caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Nooh نوح

28 verses · Mecca · revelation order 71

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِنَّآ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِۦٓ أَنْ أَنذِرْ قَوْمَكَ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn.”

See all translations of this verse →

قَالَ يَٰقَوْمِ إِنِّى لَكُمْ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín

See all translations of this verse →

أَنِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُ وَأَطِيعُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelpé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

See all translations of this verse →

يَغْفِرْ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرْكُمْ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى إِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ إِذَا جَآءَ لَا يُؤَخَّرُ لَوْ كُنتُمْ تَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fún yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ إِنِّى دَعَوْتُ قَوْمِى لَيْلًا وَنَهَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán.

See all translations of this verse →

فَلَمْ يَزِدْهُمْ دُعَآءِىٓ إِلَّا فِرَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo).

See all translations of this verse →

وَإِنِّى كُلَّمَا دَعَوْتُهُمْ لِتَغْفِرَ لَهُمْ جَعَلُوٓا۟ أَصَٰبِعَهُمْ فِىٓ ءَاذَانِهِمْ وَٱسْتَغْشَوْا۟ ثِيَابَهُمْ وَأَصَرُّوا۟ وَٱسْتَكْبَرُوا۟ ٱسْتِكْبَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an.

See all translations of this verse →

ثُمَّ إِنِّى دَعَوْتُهُمْ جِهَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, dájúdájú èmí pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè.

See all translations of this verse →

ثُمَّ إِنِّىٓ أَعْلَنتُ لَهُمْ وَأَسْرَرْتُ لَهُمْ إِسْرَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, dájúdájú èmí kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́.

See all translations of this verse →

فَقُلْتُ ٱسْتَغْفِرُوا۟ رَبَّكُمْ إِنَّهُۥ كَانَ غَفَّارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn.

See all translations of this verse →

يُرْسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيْكُم مِّدْرَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa rọ̀jò fún yín ní òjò púpọ̀,

See all translations of this verse →

وَيُمْدِدْكُم بِأَمْوَٰلٍ وَبَنِينَ وَيَجْعَل لَّكُمْ جَنَّٰتٍ وَيَجْعَل لَّكُمْ أَنْهَٰرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fún yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fún yín.

See all translations of this verse →

مَّا لَكُمْ لَا تَرْجُونَ لِلَّهِ وَقَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu?

See all translations of this verse →

وَقَدْ خَلَقَكُمْ أَطْوَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).[1]

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَوْا۟ كَيْفَ خَلَقَ ٱللَّهُ سَبْعَ سَمَٰوَٰتٍ طِبَاقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹ kò wòye sí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni?

See all translations of this verse →

وَجَعَلَ ٱلْقَمَرَ فِيهِنَّ نُورًا وَجَعَلَ ٱلشَّمْسَ سِرَاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà.

See all translations of this verse →

وَٱللَّهُ أَنۢبَتَكُم مِّنَ ٱلْأَرْضِ نَبَاتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀.

See all translations of this verse →

ثُمَّ يُعِيدُكُمْ فِيهَا وَيُخْرِجُكُمْ إِخْرَاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà.

See all translations of this verse →

وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ بِسَاطًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́

See all translations of this verse →

لِّتَسْلُكُوا۟ مِنْهَا سُبُلًا فِجَاجًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ نُوحٌ رَّبِّ إِنَّهُمْ عَصَوْنِى وَٱتَّبَعُوا۟ مَن لَّمْ يَزِدْهُ مَالُهُۥ وَوَلَدُهُۥٓ إِلَّا خَسَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò.

See all translations of this verse →

وَمَكَرُوا۟ مَكْرًا كُبَّارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì déte ní ète tó tóbi.”

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ لَا تَذَرُنَّ ءَالِهَتَكُمْ وَلَا تَذَرُنَّ وَدًّا وَلَا سُوَاعًا وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì wí pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀.”

See all translations of this verse →

وَقَدْ أَضَلُّوا۟ كَثِيرًا وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا ضَلَٰلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà.

See all translations of this verse →

مِّمَّا خَطِيٓـَٰٔتِهِمْ أُغْرِقُوا۟ فَأُدْخِلُوا۟ نَارًا فَلَمْ يَجِدُوا۟ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَنصَارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu.

See all translations of this verse →

وَقَالَ نُوحٌ رَّبِّ لَا تَذَرْ عَلَى ٱلْأَرْضِ مِنَ ٱلْكَٰفِرِينَ دَيَّارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Nūh tún sọ pé: “Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّكَ إِن تَذَرْهُمْ يُضِلُّوا۟ عِبَادَكَ وَلَا يَلِدُوٓا۟ إِلَّا فَاجِرًا كَفَّارًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

رَّبِّ ٱغْفِرْ لِى وَلِوَٰلِدَىَّ وَلِمَن دَخَلَ بَيْتِىَ مُؤْمِنًا وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَٰتِ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا تَبَارًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni tó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun.”

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70