caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ash-Shu'araa الشعراء

227 verses · Mecca · revelation order 47

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ طسٓمٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]

See all translations of this verse →

تِلْكَ ءَايَٰتُ ٱلْكِتَٰبِ ٱلْمُبِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

لَعَلَّكَ بَٰخِعٌ نَّفْسَكَ أَلَّا يَكُونُوا۟ مُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

إِن نَّشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ ءَايَةً فَظَلَّتْ أَعْنَٰقُهُمْ لَهَا خَٰضِعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.

See all translations of this verse →

وَمَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّنَ ٱلرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا۟ عَنْهُ مُعْرِضِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.

See all translations of this verse →

فَقَدْ كَذَّبُوا۟ فَسَيَأْتِيهِمْ أَنۢبَٰٓؤُا۟ مَا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَى ٱلْأَرْضِ كَمْ أَنۢبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱئْتِ ٱلْقَوْمَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: “Lọ bá ìjọ alábòsí,

See all translations of this verse →

قَوْمَ فِرْعَوْنَ أَلَا يَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé, ‘Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.’ ”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ إِنِّىٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

وَيَضِيقُ صَدْرِى وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِى فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَٰرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.

See all translations of this verse →

وَلَهُمْ عَلَىَّ ذَنۢبٌ فَأَخَافُ أَن يَقْتُلُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.”

See all translations of this verse →

قَالَ كَلَّا فَٱذْهَبَا بِـَٔايَٰتِنَآ إِنَّا مَعَكُم مُّسْتَمِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).

See all translations of this verse →

فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولُ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَنْ أَرْسِلْ مَعَنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.”

See all translations of this verse →

قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?

See all translations of this verse →

وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ ٱلَّتِى فَعَلْتَ وَأَنتَ مِنَ ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelO sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَعَلْتُهَآ إِذًا وَأَنَا۠ مِنَ ٱلضَّآلِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláṣìṣe (èmi kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é).

See all translations of this verse →

فَفَرَرْتُ مِنكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِى رَبِّى حُكْمًا وَجَعَلَنِى مِنَ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo sì sá fún yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Lẹ́yìn náà, Allāhu ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَىَّ أَنْ عَبَّدتَّ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).[1]

See all translations of this verse →

قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”

See all translations of this verse →

قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُۥٓ أَلَا تَسْتَمِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí fún àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (tó ń sọ ni)?”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ ءَابَآئِكُمُ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

See all translations of this verse →

قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ ٱلَّذِىٓ أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبُّ ٱلْمَشْرِقِ وَٱلْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”

See all translations of this verse →

قَالَ لَئِنِ ٱتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِى لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ ٱلْمَسْجُونِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”

See all translations of this verse →

قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكَ بِشَىْءٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan tó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”

See all translations of this verse →

قَالَ فَأْتِ بِهِۦٓ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

See all translations of this verse →

فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِىَ ثُعْبَانٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

وَنَزَعَ يَدَهُۥ فَإِذَا هِىَ بَيْضَآءُ لِلنَّٰظِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.

See all translations of this verse →

قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُۥٓ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٌ عَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.

See all translations of this verse →

يُرِيدُ أَن يُخْرِجَكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِۦ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fẹ́ fi idán rẹ̀ kó yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”[1]

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَٱبْعَثْ فِى ٱلْمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ[1] sí àwọn ìlú

See all translations of this verse →

يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ.”

See all translations of this verse →

فَجُمِعَ ٱلسَّحَرَةُ لِمِيقَٰتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.

See all translations of this verse →

وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلْ أَنتُم مُّجْتَمِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: “Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?

See all translations of this verse →

لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ ٱلسَّحَرَةَ إِن كَانُوا۟ هُمُ ٱلْغَٰلِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí.”

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالُوا۟ لِفِرْعَوْنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِن كُنَّا نَحْنُ ٱلْغَٰلِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”

See all translations of this verse →

قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ إِذًا لَّمِنَ ٱلْمُقَرَّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”

See all translations of this verse →

قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلْقُوا۟ مَآ أَنتُم مُّلْقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”

See all translations of this verse →

فَأَلْقَوْا۟ حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا۟ بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ ٱلْغَٰلِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”

See all translations of this verse →

فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِىَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.

See all translations of this verse →

فَأُلْقِىَ ٱلسَّحَرَةُ سَٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ ءَامَنَّا بِرَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,

See all translations of this verse →

رَبِّ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.”

See all translations of this verse →

قَالَ ءَامَنتُمْ لَهُۥ قَبْلَ أَنْ ءَاذَنَ لَكُمْ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِى عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحْرَ فَلَسَوْفَ تَعْلَمُونَ لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَٰفٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ لَا ضَيْرَ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.

See all translations of this verse →

إِنَّا نَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَٰيَٰنَآ أَن كُنَّآ أَوَّلَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”[1]

See all translations of this verse →

وَأَوْحَيْنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِىٓ إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé), dájúdájú wọn yóò lépa yín.”

See all translations of this verse →

فَأَرْسَلَ فِرْعَوْنُ فِى ٱلْمَدَآئِنِ حَٰشِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَشِرْذِمَةٌ قَلِيلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael“Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُمْ لَنَا لَغَآئِظُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun tó ń bí wa nínú.

See all translations of this verse →

وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَٰذِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura.”

See all translations of this verse →

فَأَخْرَجْنَٰهُم مِّن جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,

See all translations of this verse →

وَكُنُوزٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ilé ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.

See all translations of this verse →

كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَٰهَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

See all translations of this verse →

فَأَتْبَعُوهُم مُّشْرِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.

See all translations of this verse →

فَلَمَّا تَرَٰٓءَا ٱلْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَٰبُ مُوسَىٰٓ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”

See all translations of this verse →

قَالَ كَلَّآ إِنَّ مَعِىَ رَبِّى سَيَهْدِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”

See all translations of this verse →

فَأَوْحَيْنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱضْرِب بِّعَصَاكَ ٱلْبَحْرَ فَٱنفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَٱلطَّوْدِ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà án). Ó sì pín (sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).[1] Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.

See all translations of this verse →

وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ ٱلْـَٔاخَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.

See all translations of this verse →

وَأَنجَيْنَا مُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.

See all translations of this verse →

ثُمَّ أَغْرَقْنَا ٱلْـَٔاخَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَٱتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَٰهِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKa ìtàn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِۦ مَا تَعْبُدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ نَعْبُدُ أَصْنَامًا فَنَظَلُّ لَهَا عَٰكِفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”

See all translations of this verse →

قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?

See all translations of this verse →

أَوْ يَنفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní àǹfààní tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ بَلْ وَجَدْنَآ ءَابَآءَنَا كَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”

See all translations of this verse →

قَالَ أَفَرَءَيْتُم مَّا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “ Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,

See all translations of this verse →

أَنتُمْ وَءَابَآؤُكُمُ ٱلْأَقْدَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelẹ̀yin àti àwọn bàbá yín àwọn ẹni ìṣáájú?

See all translations of this verse →

فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِّىٓ إِلَّا رَبَّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى خَلَقَنِى فَهُوَ يَهْدِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِى هُوَ يُطْعِمُنِى وَيَسْقِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tó ń fún mi ní jíjẹ, tó ń fún mi ní mímu;

See all translations of this verse →

وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِى يُمِيتُنِى ثُمَّ يُحْيِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِىٓ أَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لِى خَطِيٓـَٔتِى يَوْمَ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.

See all translations of this verse →

رَبِّ هَبْ لِى حُكْمًا وَأَلْحِقْنِى بِٱلصَّٰلِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.

See all translations of this verse →

وَٱجْعَل لِّى لِسَانَ صِدْقٍ فِى ٱلْـَٔاخِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFi òdodo sórí ahọ́n àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi nìpa mi (ìyẹn ni pé, jẹ́ kí àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi máa sọ̀rọ̀ mi ní dáadáa).[1]

See all translations of this verse →

وَٱجْعَلْنِى مِن وَرَثَةِ جَنَّةِ ٱلنَّعِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.

See all translations of this verse →

وَٱغْفِرْ لِأَبِىٓ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلضَّآلِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.

See all translations of this verse →

وَلَا تُخْزِنِى يَوْمَ يُبْعَثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.

See all translations of this verse →

يَوْمَ لَا يَنفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.

See all translations of this verse →

إِلَّا مَنْ أَتَى ٱللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́.”[1]

See all translations of this verse →

وَأُزْلِفَتِ ٱلْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

وَبُرِّزَتِ ٱلْجَحِيمُ لِلْغَاوِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,

See all translations of this verse →

وَقِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelwọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”

See all translations of this verse →

مِن دُونِ ٱللَّهِ هَلْ يَنصُرُونَكُمْ أَوْ يَنتَصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?

See all translations of this verse →

فَكُبْكِبُوا۟ فِيهَا هُمْ وَٱلْغَاوُۥنَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì máa taari gbogbo wọn ṣubú sínú Iná; àwọn (olùṣìnà) àti àwọn ọ̀gá wọn (nínú ìṣìnà),

See all translations of this verse →

وَجُنُودُ إِبْلِيسَ أَجْمَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ وَهُمْ فِيهَا يَخْتَصِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:

See all translations of this verse →

تَٱللَّهِ إِن كُنَّا لَفِى ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael“A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

See all translations of this verse →

إِذْ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَضَلَّنَآ إِلَّا ٱلْمُجْرِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (aṣ-ṣaetọ̄n) ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

فَمَا لَنَا مِن شَٰفِعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa mọ́.

See all translations of this verse →

وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)

See all translations of this verse →

فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ قَوْمُ نُوحٍ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

See all translations of this verse →

إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ أَنُؤْمِنُ لَكَ وَٱتَّبَعَكَ ٱلْأَرْذَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”

See all translations of this verse →

قَالَ وَمَا عِلْمِى بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).

See all translations of this verse →

إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّى لَوْ تَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.

See all translations of this verse →

إِنْ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَٰنُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلْمَرْجُومِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوْمِى كَذَّبُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

فَٱفْتَحْ بَيْنِى وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِى وَمَن مَّعِىَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

See all translations of this verse →

فَأَنجَيْنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِى ٱلْفُلْكِ ٱلْمَشْحُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA la òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.

See all translations of this verse →

ثُمَّ أَغْرَقْنَا بَعْدُ ٱلْبَاقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A tẹ àwọn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn wọn rì sínú omi.

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ عَادٌ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

See all translations of this verse →

إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَتَبْنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ ءَايَةً تَعْبَثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?

See all translations of this verse →

وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمْ تَخْلُدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).

See all translations of this verse →

وَإِذَا بَطَشْتُم بَطَشْتُمْ جَبَّارِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَٱتَّقُوا۟ ٱلَّذِىٓ أَمَدَّكُم بِمَا تَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;

See all translations of this verse →

أَمَدَّكُم بِأَنْعَٰمٍ وَبَنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,

See all translations of this verse →

وَجَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.

See all translations of this verse →

إِنِّىٓ أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fún yín.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ سَوَآءٌ عَلَيْنَآ أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُن مِّنَ ٱلْوَٰعِظِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o ṣe wáàsí fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn oníwáàsí.”

See all translations of this verse →

إِنْ هَٰذَآ إِلَّا خُلُقُ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael- Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.[1] –

See all translations of this verse →

وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò sì níí jẹ wá níyà.”

See all translations of this verse →

فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَٰهُمْ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ ثَمُودُ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ صَٰلِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

See all translations of this verse →

إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَتُتْرَكُونَ فِى مَا هَٰهُنَآ ءَامِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀

See all translations of this verse →

فِى جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.

See all translations of this verse →

وَزُرُوعٍ وَنَخْلٍ طَلْعُهَا هَضِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí àwọn èso wọn ti gbó?

See all translations of this verse →

وَتَنْحِتُونَ مِنَ ٱلْجِبَالِ بُيُوتًا فَٰرِهِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ olùgbéraga!

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَلَا تُطِيعُوٓا۟ أَمْرَ ٱلْمُسْرِفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn alákọyọ (aláṣejù),

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يُفْسِدُونَ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلْمُسَحَّرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

See all translations of this verse →

مَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا فَأْتِ بِـَٔايَةٍ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

See all translations of this verse →

قَالَ هَٰذِهِۦ نَاقَةٌ لَّهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀ (ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).

See all translations of this verse →

وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”

See all translations of this verse →

فَعَقَرُوهَا فَأَصْبَحُوا۟ نَٰدِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.

See all translations of this verse →

فَأَخَذَهُمُ ٱلْعَذَابُ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

See all translations of this verse →

إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَتَأْتُونَ ٱلذُّكْرَانَ مِنَ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?

See all translations of this verse →

وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُم مِّنْ أَزْوَٰجِكُم بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fún yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَٰلُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلْمُخْرَجِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”

See all translations of this verse →

قَالَ إِنِّى لِعَمَلِكُم مِّنَ ٱلْقَالِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkórira sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.

See all translations of this verse →

رَبِّ نَجِّنِى وَأَهْلِى مِمَّا يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú).”

See all translations of this verse →

فَنَجَّيْنَٰهُ وَأَهْلَهُۥٓ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.

See all translations of this verse →

إِلَّا عَجُوزًا فِى ٱلْغَٰبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]

See all translations of this verse →

ثُمَّ دَمَّرْنَا ٱلْـَٔاخَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.

See all translations of this verse →

وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا فَسَآءَ مَطَرُ ٱلْمُنذَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

كَذَّبَ أَصْحَٰبُ لْـَٔيْكَةِ ٱلْمُرْسَلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

See all translations of this verse →

إِنِّى لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

See all translations of this verse →

فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَوْفُوا۟ ٱلْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا۟ مِنَ ٱلْمُخْسِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn tó ń dín òṣùwọ̀n kù.

See all translations of this verse →

وَزِنُوا۟ بِٱلْقِسْطَاسِ ٱلْمُسْتَقِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọn n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

وَلَا تَبْخَسُوا۟ ٱلنَّاسَ أَشْيَآءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا۟ فِى ٱلْأَرْضِ مُفْسِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.

See all translations of this verse →

وَٱتَّقُوا۟ ٱلَّذِى خَلَقَكُمْ وَٱلْجِبِلَّةَ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلْمُسَحَّرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ ٱلْكَٰذِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a kò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.

See all translations of this verse →

فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّىٓ أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ ٱلظُّلَّةِ إِنَّهُۥ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَتَنزِيلُ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

نَزَلَ بِهِ ٱلرُّوحُ ٱلْأَمِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀

See all translations of this verse →

عَلَىٰ قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ ٱلْمُنذِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelsínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀

See all translations of this verse →

بِلِسَانٍ عَرَبِىٍّ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelpẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَفِى زُبُرِ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَكُن لَّهُمْ ءَايَةً أَن يَعْلَمَهُۥ عُلَمَٰٓؤُا۟ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?[1]

See all translations of this verse →

وَلَوْ نَزَّلْنَٰهُ عَلَىٰ بَعْضِ ٱلْأَعْجَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,

See all translations of this verse →

فَقَرَأَهُۥ عَلَيْهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ مُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.

See all translations of this verse →

كَذَٰلِكَ سَلَكْنَٰهُ فِى قُلُوبِ ٱلْمُجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

لَا يُؤْمِنُونَ بِهِۦ حَتَّىٰ يَرَوُا۟ ٱلْعَذَابَ ٱلْأَلِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

See all translations of this verse →

فَيَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.

See all translations of this verse →

فَيَقُولُوا۟ هَلْ نَحْنُ مُنظَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà ni wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?”

See all translations of this verse →

أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?[1]

See all translations of this verse →

أَفَرَءَيْتَ إِن مَّتَّعْنَٰهُمْ سِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!

See all translations of this verse →

ثُمَّ جَآءَهُم مَّا كَانُوا۟ يُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní ìlérí fún wọn dé bá wọn.

See all translations of this verse →

مَآ أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يُمَتَّعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنذِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.

See all translations of this verse →

ذِكْرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.

See all translations of this verse →

وَمَا تَنَزَّلَتْ بِهِ ٱلشَّيَٰطِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í ṣe àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَا يَنۢبَغِى لَهُمْ وَمَا يَسْتَطِيعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّهُمْ عَنِ ٱلسَّمْعِ لَمَعْزُولُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).

See all translations of this verse →

فَلَا تَدْعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَكُونَ مِنَ ٱلْمُعَذَّبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.

See all translations of this verse →

وَأَنذِرْ عَشِيرَتَكَ ٱلْأَقْرَبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ tó súnmọ́ jùlọ.

See all translations of this verse →

وَٱخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّى بَرِىٓءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”

See all translations of this verse →

وَتَوَكَّلْ عَلَى ٱلْعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى يَرَىٰكَ حِينَ تَقُومُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)

See all translations of this verse →

وَتَقَلُّبَكَ فِى ٱلسَّٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

هَلْ أُنَبِّئُكُمْ عَلَىٰ مَن تَنَزَّلُ ٱلشَّيَٰطِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn aṣ-ṣaetọ̄n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá fún yín?

See all translations of this verse →

تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

يُلْقُونَ ٱلسَّمْعَ وَأَكْثَرُهُمْ كَٰذِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn aṣ-ṣaetọ̄n) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.

See all translations of this verse →

وَٱلشُّعَرَآءُ يَتَّبِعُهُمُ ٱلْغَاوُۥنَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ أَنَّهُمْ فِى كُلِّ وَادٍ يَهِيمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?

See all translations of this verse →

وَأَنَّهُمْ يَقُولُونَ مَا لَا يَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَذَكَرُوا۟ ٱللَّهَ كَثِيرًا وَٱنتَصَرُوا۟ مِنۢ بَعْدِ مَا ظُلِمُوا۟ وَسَيَعْلَمُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓا۟ أَىَّ مُنقَلَبٍ يَنقَلِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn tó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70