ٱلَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلْإِثْمِ وَٱلْفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلْمَغْفِرَةِ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلْأَرْضِ وَإِذْ أَنتُمْ أَجِنَّةٌ فِى بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمْ فَلَا تُزَكُّوٓا۟ أَنفُسَكُمْ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́.[1] Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).