caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Qamar القمر

55 verses · Mecca · revelation order 37

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱقْتَرَبَتِ ٱلسَّاعَةُ وَٱنشَقَّ ٱلْقَمَرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).[1]

See all translations of this verse →

وَإِن يَرَوْا۟ ءَايَةً يُعْرِضُوا۟ وَيَقُولُوا۟ سِحْرٌ مُّسْتَمِرٌّ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”[1]

See all translations of this verse →

وَكَذَّبُوا۟ وَٱتَّبَعُوٓا۟ أَهْوَآءَهُمْ وَكُلُّ أَمْرٍ مُّسْتَقِرٌّ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. [1]

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ جَآءَهُم مِّنَ ٱلْأَنۢبَآءِ مَا فِيهِ مُزْدَجَرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú[1] wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.

See all translations of this verse →

حِكْمَةٌۢ بَٰلِغَةٌ فَمَا تُغْنِ ٱلنُّذُرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ يَوْمَ يَدْعُ ٱلدَّاعِ إِلَىٰ شَىْءٍ نُّكُرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),

See all translations of this verse →

خُشَّعًا أَبْصَٰرُهُمْ يَخْرُجُونَ مِنَ ٱلْأَجْدَاثِ كَأَنَّهُمْ جَرَادٌ مُّنتَشِرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOjú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.

See all translations of this verse →

مُّهْطِعِينَ إِلَى ٱلدَّاعِ يَقُولُ ٱلْكَٰفِرُونَ هَٰذَا يَوْمٌ عَسِرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.”

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ فَكَذَّبُوا۟ عَبْدَنَا وَقَالُوا۟ مَجْنُونٌ وَٱزْدُجِرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.[1]

See all translations of this verse →

فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنِّى مَغْلُوبٌ فَٱنتَصِرْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”

See all translations of this verse →

فَفَتَحْنَآ أَبْوَٰبَ ٱلسَّمَآءِ بِمَآءٍ مُّنْهَمِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.

See all translations of this verse →

وَفَجَّرْنَا ٱلْأَرْضَ عُيُونًا فَٱلْتَقَى ٱلْمَآءُ عَلَىٰٓ أَمْرٍ قَدْ قُدِرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).

See all translations of this verse →

وَحَمَلْنَٰهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلْوَٰحٍ وَدُسُرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,

See all translations of this verse →

تَجْرِى بِأَعْيُنِنَا جَزَآءً لِّمَن كَانَ كُفِرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَد تَّرَكْنَٰهَآ ءَايَةً فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا ٱلْقُرْءَانَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ عَادٌ فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِى يَوْمِ نَحْسٍ مُّسْتَمِرٍّ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.[1]

See all translations of this verse →

تَنزِعُ ٱلنَّاسَ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ مُّنقَعِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا ٱلْقُرْءَانَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِٱلنُّذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.

See all translations of this verse →

فَقَالُوٓا۟ أَبَشَرًا مِّنَّا وَٰحِدًا نَّتَّبِعُهُۥٓ إِنَّآ إِذًا لَّفِى ضَلَٰلٍ وَسُعُرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.

See all translations of this verse →

أَءُلْقِىَ ٱلذِّكْرُ عَلَيْهِ مِنۢ بَيْنِنَا بَلْ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.”

See all translations of this verse →

سَيَعْلَمُونَ غَدًا مَّنِ ٱلْكَذَّابُ ٱلْأَشِرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.

See all translations of this verse →

إِنَّا مُرْسِلُوا۟ ٱلنَّاقَةِ فِتْنَةً لَّهُمْ فَٱرْتَقِبْهُمْ وَٱصْطَبِرْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.[1]

See all translations of this verse →

وَنَبِّئْهُمْ أَنَّ ٱلْمَآءَ قِسْمَةٌۢ بَيْنَهُمْ كُلُّ شِرْبٍ مُّحْتَضَرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.

See all translations of this verse →

فَنَادَوْا۟ صَاحِبَهُمْ فَتَعَاطَىٰ فَعَقَرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ صَيْحَةً وَٰحِدَةً فَكَانُوا۟ كَهَشِيمِ ٱلْمُحْتَظِرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا ٱلْقُرْءَانَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍۭ بِٱلنُّذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ حَاصِبًا إِلَّآ ءَالَ لُوطٍ نَّجَّيْنَٰهُم بِسَحَرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.

See all translations of this verse →

نِّعْمَةً مِّنْ عِندِنَا كَذَٰلِكَ نَجْزِى مَن شَكَرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ أَنذَرَهُم بَطْشَتَنَا فَتَمَارَوْا۟ بِٱلنُّذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ رَٰوَدُوهُ عَن ضَيْفِهِۦ فَطَمَسْنَآ أَعْيُنَهُمْ فَذُوقُوا۟ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ صَبَّحَهُم بُكْرَةً عَذَابٌ مُّسْتَقِرٌّ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.

See all translations of this verse →

فَذُوقُوا۟ عَذَابِى وَنُذُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ يَسَّرْنَا ٱلْقُرْءَانَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ جَآءَ ءَالَ فِرْعَوْنَ ٱلنُّذُرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.

See all translations of this verse →

كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا كُلِّهَا فَأَخَذْنَٰهُمْ أَخْذَ عَزِيزٍ مُّقْتَدِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).

See all translations of this verse →

أَكُفَّارُكُمْ خَيْرٌ مِّنْ أُو۟لَٰٓئِكُمْ أَمْ لَكُم بَرَآءَةٌ فِى ٱلزُّبُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?

See all translations of this verse →

أَمْ يَقُولُونَ نَحْنُ جَمِيعٌ مُّنتَصِرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)”

See all translations of this verse →

سَيُهْزَمُ ٱلْجَمْعُ وَيُوَلُّونَ ٱلدُّبُرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.

See all translations of this verse →

بَلِ ٱلسَّاعَةُ مَوْعِدُهُمْ وَٱلسَّاعَةُ أَدْهَىٰ وَأَمَرُّ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُجْرِمِينَ فِى ضَلَٰلٍ وَسُعُرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.

See all translations of this verse →

يَوْمَ يُسْحَبُونَ فِى ٱلنَّارِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ ذُوقُوا۟ مَسَّ سَقَرَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.

See all translations of this verse →

إِنَّا كُلَّ شَىْءٍ خَلَقْنَٰهُ بِقَدَرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَمْرُنَآ إِلَّا وَٰحِدَةٌ كَلَمْحٍۭ بِٱلْبَصَرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.[1]

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ أَهْلَكْنَآ أَشْيَاعَكُمْ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

See all translations of this verse →

وَكُلُّ شَىْءٍ فَعَلُوهُ فِى ٱلزُّبُرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.

See all translations of this verse →

وَكُلُّ صَغِيرٍ وَكَبِيرٍ مُّسْتَطَرٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى جَنَّٰتٍ وَنَهَرٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

See all translations of this verse →

فِى مَقْعَدِ صِدْقٍ عِندَ مَلِيكٍ مُّقْتَدِرٍۭ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70