caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Burooj البروج

22 verses · Mecca · revelation order 27

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلْبُرُوجِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.

See all translations of this verse →

وَٱلْيَوْمِ ٱلْمَوْعُودِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.

See all translations of this verse →

وَشَاهِدٍ وَمَشْهُودٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.

See all translations of this verse →

قُتِلَ أَصْحَٰبُ ٱلْأُخْدُودِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),

See all translations of this verse →

ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلْوَقُودِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).

See all translations of this verse →

إِذْ هُمْ عَلَيْهَا قُعُودٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَهُمْ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ بِٱلْمُؤْمِنِينَ شُهُودٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَمَا نَقَمُوا۟ مِنْهُمْ إِلَّآ أَن يُؤْمِنُوا۟ بِٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَمِيدِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ شَهِيدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُوا۟ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَٰتِ ثُمَّ لَمْ يَتُوبُوا۟ فَلَهُمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمْ عَذَابُ ٱلْحَرِيقِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمْ جَنَّٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ ذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْكَبِيرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.

See all translations of this verse →

إِنَّ بَطْشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ هُوَ يُبْدِئُ وَيُعِيدُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).

See all translations of this verse →

وَهُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلْوَدُودُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),

See all translations of this verse →

ذُو ٱلْعَرْشِ ٱلْمَجِيدُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),

See all translations of this verse →

فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.

See all translations of this verse →

هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلْجُنُودِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,

See all translations of this verse →

فِرْعَوْنَ وَثَمُودَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?

See all translations of this verse →

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى تَكْذِيبٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSíbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.

See all translations of this verse →

وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطٌۢ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.

See all translations of this verse →

بَلْ هُوَ قُرْءَانٌ مَّجِيدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,

See all translations of this verse →

فِى لَوْحٍ مَّحْفُوظٍۭ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70