيْنَٰهَا وَزَيَّنَّٰهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀?
See all translations of this verse →
وَٱلْأَرْضَ مَدَدْنَٰهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ وَأَنۢبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍۭ بَهِيجٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn tó dára hù jáde láti inú rẹ̀.
See all translations of this verse →
تَبْصِرَةً وَذِكْرَىٰ لِكُلِّ عَبْدٍ مُّنِيبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
See all translations of this verse →
وَنَزَّلْنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً مُّبَٰرَكًا فَأَنۢبَتْنَا بِهِۦ جَنَّٰتٍ وَحَبَّ ٱلْحَصِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n ń kórè rẹ̀ hù jáde.
See all translations of this verse →
وَٱلنَّخْلَ بَاسِقَٰتٍ لَّهَا طَلْعٌ نَّضِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì.
See all translations of this verse →
رِّزْقًا لِّلْعِبَادِ وَأَحْيَيْنَا بِهِۦ بَلْدَةً مَّيْتًا كَذَٰلِكَ ٱلْخُرُوجُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí).
See all translations of this verse →
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَأَصْحَٰبُ ٱلرَّسِّ وَثَمُودُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.
See all translations of this verse →
وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ وَإِخْوَٰنُ لُوطٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt,
See all translations of this verse →
وَأَصْحَٰبُ ٱلْأَيْكَةِ وَقَوْمُ تُبَّعٍ كُلٌّ كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì kò (lórí wọn).
See all translations of this verse →
أَفَعَيِينَا بِٱلْخَلْقِ ٱلْأَوَّلِ بَلْ هُمْ فِى لَبْسٍ مِّنْ خَلْقٍ جَدِيدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì (àti ìrújú) nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní ọ̀tun ni.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ وَنَعْلَمُ مَا تُوَسْوِسُ بِهِۦ نَفْسُهُۥ وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْ حَبْلِ ٱلْوَرِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn. A sì mọ ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń sọ fún un ní ròyíròyí. Àwa sì súnmọ́ ọn ju isan ọrùn rẹ̀.[1]
See all translations of this verse →
إِذْ يَتَلَقَّى ٱلْمُتَلَقِّيَانِ عَنِ ٱلْيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ قَعِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) nígbà tí (mọlāika) àwọn olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ méjì bá bẹ̀rẹ̀sí gba ọ̀rọ̀ (sílẹ̀), tí ọ̀kan jókòó sí ọ̀tún, tí ọ̀kan jókòó sí òsì.
See all translations of this verse →
مَّا يَلْفِظُ مِن قَوْلٍ إِلَّا لَدَيْهِ رَقِيبٌ عَتِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ẹnì kan) kò sì níí sọ ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ẹ̀ṣọ́ kan ti wà níkàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ (fún àkọsílẹ̀ rẹ̀).
See all translations of this verse →
وَجَآءَتْ سَكْرَةُ ٱلْمَوْتِ بِٱلْحَقِّ ذَٰلِكَ مَا كُنتَ مِنْهُ تَحِيدُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé ìpọ́kàkà ikú yóò dé láti fi òdodo ọ̀run rinlẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ìwọ ń sá fún.
See all translations of this verse →
وَنُفِخَ فِى ٱلصُّورِ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْوَعِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ìyẹn ni ọjọ́ ìlérí náà.
See all translations of this verse →
وَجَآءَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّعَهَا سَآئِقٌ وَشَهِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò wá pẹ̀lú olùdarí kan àti ẹlẹ́rìí kan (nínú àwọn mọlāika).
See all translations of this verse →
لَّقَدْ كُنتَ فِى غَفْلَةٍ مِّنْ هَٰذَا فَكَشَفْنَا عَنكَ غِطَآءَكَ فَبَصَرُكَ ٱلْيَوْمَ حَدِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìwọ ti wà nínú ìgbàgbéra níbi èyí. A sì ti ṣí èbìbò (ojú) rẹ kúrò fún ọ báyìí. Nítorí náà, ìríran rẹ yóò ríran kedere ní òní.
See all translations of this verse →
وَقَالَ قَرِينُهُۥ هَٰذَا مَا لَدَىَّ عَتِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Mọlāika) alábàárìn rẹ̀ yóò sọ pé: “Èyí ti wà nílẹ̀ ni ohun tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi (gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀).”
See all translations of this verse →
أَلْقِيَا فِى جَهَنَّمَ كُلَّ كَفَّارٍ عَنِيدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin mọlāika méjèèjì,[1] ẹ ju gbogbo aláìgbàgbọ́ olóríkunkun sínú iná Jahanamọ.
See all translations of this verse →
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ مُّرِيبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ẹ ju) ẹni tí ó dènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, oníyèméjì (sínú Iná).
See all translations of this verse →
ٱلَّذِى جَعَلَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَأَلْقِيَاهُ فِى ٱلْعَذَابِ ٱلشَّدِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹni tó mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, ẹ jù ú sínú ìyà líle.
See all translations of this verse →
قَالَ قَرِينُهُۥ رَبَّنَا مَآ أَطْغَيْتُهُۥ وَلَٰكِن كَانَ فِى ضَلَٰلٍۭ بَعِيدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (aṣ-Ṣaetọ̄n) alábàárìn rẹ̀ yóò wí pé: “Olúwa wa, èmi kọ́ ni mo mú un tayọ ẹnu-ààlà, ṣùgbọ́n ó ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà (sí òdodo) tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.”
See all translations of this verse →
قَالَ لَا تَخْتَصِمُوا۟ لَدَىَّ وَقَدْ قَدَّمْتُ إِلَيْكُم بِٱلْوَعِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ má se ṣàríyànjiyàn lọ́dọ̀ Mi. Mo kúkú ti ṣe ìlérí fún yín ṣíwájú.
See all translations of this verse →
مَا يُبَدَّلُ ٱلْقَوْلُ لَدَىَّ وَمَآ أَنَا۠ بِظَلَّٰمٍ لِّلْعَبِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn kò sì lè yí ọ̀rọ̀ náà padà ní ọ̀dọ̀ Mi. Èmi kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrú Mi.”
See all translations of this verse →
يَوْمَ نَقُولُ لِجَهَنَّمَ هَلِ ٱمْتَلَأْتِ وَتَقُولُ هَلْ مِن مَّزِيدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) ọjọ́ tí A óò sọ fún iná Jahanamọ pé: Ṣèbí o ti kún?” Ó sì máa sọ pé: “Ṣèbí àfikún tún wà?”
See all translations of this verse →
وَأُزْلِفَتِ ٱلْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ غَيْرَ بَعِيدٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n máa sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). Kò sì níí jìnnà (sí wọn).
See all translations of this verse →
هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِكُلِّ أَوَّابٍ حَفِيظٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Èyí ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún gbogbo olùronúpìwàdà, olùṣọ́ (òfin Allāhu).
See all translations of this verse →
مَّنْ خَشِىَ ٱلرَّحْمَٰنَ بِٱلْغَيْبِ وَجَآءَ بِقَلْبٍ مُّنِيبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Allāhu ní ìkọ̀kọ̀, tí ó tún dé pẹ̀lú ọkàn tó ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà),
See all translations of this verse →
ٱدْخُلُوهَا بِسَلَٰمٍ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْخُلُودِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (A óò sọ fún wọn pé): “Ẹ wọ inú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àlàáfíà. Ìyẹn ni ọjọ́ gbére.”
See all translations of this verse →
لَهُم مَّا يَشَآءُونَ فِيهَا وَلَدَيْنَا مَزِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohun tí wọ́n ń fẹ́ wà nínú rẹ̀. Àlékún sì tún wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
See all translations of this verse →
وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هُمْ أَشَدُّ مِنْهُم بَطْشًا فَنَقَّبُوا۟ فِى ٱلْبِلَٰدِ هَلْ مِن مَّحِيصٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí?)
See all translations of this verse →
إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِمَن كَانَ لَهُۥ قَلْبٌ أَوْ أَلْقَى ٱلسَّمْعَ وَهُوَ شَهِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀).
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ خَلَقْنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ وَمَا مَسَّنَا مِن لُّغُوبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje).
See all translations of this verse →
فَٱصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ ٱلشَّمْسِ وَقَبْلَ ٱلْغُرُوبِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ[1] ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).
See all translations of this verse →
وَمِنَ ٱلَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَأَدْبَٰرَ ٱلسُّجُودِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un.
See all translations of this verse →
وَٱسْتَمِعْ يَوْمَ يُنَادِ ٱلْمُنَادِ مِن مَّكَانٍ قَرِيبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí o sì tẹ́tí sí (ọ̀rọ̀) ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan tó súnmọ́.
See all translations of this verse →
يَوْمَ يَسْمَعُونَ ٱلصَّيْحَةَ بِٱلْحَقِّ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْخُرُوجِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè).
See all translations of this verse →
إِنَّا نَحْنُ نُحْىِۦ وَنُمِيتُ وَإِلَيْنَا ٱلْمَصِيرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
يَوْمَ تَشَقَّقُ ٱلْأَرْضُ عَنْهُمْ سِرَاعًا ذَٰلِكَ حَشْرٌ عَلَيْنَا يَسِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ tó rọrùn fún Wa.
See all translations of this verse →
نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ وَمَآ أَنتَ عَلَيْهِم بِجَبَّارٍ فَذَكِّرْ بِٱلْقُرْءَانِ مَن يَخَافُ وَعِيدِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ó ń páyà ìlérí Mi.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Hujuraat
Súrà Adh-Dhaariyat →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.