Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Waaqia
Súrà Al-Waaqia الواقعة
96 verses · Mecca · revelation order 46
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا وَقَعَتِ ٱلْوَاقِعَةُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
See all translations of this verse →
لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael - kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-
See all translations of this verse →
خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
See all translations of this verse →
إِذَا رُجَّتِ ٱلْأَرْضُ رَجًّا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
See all translations of this verse →
وَبُسَّتِ ٱلْجِبَالُ بَسًّا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
See all translations of this verse →
فَكَانَتْ هَبَآءً مُّنۢبَثًّا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael - wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -
See all translations of this verse →
وَكُنتُمْ أَزْوَٰجًا ثَلَٰثَةً
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.[1]
See all translations of this verse →
فَأَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
See all translations of this verse →
وَأَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
See all translations of this verse →
وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
See all translations of this verse →
أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلْمُقَرَّبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
See all translations of this verse →
فِى جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
See all translations of this verse →
ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
See all translations of this verse →
وَقَلِيلٌ مِّنَ ٱلْـَٔاخِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
See all translations of this verse →
عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوْضُونَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
See all translations of this verse →
مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيْهَا مُتَقَٰبِلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
See all translations of this verse →
يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
See all translations of this verse →
بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).
See all translations of this verse →
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
See all translations of this verse →
وَفَٰكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
See all translations of this verse →
وَلَحْمِ طَيْرٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
See all translations of this verse →
وَحُورٌ عِينٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
See all translations of this verse →
كَأَمْثَٰلِ ٱللُّؤْلُؤِ ٱلْمَكْنُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
See all translations of this verse →
جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
See all translations of this verse →
إِلَّا قِيلًا سَلَٰمًا سَلَٰمًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
See all translations of this verse →
وَأَصْحَٰبُ ٱلْيَمِينِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْيَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
See all translations of this verse →
فِى سِدْرٍ مَّخْضُودٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
See all translations of this verse →
وَطَلْحٍ مَّنضُودٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,
See all translations of this verse →
وَظِلٍّ مَّمْدُودٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti ibòji tó gbòòrò,
See all translations of this verse →
وَمَآءٍ مَّسْكُوبٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
See all translations of this verse →
وَفَٰكِهَةٍ كَثِيرَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
See all translations of this verse →
لَّا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
See all translations of this verse →
وَفُرُشٍ مَّرْفُوعَةٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
See all translations of this verse →
إِنَّآ أَنشَأْنَٰهُنَّ إِنشَآءً
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).
See all translations of this verse →
فَجَعَلْنَٰهُنَّ أَبْكَارًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
See all translations of this verse →
عُرُبًا أَتْرَابًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
See all translations of this verse →
لِّأَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
See all translations of this verse →
ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
See all translations of this verse →
وَثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْـَٔاخِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.[1]
See all translations of this verse →
وَأَصْحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلشِّمَالِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
See all translations of this verse →
فِى سَمُومٍ وَحَمِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,
See all translations of this verse →
وَظِلٍّ مِّن يَحْمُومٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
See all translations of this verse →
لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael kò tutù, kò sì dára.
See all translations of this verse →
إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
See all translations of this verse →
وَكَانُوا۟ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلْحِنثِ ٱلْعَظِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
See all translations of this verse →
وَكَانُوا۟ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبْعُوثُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
See all translations of this verse →
أَوَءَابَآؤُنَا ٱلْأَوَّلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
See all translations of this verse →
قُلْ إِنَّ ٱلْأَوَّلِينَ وَٱلْـَٔاخِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
See all translations of this verse →
لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”
See all translations of this verse →
ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلْمُكَذِّبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
See all translations of this verse →
لَـَٔاكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
See all translations of this verse →
فَمَالِـُٔونَ مِنْهَا ٱلْبُطُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
See all translations of this verse →
فَشَٰرِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ ٱلْحَمِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.
See all translations of this verse →
فَشَٰرِبُونَ شُرْبَ ٱلْهِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
See all translations of this verse →
هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ ٱلدِّينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
See all translations of this verse →
نَحْنُ خَلَقْنَٰكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!
See all translations of this verse →
أَفَرَءَيْتُم مَّا تُمْنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
See all translations of this verse →
ءَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلْخَٰلِقُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
See all translations of this verse →
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ ٱلْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara
See all translations of this verse →
عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَٰلَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِى مَا لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael láti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ ٱلنَّشْأَةَ ٱلْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?
See all translations of this verse →
أَفَرَءَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
See all translations of this verse →
ءَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلزَّٰرِعُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
See all translations of this verse →
لَوْ نَشَآءُ لَجَعَلْنَٰهُ حُطَٰمًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
See all translations of this verse →
إِنَّا لَمُغْرَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”
See all translations of this verse →
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”
See all translations of this verse →
أَفَرَءَيْتُمُ ٱلْمَآءَ ٱلَّذِى تَشْرَبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,
See all translations of this verse →
ءَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ ٱلْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنزِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
See all translations of this verse →
لَوْ نَشَآءُ جَعَلْنَٰهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
See all translations of this verse →
أَفَرَءَيْتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِى تُورُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,
See all translations of this verse →
ءَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَآ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنشِـُٔونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
See all translations of this verse →
نَحْنُ جَعَلْنَٰهَا تَذْكِرَةً وَمَتَٰعًا لِّلْمُقْوِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
See all translations of this verse →
فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
See all translations of this verse →
فَلَآ أُقْسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.[1]
See all translations of this verse →
وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٌ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّهُۥ لَقُرْءَانٌ كَرِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.
See all translations of this verse →
فِى كِتَٰبٍ مَّكْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).
See all translations of this verse →
لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلْمُطَهَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
See all translations of this verse →
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
أَفَبِهَٰذَا ٱلْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?
See all translations of this verse →
وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.[1]
See all translations of this verse →
فَلَوْلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلْحُلْقُومَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
See all translations of this verse →
وَأَنتُمْ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?
See all translations of this verse →
وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.[1]
See all translations of this verse →
فَلَوْلَآ إِن كُنتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
See all translations of this verse →
تَرْجِعُونَهَآ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
See all translations of this verse →
فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُقَرَّبِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
See all translations of this verse →
فَرَوْحٌ وَرَيْحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
See all translations of this verse →
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنْ أَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,
See all translations of this verse →
فَسَلَٰمٌ لَّكَ مِنْ أَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
See all translations of this verse →
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
See all translations of this verse →
فَنُزُلٌ مِّنْ حَمِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí
See all translations of this verse →
وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael àti wíwọ inú iná Jẹhīm.
See all translations of this verse →
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلْيَقِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.
See all translations of this verse →
فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
See all translations of this verse →
← Súrà Ar-Rahmaan
Súrà Al-Hadid →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.