caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Saad ص

88 verses · Mecca · revelation order 38

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ صٓ وَٱلْقُرْءَانِ ذِى ٱلذِّكْرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.)[1] Allāhu fi al-Ƙur’ān tí ó kún fún ìrántí bura.

See all translations of this verse →

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى عِزَّةٍ وَشِقَاقٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSíbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo).

See all translations of this verse →

كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّن قَرْنٍ فَنَادَوا۟ وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) nígbà tí kò sí ibùsásí kan.

See all translations of this verse →

وَعَجِبُوٓا۟ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ وَقَالَ ٱلْكَٰفِرُونَ هَٰذَا سَٰحِرٌ كَذَّابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni òpìdán, òpùrọ́.”

See all translations of this verse →

أَجَعَلَ ٱلْـَٔالِهَةَ إِلَٰهًا وَٰحِدًا إِنَّ هَٰذَا لَشَىْءٌ عُجَابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu.

See all translations of this verse →

وَٱنطَلَقَ ٱلْمَلَأُ مِنْهُمْ أَنِ ٱمْشُوا۟ وَٱصْبِرُوا۟ عَلَىٰٓ ءَالِهَتِكُمْ إِنَّ هَٰذَا لَشَىْءٌ يُرَادُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káà kiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: “Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbàlérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run).

See all translations of this verse →

مَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِى ٱلْمِلَّةِ ٱلْـَٔاخِرَةِ إِنْ هَٰذَآ إِلَّا ٱخْتِلَٰقٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄)[1]. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́.

See all translations of this verse →

أَءُنزِلَ عَلَيْهِ ٱلذِّكْرُ مِنۢ بَيْنِنَا بَلْ هُمْ فِى شَكٍّ مِّن ذِكْرِى بَل لَّمَّا يَذُوقُوا۟ عَذَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé Wọ́n sọ (tírà) Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?” Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa (tírà) Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni.

See all translations of this verse →

أَمْ عِندَهُمْ خَزَآئِنُ رَحْمَةِ رَبِّكَ ٱلْعَزِيزِ ٱلْوَهَّابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí tiwọn ni àwọn ilé ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ?

See all translations of this verse →

أَمْ لَهُم مُّلْكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا فَلْيَرْتَقُوا۟ فِى ٱلْأَسْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa).

See all translations of this verse →

جُندٌ مَّا هُنَالِكَ مَهْزُومٌ مِّنَ ٱلْأَحْزَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA máa ṣẹ́gun ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ.[1]

See all translations of this verse →

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ ذُو ٱلْأَوْتَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.

See all translations of this verse →

وَثَمُودُ وَقَوْمُ لُوطٍ وَأَصْحَٰبُ لْـَٔيْكَةِ أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلْأَحْزَابُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará ’Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (tó pe òdodo ní irọ́).

See all translations of this verse →

إِن كُلٌّ إِلَّا كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ عِقَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí.

See all translations of this verse →

وَمَا يَنظُرُ هَٰٓؤُلَآءِ إِلَّا صَيْحَةً وَٰحِدَةً مَّا لَهَا مِن فَوَاقٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan, tí kò níí ní ìdádúró.[1]

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ رَبَّنَا عَجِّل لَّنَا قِطَّنَا قَبْلَ يَوْمِ ٱلْحِسَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ìpín ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.”

See all translations of this verse →

ٱصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱذْكُرْ عَبْدَنَا دَاوُۥدَ ذَا ٱلْأَيْدِ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà.

See all translations of this verse →

إِنَّا سَخَّرْنَا ٱلْجِبَالَ مَعَهُۥ يُسَبِّحْنَ بِٱلْعَشِىِّ وَٱلْإِشْرَاقِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ (ní òwúrọ̀).

See all translations of this verse →

وَٱلطَّيْرَ مَحْشُورَةً كُلٌّ لَّهُۥٓ أَوَّابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu).

See all translations of this verse →

وَشَدَدْنَا مُلْكَهُۥ وَءَاتَيْنَٰهُ ٱلْحِكْمَةَ وَفَصْلَ ٱلْخِطَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́.

See all translations of this verse →

وَهَلْ أَتَىٰكَ نَبَؤُا۟ ٱلْخَصْمِ إِذْ تَسَوَّرُوا۟ ٱلْمِحْرَابَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn?

See all translations of this verse →

إِذْ دَخَلُوا۟ عَلَىٰ دَاوُۥدَ فَفَزِعَ مِنْهُمْ قَالُوا۟ لَا تَخَفْ خَصْمَانِ بَغَىٰ بَعْضُنَا عَلَىٰ بَعْضٍ فَٱحْكُم بَيْنَنَا بِٱلْحَقِّ وَلَا تُشْطِطْ وَٱهْدِنَآ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلصِّرَٰطِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù wọn bà á. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-ààlà sí apá kan. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin wa. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذَآ أَخِى لَهُۥ تِسْعٌ وَتِسْعُونَ نَعْجَةً وَلِىَ نَعْجَةٌ وَٰحِدَةٌ فَقَالَ أَكْفِلْنِيهَا وَعَزَّنِى فِى ٱلْخِطَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: “Fà á lé mi lọ́wọ́ (Fi mí ṣe alámòójútó rẹ̀). Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀.” (Ó fi ọ̀rọ̀ tirẹ̀ borí ọ̀rọ̀ tèmi.)

See all translations of this verse →

قَالَ لَقَدْ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعْجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ ٱلْخُلَطَآءِ لَيَبْغِى بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٌ مَّا هُمْ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّٰهُ فَٱسْتَغْفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّ رَاكِعًا وَأَنَابَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì Dāwūd) sọ pé: “Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-ààlà lórí apá kan àfi àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n.” (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).[1]

See all translations of this verse →

فَغَفَرْنَا لَهُۥ ذَٰلِكَ وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلْفَىٰ وَحُسْنَ مَـَٔابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

يَٰدَاوُۥدُ إِنَّا جَعَلْنَٰكَ خَلِيفَةً فِى ٱلْأَرْضِ فَٱحْكُم بَيْنَ ٱلنَّاسِ بِٱلْحَقِّ وَلَا تَتَّبِعِ ٱلْهَوَىٰ فَيُضِلَّكَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَضِلُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌۢ بِمَا نَسُوا۟ يَوْمَ ٱلْحِسَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé, wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَمَا خَلَقْنَا ٱلسَّمَآءَ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا بَٰطِلًا ذَٰلِكَ ظَنُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنَ ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò fi irọ́ ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. (Irọ́), ìyẹn ni èrò ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (sí Wa). Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná.

See all translations of this verse →

أَمْ نَجْعَلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ كَٱلْمُفْسِدِينَ فِى ٱلْأَرْضِ أَمْ نَجْعَلُ ٱلْمُتَّقِينَ كَٱلْفُجَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kí Á ṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi?

See all translations of this verse →

كِتَٰبٌ أَنزَلْنَٰهُ إِلَيْكَ مُبَٰرَكٌ لِّيَدَّبَّرُوٓا۟ ءَايَٰتِهِۦ وَلِيَتَذَكَّرَ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.

See all translations of this verse →

وَوَهَبْنَا لِدَاوُۥدَ سُلَيْمَٰنَ نِعْمَ ٱلْعَبْدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà).

See all translations of this verse →

إِذْ عُرِضَ عَلَيْهِ بِٱلْعَشِىِّ ٱلصَّٰفِنَٰتُ ٱلْجِيَادُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́,

See all translations of this verse →

فَقَالَ إِنِّىٓ أَحْبَبْتُ حُبَّ ٱلْخَيْرِ عَن ذِكْرِ رَبِّى حَتَّىٰ تَوَارَتْ بِٱلْحِجَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeló sọ pé: “Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀.

See all translations of this verse →

رُدُّوهَا عَلَىَّ فَطَفِقَ مَسْحًۢا بِٱلسُّوقِ وَٱلْأَعْنَاقِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ فَتَنَّا سُلَيْمَٰنَ وَأَلْقَيْنَا عَلَىٰ كُرْسِيِّهِۦ جَسَدًا ثُمَّ أَنَابَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà).[1]

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ ٱغْفِرْ لِى وَهَبْ لِى مُلْكًا لَّا يَنۢبَغِى لِأَحَدٍ مِّنۢ بَعْدِىٓ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْوَهَّابُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ.”

See all translations of this verse →

فَسَخَّرْنَا لَهُ ٱلرِّيحَ تَجْرِى بِأَمْرِهِۦ رُخَآءً حَيْثُ أَصَابَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́.

See all translations of this verse →

وَٱلشَّيَٰطِينَ كُلَّ بَنَّآءٍ وَغَوَّاصٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un).

See all translations of this verse →

وَءَاخَرِينَ مُقَرَّنِينَ فِى ٱلْأَصْفَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un).

See all translations of this verse →

هَٰذَا عَطَآؤُنَا فَٱمْنُنْ أَوْ أَمْسِكْ بِغَيْرِ حِسَابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání[1] láì níí ní ìṣírò.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلْفَىٰ وَحُسْنَ مَـَٔابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

وَٱذْكُرْ عَبْدَنَآ أَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُۥٓ أَنِّى مَسَّنِىَ ٱلشَّيْطَٰنُ بِنُصْبٍ وَعَذَابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì)’Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): “Dájúdájú aṣ-Ṣaetọ̄n ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi.”[1]

See all translations of this verse →

ٱرْكُضْ بِرِجْلِكَ هَٰذَا مُغْتَسَلٌۢ بَارِدٌ وَشَرَابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Mọlāika sọ fún un pé): “Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ).”

See all translations of this verse →

وَوَهَبْنَا لَهُۥٓ أَهْلَهُۥ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنَّا وَذِكْرَىٰ لِأُو۟لِى ٱلْأَلْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.

See all translations of this verse →

وَخُذْ بِيَدِكَ ضِغْثًا فَٱضْرِب بِّهِۦ وَلَا تَحْنَثْ إِنَّا وَجَدْنَٰهُ صَابِرًا نِّعْمَ ٱلْعَبْدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ.[1] Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà).

See all translations of this verse →

وَٱذْكُرْ عِبَٰدَنَآ إِبْرَٰهِيمَ وَإِسْحَٰقَ وَيَعْقُوبَ أُو۟لِى ٱلْأَيْدِى وَٱلْأَبْصَٰرِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára àti olùríran (nípa ẹ̀sìn).

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَخْلَصْنَٰهُم بِخَالِصَةٍ ذِكْرَى ٱلدَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan, (òhun ni) ìrántí Ilé náà (ilé Ìkẹ́yìn).

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُمْ عِندَنَا لَمِنَ ٱلْمُصْطَفَيْنَ ٱلْأَخْيَارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

وَٱذْكُرْ إِسْمَٰعِيلَ وَٱلْيَسَعَ وَذَا ٱلْكِفْلِ وَكُلٌّ مِّنَ ٱلْأَخْيَارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ.

See all translations of this verse →

هَٰذَا ذِكْرٌ وَإِنَّ لِلْمُتَّقِينَ لَحُسْنَ مَـَٔابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

جَنَّٰتِ عَدْنٍ مُّفَتَّحَةً لَّهُمُ ٱلْأَبْوَٰبُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.

See all translations of this verse →

مُتَّكِـِٔينَ فِيهَا يَدْعُونَ فِيهَا بِفَٰكِهَةٍ كَثِيرَةٍ وَشَرَابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَعِندَهُمْ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرْفِ أَتْرَابٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.

See all translations of this verse →

هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِيَوْمِ ٱلْحِسَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذَا لَرِزْقُنَا مَا لَهُۥ مِن نَّفَادٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán.

See all translations of this verse →

هَٰذَا وَإِنَّ لِلطَّٰغِينَ لَشَرَّ مَـَٔابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu).

See all translations of this verse →

جَهَنَّمَ يَصْلَوْنَهَا فَبِئْسَ ٱلْمِهَادُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé.

See all translations of this verse →

هَٰذَا فَلْيَذُوقُوهُ حَمِيمٌ وَغَسَّاقٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.

See all translations of this verse →

وَءَاخَرُ مِن شَكْلِهِۦٓ أَزْوَٰجٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

See all translations of this verse →

هَٰذَا فَوْجٌ مُّقْتَحِمٌ مَّعَكُمْ لَا مَرْحَبًۢا بِهِمْ إِنَّهُمْ صَالُوا۟ ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí ni ìjọ kan tó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) “Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn.” Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ بَلْ أَنتُمْ لَا مَرْحَبًۢا بِكُمْ أَنتُمْ قَدَّمْتُمُوهُ لَنَا فَبِئْسَ ٱلْقَرَارُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: “Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fún yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (tó bí Iná).” Ó sì burú ní ibùgbé.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدْهُ عَذَابًا ضِعْفًا فِى ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n (tún) wí pé: “Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná.”

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالًا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ ٱلْأَشْرَارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n tún wí pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a kò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú.

See all translations of this verse →

أَتَّخَذْنَٰهُمْ سِخْرِيًّا أَمْ زَاغَتْ عَنْهُمُ ٱلْأَبْصَٰرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)?”

See all translations of this verse →

إِنَّ ذَٰلِكَ لَحَقٌّ تَخَاصُمُ أَهْلِ ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni.

See all translations of this verse →

قُلْ إِنَّمَآ أَنَا۠ مُنذِرٌ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُ ٱلْوَٰحِدُ ٱلْقَهَّارُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

See all translations of this verse →

رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ٱلْعَزِيزُ ٱلْغَفَّٰرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOlúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn.”

See all translations of this verse →

قُلْ هُوَ نَبَؤٌا۟ عَظِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá.

See all translations of this verse →

أَنتُمْ عَنْهُ مُعْرِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.

See all translations of this verse →

مَا كَانَ لِىَ مِنْ عِلْمٍۭ بِٱلْمَلَإِ ٱلْأَعْلَىٰٓ إِذْ يَخْتَصِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé.

See all translations of this verse →

إِن يُوحَىٰٓ إِلَىَّ إِلَّآ أَنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّى خَٰلِقٌۢ بَشَرًا مِّن طِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrẹ̀.

See all translations of this verse →

فَإِذَا سَوَّيْتُهُۥ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِى فَقَعُوا۟ لَهُۥ سَٰجِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí Mo bá ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un, kí ẹ forí kanlẹ̀ kí i.”

See all translations of this verse →

فَسَجَدَ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.

See all translations of this verse →

إِلَّآ إِبْلِيسَ ٱسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

قَالَ يَٰٓإِبْلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسْجُدَ لِمَا خَلَقْتُ بِيَدَىَّ أَسْتَكْبَرْتَ أَمْ كُنتَ مِنَ ٱلْعَالِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga?”

See all translations of this verse →

قَالَ أَنَا۠ خَيْرٌ مِّنْهُ خَلَقْتَنِى مِن نَّارٍ وَخَلَقْتَهُۥ مِن طِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wí pé: “Èmi lóore jù ú lọ; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara ẹrẹ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَٱخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé, dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀.

See all translations of this verse →

وَإِنَّ عَلَيْكَ لَعْنَتِىٓ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلدِّينِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِىٓ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلْمُنظَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára

See all translations of this verse →

إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْوَقْتِ ٱلْمَعْلُومِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltítí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà

See all translations of this verse →

إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ ٱلْمُخْلَصِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo) nínú wọn.”

See all translations of this verse →

قَالَ فَٱلْحَقُّ وَٱلْحَقَّ أَقُولُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)

See all translations of this verse →

لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنْهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn tó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ.”

See all translations of this verse →

قُلْ مَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلْمُتَكَلِّفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ.”

See all translations of this verse →

إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

وَلَتَعْلَمُنَّ نَبَأَهُۥ بَعْدَ حِينٍۭ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70