جَنَّٰتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ لَهُمْ فِيهَا مَا يَشَآءُونَ كَذَٰلِكَ يَجْزِى ٱللَّهُ ٱلْمُتَّقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra 'Adn ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).