caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà At-Taariq الطارق

17 verses · Mecca · revelation order 36

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?

See all translations of this verse →

ٱلنَّجْمُ ٱلثَّاقِبُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).

See all translations of this verse →

إِن كُلُّ نَفْسٍ لَّمَّا عَلَيْهَا حَافِظٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).

See all translations of this verse →

فَلْيَنظُرِ ٱلْإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.

See all translations of this verse →

خُلِقَ مِن مَّآءٍ دَافِقٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.

See all translations of this verse →

يَخْرُجُ مِنۢ بَيْنِ ٱلصُّلْبِ وَٱلتَّرَآئِبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجْعِهِۦ لَقَادِرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀

See all translations of this verse →

يَوْمَ تُبْلَى ٱلسَّرَآئِرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.

See all translations of this verse →

فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٍ وَلَا نَاصِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.

See all translations of this verse →

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجْعِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.

See all translations of this verse →

وَٱلْأَرْضِ ذَاتِ ٱلصَّدْعِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ لَقَوْلٌ فَصْلٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).

See all translations of this verse →

وَمَا هُوَ بِٱلْهَزْلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í sì ṣe àwàdà.

See all translations of this verse →

إِنَّهُمْ يَكِيدُونَ كَيْدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọ́n ń déte gan-an.

See all translations of this verse →

وَأَكِيدُ كَيْدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi náà sì ń déte gan-an.[1]

See all translations of this verse →

فَمَهِّلِ ٱلْكَٰفِرِينَ أَمْهِلْهُمْ رُوَيْدًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70