وَيَوْمَ نَبْعَثُ فِى كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا عَلَيْهِم مِّنْ أَنفُسِهِمْ وَجِئْنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ تِبْيَٰنًا لِّكُلِّ شَىْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً وَبُشْرَىٰ لِلْمُسْلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan,[1] ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.