caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Naazi'aat النازعات

46 verses · Mecca · revelation order 81

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلنَّٰزِعَٰتِ غَرْقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.

See all translations of this verse →

وَٱلنَّٰشِطَٰتِ نَشْطًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.

See all translations of this verse →

وَٱلسَّٰبِحَٰتِ سَبْحًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.

See all translations of this verse →

فَٱلسَّٰبِقَٰتِ سَبْقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْمُدَبِّرَٰتِ أَمْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.

See all translations of this verse →

يَوْمَ تَرْجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.[1]

See all translations of this verse →

تَتْبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.[1]

See all translations of this verse →

قُلُوبٌ يَوْمَئِذٍ وَاجِفَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.

See all translations of this verse →

أَبْصَٰرُهَا خَٰشِعَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOjú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.

See all translations of this verse →

يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِى ٱلْحَافِرَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?

See all translations of this verse →

أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمًا نَّخِرَةً

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ تِلْكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”

See all translations of this verse →

فَإِنَّمَا هِىَ زَجْرَةٌ وَٰحِدَةٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.

See all translations of this verse →

فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.

See all translations of this verse →

هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

See all translations of this verse →

إِذْ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلْوَادِ ٱلْمُقَدَّسِ طُوًى

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.

See all translations of this verse →

ٱذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

See all translations of this verse →

فَقُلْ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?

See all translations of this verse →

وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”

See all translations of this verse →

فَأَرَىٰهُ ٱلْـَٔايَةَ ٱلْكُبْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì fi àmì tó tóbi hàn án.

See all translations of this verse →

فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).

See all translations of this verse →

ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).

See all translations of this verse →

فَحَشَرَ فَنَادَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.

See all translations of this verse →

فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلْأَعْلَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”

See all translations of this verse →

فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلْـَٔاخِرَةِ وَٱلْأُولَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).[1]

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّمَن يَخْشَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

See all translations of this verse →

ءَأَنتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُ بَنَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?

See all translations of this verse →

رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.

See all translations of this verse →

وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.

See all translations of this verse →

وَٱلْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.[1]

See all translations of this verse →

أَخْرَجَ مِنْهَا مَآءَهَا وَمَرْعَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَٱلْجِبَالَ أَرْسَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.

See all translations of this verse →

مَتَٰعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَٰمِكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.

See all translations of this verse →

فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلْكُبْرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,

See all translations of this verse →

يَوْمَ يَتَذَكَّرُ ٱلْإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَبُرِّزَتِ ٱلْجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.

See all translations of this verse →

فَأَمَّا مَن طَغَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,

See all translations of this verse →

وَءَاثَرَ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,

See all translations of this verse →

فَإِنَّ ٱلْجَحِيمَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

See all translations of this verse →

وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفْسَ عَنِ ٱلْهَوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),

See all translations of this verse →

فَإِنَّ ٱلْجَنَّةَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

See all translations of this verse →

يَسْـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”

See all translations of this verse →

فِيمَ أَنتَ مِن ذِكْرَىٰهَآ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNíbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?[1]

See all translations of this verse →

إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.

See all translations of this verse →

إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخْشَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.

See all translations of this verse →

كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوٓا۟ إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَىٰهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70