وَإِنَّ لَكُمْ فِى ٱلْأَنْعَٰمِ لَعِبْرَةً نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِى بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَّبَنًا خَالِصًا سَآئِغًا لِّلشَّٰرِبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fún yín mu nínú n̄ǹkan tó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ tó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn tó ń mu ún.