caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ad-Dhuhaa الضحى

11 verses · Mecca · revelation order 11

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلضُّحَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi ìyálẹ̀ta búra.

See all translations of this verse →

وَٱلَّيْلِ إِذَا سَجَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.

See all translations of this verse →

مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.

See all translations of this verse →

وَلَلْـَٔاخِرَةُ خَيْرٌ لَّكَ مِنَ ٱلْأُولَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.

See all translations of this verse →

وَلَسَوْفَ يُعْطِيكَ رَبُّكَ فَتَرْضَىٰٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.

See all translations of this verse →

أَلَمْ يَجِدْكَ يَتِيمًا فَـَٔاوَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.

See all translations of this verse →

وَوَجَدَكَ ضَآلًّا فَهَدَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.[1]

See all translations of this verse →

وَوَجَدَكَ عَآئِلًا فَأَغْنَىٰ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

فَأَمَّا ٱلْيَتِيمَ فَلَا تَقْهَرْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).

See all translations of this verse →

وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنْهَرْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).

See all translations of this verse →

وَأَمَّا بِنِعْمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70