Súrà At-Tin التين
8 verses · Mecca · revelation order 28
بِّسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلتِّينِ وَٱلزَّيْتُونِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi èso tīn àti èso zaetūn búra.
See all translations of this verse →
وَطُورِ سِينِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àpáta Sīnīn búra.
See all translations of this verse →
وَهَٰذَا ٱلْبَلَدِ ٱلْأَمِينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.
See all translations of this verse →
لَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ فِىٓ أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.
See all translations of this verse →
ثُمَّ رَدَدْنَٰهُ أَسْفَلَ سَٰفِلِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
See all translations of this verse →
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
See all translations of this verse →
فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعْدُ بِٱلدِّينِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTa l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
See all translations of this verse →
أَلَيْسَ ٱللَّهُ بِأَحْكَمِ ٱلْحَٰكِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→