caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Alaq العلق

19 verses · Mecca · revelation order 1

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱقْرَأْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلَّذِى خَلَقَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKé (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

خَلَقَ ٱلْإِنسَٰنَ مِنْ عَلَقٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

See all translations of this verse →

ٱقْرَأْ وَرَبُّكَ ٱلْأَكْرَمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKé e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِى عَلَّمَ بِٱلْقَلَمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

See all translations of this verse →

عَلَّمَ ٱلْإِنسَٰنَ مَا لَمْ يَعْلَمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

See all translations of this verse →

كَلَّآ إِنَّ ٱلْإِنسَٰنَ لَيَطْغَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

See all translations of this verse →

أَن رَّءَاهُ ٱسْتَغْنَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجْعَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَرَءَيْتَ ٱلَّذِى يَنْهَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

See all translations of this verse →

عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelfún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

See all translations of this verse →

أَرَءَيْتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلْهُدَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

See all translations of this verse →

أَوْ أَمَرَ بِٱلتَّقْوَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

See all translations of this verse →

أَرَءَيْتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

See all translations of this verse →

أَلَمْ يَعْلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

See all translations of this verse →

كَلَّا لَئِن لَّمْ يَنتَهِ لَنَسْفَعًۢا بِٱلنَّاصِيَةِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.[1]) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí² rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

See all translations of this verse →

نَاصِيَةٍ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

فَلْيَدْعُ نَادِيَهُۥ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

See all translations of this verse →

سَنَدْعُ ٱلزَّبَانِيَةَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

See all translations of this verse →

كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَٱسْجُدْ وَٱقْتَرِب

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70