caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Ma'aarij المعارج

44 verses · Mecca · revelation order 79

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ سَأَلَ سَآئِلٌۢ بِعَذَابٍ وَاقِعٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀

See all translations of this verse →

لِّلْكَٰفِرِينَ لَيْسَ لَهُۥ دَافِعٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelsí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́

See all translations of this verse →

مِّنَ ٱللَّهِ ذِى ٱلْمَعَارِجِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaellọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.

See all translations of this verse →

تَعْرُجُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيْهِ فِى يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُۥ خَمْسِينَ أَلْفَ سَنَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1]

See all translations of this verse →

فَٱصْبِرْ صَبْرًا جَمِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.

See all translations of this verse →

إِنَّهُمْ يَرَوْنَهُۥ بَعِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.

See all translations of this verse →

وَنَرَىٰهُ قَرِيبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.

See all translations of this verse →

يَوْمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلْمُهْلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,

See all translations of this verse →

وَتَكُونُ ٱلْجِبَالُ كَٱلْعِهْنِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,

See all translations of this verse →

وَلَا يَسْـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).

See all translations of this verse →

يُبَصَّرُونَهُمْ يَوَدُّ ٱلْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِى مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍۭ بِبَنِيهِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.

See all translations of this verse →

وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,

See all translations of this verse →

وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِى تُـْٔوِيهِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,

See all translations of this verse →

وَمَن فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنجِيهِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّهَا لَظَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).

See all translations of this verse →

نَزَّاعَةً لِّلشَّوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa bó awọ orí tòró.

See all translations of this verse →

تَدْعُوا۟ مَنْ أَدْبَرَ وَتَوَلَّىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,

See all translations of this verse →

وَجَمَعَ فَأَوْعَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeló kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.

See all translations of this verse →

إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.

See all translations of this verse →

وَإِذَا مَسَّهُ ٱلْخَيْرُ مَنُوعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱلْمُصَلِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn olùkírun,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ دَآئِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ فِىٓ أَمْوَٰلِهِمْ حَقٌّ مَّعْلُومٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn

See all translations of this verse →

لِّلسَّآئِلِ وَٱلْمَحْرُومِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelsí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ هُم مِّنْ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,

See all translations of this verse →

إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمْ غَيْرُ مَأْمُونٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَٰفِظُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,

See all translations of this verse →

إِلَّا عَلَىٰٓ أَزْوَٰجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,

See all translations of this verse →

فَمَنِ ٱبْتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْعَادُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ هُمْ لِأَمَٰنَٰتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَٰعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمْ قَآئِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ فِى جَنَّٰتٍ مُّكْرَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.

See all translations of this verse →

فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ قِبَلَكَ مُهْطِعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,

See all translations of this verse →

عَنِ ٱلْيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?

See all translations of this verse →

أَيَطْمَعُ كُلُّ ٱمْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُدْخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّا خَلَقْنَٰهُم مِّمَّا يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.

See all translations of this verse →

فَلَآ أُقْسِمُ بِرَبِّ ٱلْمَشَٰرِقِ وَٱلْمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn[1] búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára

See all translations of this verse →

عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيْرًا مِّنْهُمْ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelláti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.[1]

See all translations of this verse →

فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا۟ وَيَلْعَبُوا۟ حَتَّىٰ يُلَٰقُوا۟ يَوْمَهُمُ ٱلَّذِى يُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

See all translations of this verse →

يَوْمَ يَخْرُجُونَ مِنَ ٱلْأَجْدَاثِ سِرَاعًا كَأَنَّهُمْ إِلَىٰ نُصُبٍ يُوفِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelỌjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.

See all translations of this verse →

خَٰشِعَةً أَبْصَٰرُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ذَٰلِكَ ٱلْيَوْمُ ٱلَّذِى كَانُوا۟ يُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOjú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70