إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُوا۟ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَٰتِ ثُمَّ لَمْ يَتُوبُوا۟ فَلَهُمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمْ عَذَابُ ٱلْحَرِيقِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.