Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Ad-Dukhaan
Súrà Ad-Dukhaan الدخان
59 verses · Mecca · revelation order 64
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ حمٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
See all translations of this verse →
وَٱلْكِتَٰبِ ٱلْمُبِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
See all translations of this verse →
إِنَّآ أَنزَلْنَٰهُ فِى لَيْلَةٍ مُّبَٰرَكَةٍ إِنَّا كُنَّا مُنذِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún.[1] Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀.
See all translations of this verse →
فِيهَا يُفْرَقُ كُلُّ أَمْرٍ حَكِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá).
See all translations of this verse →
أَمْرًا مِّنْ عِندِنَآ إِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
See all translations of this verse →
رَحْمَةً مِّن رَّبِّكَ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
See all translations of this verse →
رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.
See all translations of this verse →
لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ رَبُّكُمْ وَرَبُّ ءَابَآئِكُمُ ٱلْأَوَّلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
See all translations of this verse →
بَلْ هُمْ فِى شَكٍّ يَلْعَبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré.
See all translations of this verse →
فَٱرْتَقِبْ يَوْمَ تَأْتِى ٱلسَّمَآءُ بِدُخَانٍ مُّبِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá.
See all translations of this verse →
يَغْشَى ٱلنَّاسَ هَٰذَا عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
See all translations of this verse →
رَّبَّنَا ٱكْشِفْ عَنَّا ٱلْعَذَابَ إِنَّا مُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo.
See all translations of this verse →
أَنَّىٰ لَهُمُ ٱلذِّكْرَىٰ وَقَدْ جَآءَهُمْ رَسُولٌ مُّبِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn.
See all translations of this verse →
ثُمَّ تَوَلَّوْا۟ عَنْهُ وَقَالُوا۟ مُعَلَّمٌ مَّجْنُونٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè tí àwọn ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni.”
See all translations of this verse →
إِنَّا كَاشِفُوا۟ ٱلْعَذَابِ قَلِيلًا إِنَّكُمْ عَآئِدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́).
See all translations of this verse →
يَوْمَ نَبْطِشُ ٱلْبَطْشَةَ ٱلْكُبْرَىٰٓ إِنَّا مُنتَقِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú tó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn).
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ فَتَنَّا قَبْلَهُمْ قَوْمَ فِرْعَوْنَ وَجَآءَهُمْ رَسُولٌ كَرِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn.
See all translations of this verse →
أَنْ أَدُّوٓا۟ إِلَىَّ عِبَادَ ٱللَّهِ إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.
See all translations of this verse →
وَأَن لَّا تَعْلُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ إِنِّىٓ ءَاتِيكُم بِسُلْطَٰنٍ مُّبِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín.
See all translations of this verse →
وَإِنِّى عُذْتُ بِرَبِّى وَرَبِّكُمْ أَن تَرْجُمُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí ní òkò.
See all translations of this verse →
وَإِن لَّمْ تُؤْمِنُوا۟ لِى فَٱعْتَزِلُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́.”
See all translations of this verse →
فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنَّ هَٰٓؤُلَآءِ قَوْمٌ مُّجْرِمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀.
See all translations of this verse →
فَأَسْرِ بِعِبَادِى لَيْلًا إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu sọ pé): “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn.
See all translations of this verse →
وَٱتْرُكِ ٱلْبَحْرَ رَهْوًا إِنَّهُمْ جُندٌ مُّغْرَقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí o sì fi agbami òkun náà sílẹ̀ (ná) kí ó dákẹ́ rọ́rọ́ láì níí ru (kí ojú ọ̀nà tí ẹ tọ̀ nínú rẹ̀ lè wà bẹ́ẹ̀, kí Fir‘aon àti ọmọ-ogun rẹ̀ lè kó sójú-ọ̀nà náà). Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú rẹ̀.
See all translations of this verse →
كَمْ تَرَكُوا۟ مِن جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn).
See all translations of this verse →
وَزُرُوعٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀).
See all translations of this verse →
وَنَعْمَةٍ كَانُوا۟ فِيهَا فَٰكِهِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn).
See all translations of this verse →
كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَٰهَا قَوْمًا ءَاخَرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn.
See all translations of this verse →
فَمَا بَكَتْ عَلَيْهِمُ ٱلسَّمَآءُ وَٱلْأَرْضُ وَمَا كَانُوا۟ مُنظَرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ نَجَّيْنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ مِنَ ٱلْعَذَابِ ٱلْمُهِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ.
See all translations of this verse →
مِن فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ كَانَ عَالِيًا مِّنَ ٱلْمُسْرِفِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ.
See all translations of this verse →
وَلَقَدِ ٱخْتَرْنَٰهُمْ عَلَىٰ عِلْمٍ عَلَى ٱلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀ (tí a mọ̀ nípa wọn).[1]
See all translations of this verse →
وَءَاتَيْنَٰهُم مِّنَ ٱلْـَٔايَٰتِ مَا فِيهِ بَلَٰٓؤٌا۟ مُّبِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَيَقُولُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé:
See all translations of this verse →
إِنْ هِىَ إِلَّا مَوْتَتُنَا ٱلْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُنشَرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael “Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde.
See all translations of this verse →
فَأْتُوا۟ بِـَٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
See all translations of this verse →
أَهُمْ خَيْرٌ أَمْ قَوْمُ تُبَّعٍ وَٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ أَهْلَكْنَٰهُمْ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ مُجْرِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn tó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
See all translations of this verse →
وَمَا خَلَقْنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَٰعِبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
See all translations of this verse →
مَا خَلَقْنَٰهُمَآ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ يَوْمَ ٱلْفَصْلِ مِيقَٰتُهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá.
See all translations of this verse →
يَوْمَ لَا يُغْنِى مَوْلًى عَن مَّوْلًى شَيْـًٔا وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
See all translations of this verse →
إِلَّا مَن رَّحِمَ ٱللَّهُ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
See all translations of this verse →
إِنَّ شَجَرَتَ ٱلزَّقُّومِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú igi zaƙūm
See all translations of this verse →
طَعَامُ ٱلْأَثِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.
See all translations of this verse →
كَٱلْمُهْلِ يَغْلِى فِى ٱلْبُطُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó dà bí ògéré epo gbígbóná tí ń hó nínú ikùn
See all translations of this verse →
كَغَلْىِ ٱلْحَمِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (tó) dà bí híhó omi tó gbóná gan-an.
See all translations of this verse →
خُذُوهُ فَٱعْتِلُوهُ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلْجَحِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm.
See all translations of this verse →
ثُمَّ صُبُّوا۟ فَوْقَ رَأْسِهِۦ مِنْ عَذَابِ ٱلْحَمِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí.
See all translations of this verse →
ذُقْ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْكَرِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ).
See all translations of this verse →
إِنَّ هَٰذَا مَا كُنتُم بِهِۦ تَمْتَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى مَقَامٍ أَمِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀.
See all translations of this verse →
فِى جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
See all translations of this verse →
يَلْبَسُونَ مِن سُندُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُّتَقَٰبِلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán tó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn (sọ̀rọ̀).
See all translations of this verse →
كَذَٰلِكَ وَزَوَّجْنَٰهُم بِحُورٍ عِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn.
See all translations of this verse →
يَدْعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَٰكِهَةٍ ءَامِنِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀.
See all translations of this verse →
لَا يَذُوقُونَ فِيهَا ٱلْمَوْتَ إِلَّا ٱلْمَوْتَةَ ٱلْأُولَىٰ وَوَقَىٰهُمْ عَذَابَ ٱلْجَحِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm.
See all translations of this verse →
فَضْلًا مِّن رَّبِّكَ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
See all translations of this verse →
فَإِنَّمَا يَسَّرْنَٰهُ بِلِسَانِكَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
See all translations of this verse →
فَٱرْتَقِبْ إِنَّهُم مُّرْتَقِبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, máa retí[1]. Dájúdájú àwọn náà ń retí.
See all translations of this verse →
← Súrà Az-Zukhruf
Súrà Al-Jaathiya →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.