caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Naml النمل

93 verses · Mecca · revelation order 48

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ طسٓ تِلْكَ ءَايَٰتُ ٱلْقُرْءَانِ وَكِتَابٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTọ̄ sīn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur’ān àti (àwọn āyah) Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

هُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤْتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلْـَٔاخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱلْـَٔاخِرَةِ زَيَّنَّا لَهُمْ أَعْمَٰلَهُمْ فَهُمْ يَعْمَهُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà.

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَهُمْ سُوٓءُ ٱلْعَذَابِ وَهُمْ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ هُمُ ٱلْأَخْسَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

See all translations of this verse →

وَإِنَّكَ لَتُلَقَّى ٱلْقُرْءَانَ مِن لَّدُنْ حَكِيمٍ عَلِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِأَهْلِهِۦٓ إِنِّىٓ ءَانَسْتُ نَارًا سَـَٔاتِيكُم مِّنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ ءَاتِيكُم بِشِهَابٍ قَبَسٍ لَّعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fún yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan tó ń tanná wá fún yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná.

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَهَا نُودِىَ أَنۢ بُورِكَ مَن فِى ٱلنَّارِ وَمَنْ حَوْلَهَا وَسُبْحَٰنَ ٱللَّهِ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّهُۥٓ أَنَا ٱللَّهُ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMūsā, dájúdájú (ẹni tí ó ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَأَلْقِ عَصَاكَ فَلَمَّا رَءَاهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَآنٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ يَٰمُوسَىٰ لَا تَخَفْ إِنِّى لَا يَخَافُ لَدَىَّ ٱلْمُرْسَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelJu ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ. Kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi.

See all translations of this verse →

إِلَّا مَن ظَلَمَ ثُمَّ بَدَّلَ حُسْنًۢا بَعْدَ سُوٓءٍ فَإِنِّى غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí,[1] lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَأَدْخِلْ يَدَكَ فِى جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَآءَ مِنْ غَيْرِ سُوٓءٍ فِى تِسْعِ ءَايَٰتٍ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَقَوْمِهِۦٓ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَوْمًا فَٰسِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَتْهُمْ ءَايَٰتُنَا مُبْصِرَةً قَالُوا۟ هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn àmì Wa tó fojú hàn kedere sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

وَجَحَدُوا۟ بِهَا وَٱسْتَيْقَنَتْهَآ أَنفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا فَٱنظُرْ كَيْفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلْمُفْسِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n fi àbòsí àti ìgbéraga takò ó, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا دَاوُۥدَ وَسُلَيْمَٰنَ عِلْمًا وَقَالَا ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ٱلَّذِى فَضَّلَنَا عَلَىٰ كَثِيرٍ مِّنْ عِبَادِهِ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fún (Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n ní ìmọ̀. Àwọn méjèèjì sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún wa ní oore àjùlọ lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

See all translations of this verse →

وَوَرِثَ سُلَيْمَٰنُ دَاوُۥدَ وَقَالَ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ عُلِّمْنَا مَنطِقَ ٱلطَّيْرِ وَأُوتِينَا مِن كُلِّ شَىْءٍ إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلْفَضْلُ ٱلْمُبِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Sulaemọ̄n sì jogún (Ànábì) Dāwūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi ohùn ẹyẹ mọ̀ wá. Wọ́n sì fún wa nínú gbogbo n̄ǹkan.[1] Dájúdájú èyí, òhun ni oore àjùlọ pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

وَحُشِرَ لِسُلَيْمَٰنَ جُنُودُهُۥ مِنَ ٱلْجِنِّ وَٱلْإِنسِ وَٱلطَّيْرِ فَهُمْ يُوزَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń bá a rìn káàkiri

See all translations of this verse →

حَتَّىٰٓ إِذَآ أَتَوْا۟ عَلَىٰ وَادِ ٱلنَّمْلِ قَالَتْ نَمْلَةٌ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّمْلُ ٱدْخُلُوا۟ مَسَٰكِنَكُمْ لَا يَحْطِمَنَّكُمْ سُلَيْمَٰنُ وَجُنُودُهُۥ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltítí wọ́n fi dé àfonúfojì àwọn àwúrèbe. Àwúrèbe kan sì wí pé: “Ẹ̀yin àwúrèbe, ẹ wọ inú ilé yín lọ, kí (Ànábì) Sulaemọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ má baà tẹ̀ yín rẹ́ mọ́lẹ̀. Wọn kò sì níí furamọ̀.”

See all translations of this verse →

فَتَبَسَّمَ ضَاحِكًا مِّن قَوْلِهَا وَقَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِىٓ أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ ٱلَّتِىٓ أَنْعَمْتَ عَلَىَّ وَعَلَىٰ وَٰلِدَىَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَٰلِحًا تَرْضَىٰهُ وَأَدْخِلْنِى بِرَحْمَتِكَ فِى عِبَادِكَ ٱلصَّٰلِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀rín pa á nítorí ọ̀rọ̀ (àwúrèbe náà). Ó sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí bí mo ṣe máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí O fi ṣe ìdẹ̀ra fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì. (Fi mọ̀ mí) bí mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Pẹ̀lú àánú Rẹ, fi mí sáààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni rere.”

See all translations of this verse →

وَتَفَقَّدَ ٱلطَّيْرَ فَقَالَ مَا لِىَ لَآ أَرَى ٱلْهُدْهُدَ أَمْ كَانَ مِنَ ٱلْغَآئِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ yẹ àwọn ẹyẹ wò, ó sì sọ pé: “Nítorí kí ni èmi kò ṣe rí ẹyẹ hudhuda? Àbí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí kò wá ni?

See all translations of this verse →

لَأُعَذِّبَنَّهُۥ عَذَابًا شَدِيدًا أَوْ لَأَا۟ذْبَحَنَّهُۥٓ أَوْ لَيَأْتِيَنِّى بِسُلْطَٰنٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú mo máa jẹ ẹ́ níyà líle, tàbí kí n̄g dúńbú rẹ̀, tàbí kí ó mú ẹ̀rí tó yanjú wá fún mi.”

See all translations of this verse →

فَمَكَثَ غَيْرَ بَعِيدٍ فَقَالَ أَحَطتُ بِمَا لَمْ تُحِطْ بِهِۦ وَجِئْتُكَ مِن سَبَإٍۭ بِنَبَإٍ يَقِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Sulaemọ̄n) kò dúró pẹ́ (títí ó fi dé), ó sì wí pé: “Mo mọ n̄ǹkan tí o ò mọ̀. Mo sì mú ìró kan tó dájú wá bá ọ láti ìlú Saba’i.

See all translations of this verse →

إِنِّى وَجَدتُّ ٱمْرَأَةً تَمْلِكُهُمْ وَأُوتِيَتْ مِن كُلِّ شَىْءٍ وَلَهَا عَرْشٌ عَظِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èmi bá obìnrin kan (ní ìlú Saba’i), tó ń jọba lé wọn lórí. Wọ́n fún un ní gbogbo n̄ǹkan. Ó sì ní ìtẹ́ ńlá kan.

See all translations of this verse →

وَجَدتُّهَا وَقَوْمَهَا يَسْجُدُونَ لِلشَّمْسِ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيْطَٰنُ أَعْمَٰلَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ ٱلسَّبِيلِ فَهُمْ لَا يَهْتَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo sì bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún òòrùn lẹ́yìn Allāhu. Aṣ-ṣaetọ̄n sì ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (òdodo). Nítorí náà, wọn kò sì mọ̀nà.

See all translations of this verse →

أَلَّا يَسْجُدُوا۟ لِلَّهِ ٱلَّذِى يُخْرِجُ ٱلْخَبْءَ فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُخْفُونَ وَمَا تُعْلِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Aṣ-ṣaetọ̄n ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn) torí kí wọ́n má lè forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tó ń mú ohùn tó pamọ́ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ jáde, Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn.

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ ٱلْعَرْشِ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ ńlá.”

See all translations of this verse →

قَالَ سَنَنظُرُ أَصَدَقْتَ أَمْ كُنتَ مِنَ ٱلْكَٰذِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “A máa wòye bóyá òdodo l’o sọ tàbí o wà nínú àwọn òpùrọ́.

See all translations of this verse →

ٱذْهَب بِّكِتَٰبِى هَٰذَا فَأَلْقِهْ إِلَيْهِمْ ثُمَّ تَوَلَّ عَنْهُمْ فَٱنظُرْ مَاذَا يَرْجِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMú ìwé mi yìí lọ, kí o jù ú sí wọn. Lẹ́yìn náà, kí o takété sí wọn, kí o sì wo ohun tí wọn yóò dá padà (ní èsì).”

See all translations of this verse →

قَالَتْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمَلَؤُا۟ إِنِّىٓ أُلْقِىَ إِلَىَّ كِتَٰبٌ كَرِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, dájúdájú wọ́n ti ju ìwé alápọ̀n-ọ́nlé kan sí mi.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ مِن سُلَيْمَٰنَ وَإِنَّهُۥ بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ó wá láti ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n. Dájúdájú ó (sọ pé) “Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

أَلَّا تَعْلُوا۟ عَلَىَّ وَأْتُونِى مُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ẹ má ṣègbéraga sí mi, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi (láti di) mùsùlùmí.”

See all translations of this verse →

قَالَتْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمَلَؤُا۟ أَفْتُونِى فِىٓ أَمْرِى مَا كُنتُ قَاطِعَةً أَمْرًا حَتَّىٰ تَشْهَدُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì í gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan títí ẹ máa fi jẹ́rìí sí i.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ نَحْنُ أُو۟لُوا۟ قُوَّةٍ وَأُو۟لُوا۟ بَأْسٍ شَدِيدٍ وَٱلْأَمْرُ إِلَيْكِ فَٱنظُرِى مَاذَا تَأْمُرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Alágbára ni àwa. Akọni ogun sì tún ni wá. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọ̀rọ̀ wà. Nítorí náà, wòye sí ohun tí o máa pa láṣẹ.”

See all translations of this verse →

قَالَتْ إِنَّ ٱلْمُلُوكَ إِذَا دَخَلُوا۟ قَرْيَةً أَفْسَدُوهَا وَجَعَلُوٓا۟ أَعِزَّةَ أَهْلِهَآ أَذِلَّةً وَكَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Bilƙīs) wí pé: “Dájúdájú àwọn ọba, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ìlú kan, wọn yóò bà á jẹ́. Wọn yó sì sọ àwọn ẹni abiyì ibẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ. Báyẹn ni wọ́n máa ń ṣe.

See all translations of this verse →

وَإِنِّى مُرْسِلَةٌ إِلَيْهِم بِهَدِيَّةٍ فَنَاظِرَةٌۢ بِمَ يَرْجِعُ ٱلْمُرْسَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú mo máa fi ẹ̀bùn kan ránṣẹ́ sí wọn. Mo sì máa wo ohun tí àwọn ìránṣẹ́ yóò mú padà (ní èsì).”

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَ سُلَيْمَٰنَ قَالَ أَتُمِدُّونَنِ بِمَالٍ فَمَآ ءَاتَىٰنِۦَ ٱللَّهُ خَيْرٌ مِّمَّآ ءَاتَىٰكُم بَلْ أَنتُم بِهَدِيَّتِكُمْ تَفْرَحُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: “Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí Ó fún yín. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín.

See all translations of this verse →

ٱرْجِعْ إِلَيْهِمْ فَلَنَأْتِيَنَّهُم بِجُنُودٍ لَّا قِبَلَ لَهُم بِهَا وَلَنُخْرِجَنَّهُم مِّنْهَآ أَذِلَّةً وَهُمْ صَٰغِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelPadà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni yẹpẹrẹ, tí wọn yó sì di ẹni àbùkù.”

See all translations of this verse →

قَالَ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمَلَؤُا۟ أَيُّكُمْ يَأْتِينِى بِعَرْشِهَا قَبْلَ أَن يَأْتُونِى مُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l’ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí.”

See all translations of this verse →

قَالَ عِفْرِيتٌ مِّنَ ٱلْجِنِّ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبْلَ أَن تَقُومَ مِن مَّقَامِكَ وَإِنِّى عَلَيْهِ لَقَوِىٌّ أَمِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: “Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní ibùjókòó rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ ٱلَّذِى عِندَهُۥ عِلْمٌ مِّنَ ٱلْكِتَٰبِ أَنَا۠ ءَاتِيكَ بِهِۦ قَبْلَ أَن يَرْتَدَّ إِلَيْكَ طَرْفُكَ فَلَمَّا رَءَاهُ مُسْتَقِرًّا عِندَهُۥ قَالَ هَٰذَا مِن فَضْلِ رَبِّى لِيَبْلُوَنِىٓ ءَأَشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ وَمَن شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِۦ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّى غَنِىٌّ كَرِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú.” Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé.”

See all translations of this verse →

قَالَ نَكِّرُوا۟ لَهَا عَرْشَهَا نَنظُرْ أَتَهْتَدِىٓ أَمْ تَكُونُ مِنَ ٱلَّذِينَ لَا يَهْتَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Ẹ pa á lójú dà fún un sí ìrísí mìíràn tí kò fi níí dá a mọ̀, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀.”

See all translations of this verse →

فَلَمَّا جَآءَتْ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرْشُكِ قَالَتْ كَأَنَّهُۥ هُوَ وَأُوتِينَا ٱلْعِلْمَ مِن قَبْلِهَا وَكُنَّا مُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?” Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): “Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí.”

See all translations of this verse →

وَصَدَّهَا مَا كَانَت تَّعْبُدُ مِن دُونِ ٱللَّهِ إِنَّهَا كَانَتْ مِن قَوْمٍ كَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi jíjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

قِيلَ لَهَا ٱدْخُلِى ٱلصَّرْحَ فَلَمَّا رَأَتْهُ حَسِبَتْهُ لُجَّةً وَكَشَفَتْ عَن سَاقَيْهَا قَالَ إِنَّهُۥ صَرْحٌ مُّمَرَّدٌ مِّن قَوَارِيرَ قَالَتْ رَبِّ إِنِّى ظَلَمْتُ نَفْسِى وَأَسْلَمْتُ مَعَ سُلَيْمَٰنَ لِلَّهِ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sọ fún un pé: “Wọ inú ààfin.” Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni.” (Bilƙīs) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَآ إِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَٰلِحًا أَنِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ فَإِذَا هُمْ فَرِيقَانِ يَخْتَصِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti ránṣẹ́ sí ìjọ Thamūd. (A rán) arákùnrin wọn, Sọ̄lih (níṣẹ́ sí wọn), pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu.” Nígbà náà ni wọ́n pín sí ìjọ méjì, tó ń bára wọn jiyàn.

See all translations of this verse →

قَالَ يَٰقَوْمِ لِمَ تَسْتَعْجِلُونَ بِٱلسَّيِّئَةِ قَبْلَ ٱلْحَسَنَةِ لَوْلَا تَسْتَغْفِرُونَ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá (ìyà) aburú pẹ̀lú ìkánjú ṣíwájú (ohun) rere (tó yẹ kí ẹ mú ṣe níṣẹ́)? Ẹ kò ṣe tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu nítorí kí Wọ́n lè ṣàánú yín?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ ٱطَّيَّرْنَا بِكَ وَبِمَن مَّعَكَ قَالَ طَٰٓئِرُكُمْ عِندَ ٱللَّهِ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ تُفْتَنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “A rí àmì aburú láti ọ̀dọ̀ rẹ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ.” (Ànábì Sọ̄lih) sọ pé: “Àmì aburú yín wà (nínú kádàrá yín) lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì rí bí ẹ ṣe rò ó àmọ́ ìjọ aládàn-ánwò ni yín.”

See all translations of this verse →

وَكَانَ فِى ٱلْمَدِينَةِ تِسْعَةُ رَهْطٍ يُفْسِدُونَ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kan sì wà nínú ìlú, tí wọ́n ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣàtúnṣe.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ تَقَاسَمُوا۟ بِٱللَّهِ لَنُبَيِّتَنَّهُۥ وَأَهْلَهُۥ ثُمَّ لَنَقُولَنَّ لِوَلِيِّهِۦ مَا شَهِدْنَا مَهْلِكَ أَهْلِهِۦ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí (fúnra wọn) pé: “Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa lọ bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní alẹ́ (láti pa á). Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa.”

See all translations of this verse →

وَمَكَرُوا۟ مَكْرًا وَمَكَرْنَا مَكْرًا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura.[1]

See all translations of this verse →

فَٱنظُرْ كَيْفَ كَانَ عَٰقِبَةُ مَكْرِهِمْ أَنَّا دَمَّرْنَٰهُمْ وَقَوْمَهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá.

See all translations of this verse →

فَتِلْكَ بُيُوتُهُمْ خَاوِيَةًۢ بِمَا ظَلَمُوٓا۟ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّقَوْمٍ يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ìwọ̀nyẹn ni ilé wọn. Ó tí di ilé ahoro nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó nímọ̀.

See all translations of this verse →

وَأَنجَيْنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَكَانُوا۟ يَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA gba àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo là, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِۦٓ أَتَأْتُونَ ٱلْفَٰحِشَةَ وَأَنتُمْ تُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(A tún fi iṣẹ́ ìmísí rán Ànábì) Lūt. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé iṣẹ́ aburú ni ẹ óò máa ṣe ni, ẹ sì ríran?

See all translations of this verse →

أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ ٱلرِّجَالَ شَهْوَةً مِّن دُونِ ٱلنِّسَآءِ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín ni) dípò àwọn obìnrin? Àní sẹ́, òpè ènìyàn ni yín.”

See all translations of this verse →

فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓا۟ أَخْرِجُوٓا۟ ءَالَ لُوطٍ مِّن قَرْيَتِكُمْ إِنَّهُمْ أُنَاسٌ يَتَطَهَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn tó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”

See all translations of this verse →

فَأَنجَيْنَٰهُ وَأَهْلَهُۥٓ إِلَّا ٱمْرَأَتَهُۥ قَدَّرْنَٰهَا مِنَ ٱلْغَٰبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.

See all translations of this verse →

وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا فَسَآءَ مَطَرُ ٱلْمُنذَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.

See all translations of this verse →

قُلِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ وَسَلَٰمٌ عَلَىٰ عِبَادِهِ ٱلَّذِينَ ٱصْطَفَىٰٓ ءَآللَّهُ خَيْرٌ أَمَّا يُشْرِكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l’Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?”

See all translations of this verse →

أَمَّنْ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَنۢبَتْنَا بِهِۦ حَدَآئِقَ ذَاتَ بَهْجَةٍ مَّا كَانَ لَكُمْ أَن تُنۢبِتُوا۟ شَجَرَهَآ أَءِلَٰهٌ مَّعَ ٱللَّهِ بَلْ هُمْ قَوْمٌ يَعْدِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fún yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ tó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni.

See all translations of this verse →

أَمَّن جَعَلَ ٱلْأَرْضَ قَرَارًا وَجَعَلَ خِلَٰلَهَآ أَنْهَٰرًا وَجَعَلَ لَهَا رَوَٰسِىَ وَجَعَلَ بَيْنَ ٱلْبَحْرَيْنِ حَاجِزًا أَءِلَٰهٌ مَّعَ ٱللَّهِ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta gbagidi sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

See all translations of this verse →

أَمَّن يُجِيبُ ٱلْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ ٱلسُّوٓءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَآءَ ٱلْأَرْضِ أَءِلَٰهٌ مَّعَ ٱللَّهِ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí!

See all translations of this verse →

أَمَّن يَهْدِيكُمْ فِى ظُلُمَٰتِ ٱلْبَرِّ وَٱلْبَحْرِ وَمَن يُرْسِلُ ٱلرِّيَٰحَ بُشْرًۢا بَيْنَ يَدَىْ رَحْمَتِهِۦٓ أَءِلَٰهٌ مَّعَ ٱللَّهِ تَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

See all translations of this verse →

أَمَّن يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ وَمَن يَرْزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ أَءِلَٰهٌ مَّعَ ٱللَّهِ قُلْ هَاتُوا۟ بُرْهَٰنَكُمْ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fún yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

See all translations of this verse →

قُل لَّا يَعْلَمُ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ٱلْغَيْبَ إِلَّا ٱللَّهُ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde.”

See all translations of this verse →

بَلِ ٱدَّٰرَكَ عِلْمُهُمْ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ بَلْ هُمْ فِى شَكٍّ مِّنْهَا بَلْ هُم مِّنْهَا عَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, ìmọ̀ wọn máa kẹ́sẹjá ní ọ̀run (orí wọn máa pé ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Àní sẹ́, wọ́n fọ́jú nípa rẹ̀ ni.

See all translations of this verse →

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبًا وَءَابَآؤُنَآ أَئِنَّا لَمُخْرَجُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé nígbà tí àwa àti àwọn bàbá wa bá ti di erùpẹ̀, ṣé (nígbà náà ni) wọn yóò mú wa jáde?

See all translations of this verse →

لَقَدْ وُعِدْنَا هَٰذَا نَحْنُ وَءَابَآؤُنَا مِن قَبْلُ إِنْ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

See all translations of this verse →

قُلْ سِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَٱنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلْمُجْرِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí.”

See all translations of this verse →

وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَلَا تَكُن فِى ضَيْقٍ مِّمَّا يَمْكُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń dá ní ète kó ìnira bá ọ.

See all translations of this verse →

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

See all translations of this verse →

قُلْ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ رَدِفَ لَكُم بَعْضُ ٱلَّذِى تَسْتَعْجِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ó lè jẹ́ pé apá kan ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ti súnmọ́ yín tán.”

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَشْكُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ mà ni Ọlọ́lá lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kì í dúpẹ́ (fún Un).

See all translations of this verse →

وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَعْلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمْ وَمَا يُعْلِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Ó kúkú mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَا مِنْ غَآئِبَةٍ فِى ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ إِلَّا فِى كِتَٰبٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó hàn kedere.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذَا ٱلْقُرْءَانَ يَقُصُّ عَلَىٰ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ أَكْثَرَ ٱلَّذِى هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú al-Ƙur’ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu sí.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِى بَيْنَهُم بِحُكْمِهِۦ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْعَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú ìdájọ́ Rẹ̀. Òun ni Alágbára, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

فَتَوَكَّلْ عَلَى ٱللَّهِ إِنَّكَ عَلَى ٱلْحَقِّ ٱلْمُبِينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, gbáralé Allāhu. Dájúdájú ìwọ wà lórí òdodo pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

إِنَّكَ لَا تُسْمِعُ ٱلْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوْا۟ مُدْبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَنتَ بِهَٰدِى ٱلْعُمْىِ عَن ضَلَٰلَتِهِمْ إِن تُسْمِعُ إِلَّا مَن يُؤْمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا فَهُم مُّسْلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́ nítorí pé, àwọn ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.[1]

See all translations of this verse →

وَإِذَا وَقَعَ ٱلْقَوْلُ عَلَيْهِمْ أَخْرَجْنَا لَهُمْ دَآبَّةً مِّنَ ٱلْأَرْضِ تُكَلِّمُهُمْ أَنَّ ٱلنَّاسَ كَانُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا لَا يُوقِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ọ̀rọ̀ náà bá kò lé wọn lórí, A máa mú ẹranko kan jáde fún wọn láti inú ilẹ̀, tí ó máa bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú àwọn ènìyàn kì í ní ìmọ̀ àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.”

See all translations of this verse →

وَيَوْمَ نَحْشُرُ مِن كُلِّ أُمَّةٍ فَوْجًا مِّمَّن يُكَذِّبُ بِـَٔايَٰتِنَا فَهُمْ يُوزَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé (rántí) ọjọ́ tí A óò kó ìjọ kan jọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn tó ń pe àwọn āyah Wa ní irọ́. A ó sì kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn tí wọ́n máa tẹ̀lé ara wọn.

See all translations of this verse →

حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُو قَالَ أَكَذَّبْتُم بِـَٔايَٰتِى وَلَمْ تُحِيطُوا۟ بِهَا عِلْمًا أَمَّاذَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTítí (di) ìgbà tí wọ́n bá dé (tán), (Allāhu) yóò sọ pé: “Ṣé ẹ pe àwọn āyah Mi ní irọ́, tí ẹ̀yin kò sì ní ìmọ̀ kan nípa rẹ̀ (tí ẹ lè fi já a nírọ́)? Tàbí kí ni ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ (nílé ayé)?”

See all translations of this verse →

وَوَقَعَ ٱلْقَوْلُ عَلَيْهِم بِمَا ظَلَمُوا۟ فَهُمْ لَا يَنطِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀.

See all translations of this verse →

أَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا جَعَلْنَا ٱلَّيْلَ لِيَسْكُنُوا۟ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبْصِرًا إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A dá òru nítorí kí wọ́n lè sinmi nínú rẹ̀, (A sì dá) ọ̀sán (nítorí kí wọ́n lè) ríran? Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَيَوْمَ يُنفَخُ فِى ٱلصُّورِ فَفَزِعَ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِى ٱلْأَرْضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُ وَكُلٌّ أَتَوْهُ دَٰخِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo, gbogbo ẹni tí ó wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ yó sì jáyà tó máa mú wọn kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Gbogbo ẹ̀dá l’ó sì máa yẹpẹrẹ wá bá Allāhu.

See all translations of this verse →

وَتَرَى ٱلْجِبَالَ تَحْسَبُهَا جَامِدَةً وَهِىَ تَمُرُّ مَرَّ ٱلسَّحَابِ صُنْعَ ٱللَّهِ ٱلَّذِىٓ أَتْقَنَ كُلَّ شَىْءٍ إِنَّهُۥ خَبِيرٌۢ بِمَا تَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelO sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi tó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò.[1] (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan dáadáa. Dájúdájú Alámọ̀tán ni nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

مَن جَآءَ بِٱلْحَسَنَةِ فَلَهُۥ خَيْرٌ مِّنْهَا وَهُم مِّن فَزَعٍ يَوْمَئِذٍ ءَامِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá dé pẹ̀lú iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni rere tó lóore ju èyí tó ṣe. Àwọn sì ni olùfàyàbalẹ̀ nínú ìjáyà ọjọ́ yẹn.

See all translations of this verse →

وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَكُبَّتْ وُجُوهُهُمْ فِى ٱلنَّارِ هَلْ تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá sì dé pẹ̀lú iṣẹ́ aburú, A sì máa da ojú wọn bolẹ̀ nínú Iná. Ǹjẹ́ A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?

See all translations of this verse →

إِنَّمَآ أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ رَبَّ هَٰذِهِ ٱلْبَلْدَةِ ٱلَّذِى حَرَّمَهَا وَلَهُۥ كُلُّ شَىْءٍ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ ٱلْمُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tí wọ́n pa mí ní àṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Olúwa Ìlú yìí, Ẹni tí Ó ṣe é ní àyè ọ̀wọ̀. TiRẹ̀ sì ni gbogbo n̄ǹkan. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí.

See all translations of this verse →

وَأَنْ أَتْلُوَا۟ ٱلْقُرْءَانَ فَمَنِ ٱهْتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهْتَدِى لِنَفْسِهِۦ وَمَن ضَلَّ فَقُلْ إِنَّمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلْمُنذِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kí èmi máa ké al-Ƙur’ān. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkìlọ̀.”

See all translations of this verse →

وَقُلِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ سَيُرِيكُمْ ءَايَٰتِهِۦ فَتَعْرِفُونَهَا وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu.” (Allāhu) yóò fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ẹ̀yin yó sì mọ̀ wọ́n. Olúwa rẹ kò sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70