Súrà At-Takwir التكوير
29 verses · Mecca · revelation order 7
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلشَّمْسُ كُوِّرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْجِبَالُ سُيِّرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْعِشَارُ عُطِّلَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْوُحُوشُ حُشِرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْبِحَارُ سُجِّرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْمَوْءُۥدَةُ سُئِلَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
See all translations of this verse →
بِأَىِّ ذَنۢبٍ قُتِلَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْجَحِيمُ سُعِّرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
See all translations of this verse →
وَإِذَا ٱلْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
See all translations of this verse →
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّآ أَحْضَرَتْ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
See all translations of this verse →
فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلْخُنَّسِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,
See all translations of this verse →
ٱلْجَوَارِ ٱلْكُنَّسِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
See all translations of this verse →
وَٱلَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.[1]
See all translations of this verse →
وَٱلصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,[1]
See all translations of this verse →
ذِى قُوَّةٍ عِندَ ذِى ٱلْعَرْشِ مَكِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelalágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
See all translations of this verse →
مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
See all translations of this verse →
وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ رَءَاهُ بِٱلْأُفُقِ ٱلْمُبِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ kúkú rí i nínú òfurufú kedere.[1]
See all translations of this verse →
وَمَا هُوَ عَلَى ٱلْغَيْبِ بِضَنِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
See all translations of this verse →
وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَٰنٍ رَّجِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAl-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) aṣ-Ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.
See all translations of this verse →
فَأَيْنَ تَذْهَبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
See all translations of this verse →
إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
لِمَن شَآءَ مِنكُمْ أَن يَسْتَقِيمَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
See all translations of this verse →
وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→