caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Az-Zumar الزمر

75 verses · Mecca · revelation order 59

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ تَنزِيلُ ٱلْكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَكِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀[1] láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَنزَلْنَآ إِلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ بِٱلْحَقِّ فَٱعْبُدِ ٱللَّهَ مُخْلِصًا لَّهُ ٱلدِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1]

See all translations of this verse →

أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلْخَالِصُ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلْفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِى مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى مَنْ هُوَ كَٰذِبٌ كَفَّارٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelGbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.[1] Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): “A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni.” Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

لَّوْ أَرَادَ ٱللَّهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا لَّٱصْطَفَىٰ مِمَّا يَخْلُقُ مَا يَشَآءُ سُبْحَٰنَهُۥ هُوَ ٱللَّهُ ٱلْوَٰحِدُ ٱلْقَهَّارُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

See all translations of this verse →

خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِٱلْحَقِّ يُكَوِّرُ ٱلَّيْلَ عَلَى ٱلنَّهَارِ وَيُكَوِّرُ ٱلنَّهَارَ عَلَى ٱلَّيْلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِى لِأَجَلٍ مُّسَمًّى أَلَا هُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْغَفَّٰرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn.

See all translations of this verse →

خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَٰحِدَةٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلْأَنْعَٰمِ ثَمَٰنِيَةَ أَزْوَٰجٍ يَخْلُقُكُمْ فِى بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمْ خَلْقًا مِّنۢ بَعْدِ خَلْقٍ فِى ظُلُمَٰتٍ ثَلَٰثٍ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ ٱلْمُلْكُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fún yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ- tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta.[1] Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

See all translations of this verse →

إِن تَكْفُرُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِىٌّ عَنكُمْ وَلَا يَرْضَىٰ لِعِبَادِهِ ٱلْكُفْرَ وَإِن تَشْكُرُوا۟ يَرْضَهُ لَكُمْ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرْجِعُكُمْ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fún yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

وَإِذَا مَسَّ ٱلْإِنسَٰنَ ضُرٌّ دَعَا رَبَّهُۥ مُنِيبًا إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُۥ نِعْمَةً مِّنْهُ نَسِىَ مَا كَانَ يَدْعُوٓا۟ إِلَيْهِ مِن قَبْلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادًا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِۦ قُلْ تَمَتَّعْ بِكُفْرِكَ قَلِيلًا إِنَّكَ مِنْ أَصْحَٰبِ ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ lẹ́ni tí ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun tó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: “Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná.”

See all translations of this verse →

أَمَّنْ هُوَ قَٰنِتٌ ءَانَآءَ ٱلَّيْلِ سَاجِدًا وَقَآئِمًا يَحْذَرُ ٱلْـَٔاخِرَةَ وَيَرْجُوا۟ رَحْمَةَ رَبِّهِۦ قُلْ هَلْ يَسْتَوِى ٱلَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَٱلَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (tó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, tó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, tó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí.

See all translations of this verse →

قُلْ يَٰعِبَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّقُوا۟ رَبَّكُمْ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا۟ فِى هَٰذِهِ ٱلدُّنْيَا حَسَنَةٌ وَأَرْضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٌ إِنَّمَا يُوَفَّى ٱلصَّٰبِرُونَ أَجْرَهُم بِغَيْرِ حِسَابٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí.[1] Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò.² Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láì níí ní ìṣírò.”

See all translations of this verse →

قُلْ إِنِّىٓ أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ ٱللَّهَ مُخْلِصًا لَّهُ ٱلدِّينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1]

See all translations of this verse →

وَأُمِرْتُ لِأَنْ أَكُونَ أَوَّلَ ٱلْمُسْلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi).”[1]

See all translations of this verse →

قُلْ إِنِّىٓ أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّى عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi.”

See all translations of this verse →

قُلِ ٱللَّهَ أَعْبُدُ مُخْلِصًا لَّهُۥ دِينِى

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún lẹ́ni tí èmi yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn mi fún Un

See all translations of this verse →

فَٱعْبُدُوا۟ مَا شِئْتُم مِّن دُونِهِۦ قُلْ إِنَّ ٱلْخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْخُسْرَانُ ٱلْمُبِينُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀.”[1] Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

لَهُم مِّن فَوْقِهِمْ ظُلَلٌ مِّنَ ٱلنَّارِ وَمِن تَحْتِهِمْ ظُلَلٌ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ ٱللَّهُ بِهِۦ عِبَادَهُۥ يَٰعِبَادِ فَٱتَّقُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi.”

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ٱجْتَنَبُوا۟ ٱلطَّٰغُوتَ أَن يَعْبُدُوهَا وَأَنَابُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ لَهُمُ ٱلْبُشْرَىٰ فَبَشِّرْ عِبَادِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tí wọ́n takété sí àwọn òrìṣà tí wọn kò jọ́sìn fún un,[1] wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَسْتَمِعُونَ ٱلْقَوْلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحْسَنَهُۥٓ أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمْ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí tó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.

See all translations of this verse →

أَفَمَنْ حَقَّ عَلَيْهِ كَلِمَةُ ٱلْعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِى ٱلنَّارِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni tó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?

See all translations of this verse →

لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ رَبَّهُمْ لَهُمْ غُرَفٌ مِّن فَوْقِهَا غُرَفٌ مَّبْنِيَّةٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ وَعْدَ ٱللَّهِ لَا يُخْلِفُ ٱللَّهُ ٱلْمِيعَادَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَسَلَكَهُۥ يَنَٰبِيعَ فِى ٱلْأَرْضِ ثُمَّ يُخْرِجُ بِهِۦ زَرْعًا مُّخْتَلِفًا أَلْوَٰنُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَجْعَلُهُۥ حُطَٰمًا إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِأُو۟لِى ٱلْأَلْبَٰبِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà wọnú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

See all translations of this verse →

أَفَمَن شَرَحَ ٱللَّهُ صَدْرَهُۥ لِلْإِسْلَٰمِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٍ مِّن رَّبِّهِۦ فَوَيْلٌ لِّلْقَٰسِيَةِ قُلُوبُهُم مِّن ذِكْرِ ٱللَّهِ أُو۟لَٰٓئِكَ فِى ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn ’Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ نَزَّلَ أَحْسَنَ ٱلْحَدِيثِ كِتَٰبًا مُّتَشَٰبِهًا مَّثَانِىَ تَقْشَعِرُّ مِنْهُ جُلُودُ ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمْ وَقُلُوبُهُمْ إِلَىٰ ذِكْرِ ٱللَّهِ ذَٰلِكَ هُدَى ٱللَّهِ يَهْدِى بِهِۦ مَن يَشَآءُ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنْ هَادٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu l’Ó sọ ọ̀rọ̀ tó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn tó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un.

See all translations of this verse →

أَفَمَن يَتَّقِى بِوَجْهِهِۦ سُوٓءَ ٱلْعَذَابِ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ وَقِيلَ لِلظَّٰلِمِينَ ذُوقُوا۟ مَا كُنتُمْ تَكْسِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”

See all translations of this verse →

كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَأَتَىٰهُمُ ٱلْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣíwájú wọn pe òdodo ní irọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.

See all translations of this verse →

فَأَذَاقَهُمُ ٱللَّهُ ٱلْخِزْىَ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَكْبَرُ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِى هَٰذَا ٱلْقُرْءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ti ṣe gbogbo àkàwé (àpèjúwe àti àpẹ̀ẹrẹ) fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

See all translations of this verse →

قُرْءَانًا عَرَبِيًّا غَيْرَ ذِى عِوَجٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAl-Ƙur’ān (tí A sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú) èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا رَّجُلًا فِيهِ شُرَكَآءُ مُتَشَٰكِسُونَ وَرَجُلًا سَلَمًا لِّرَجُلٍ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan tó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà lórí rẹ̀ (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan tó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّكَ مَيِّتٌ وَإِنَّهُم مَّيِّتُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú.

See all translations of this verse →

ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ عِندَ رَبِّكُمْ تَخْتَصِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

See all translations of this verse →

فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن كَذَبَ عَلَى ٱللَّهِ وَكَذَّبَ بِٱلصِّدْقِ إِذْ جَآءَهُۥٓ أَلَيْسَ فِى جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tó parọ́ mọ́ Allāhu, tó tún pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِى جَآءَ بِٱلصِّدْقِ وَصَدَّقَ بِهِۦٓ أُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُتَّقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti (àwọn) ẹni tó jẹ́rìí sí òdodo náà; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu).

See all translations of this verse →

لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمْ ذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلْمُحْسِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere

See all translations of this verse →

لِيُكَفِّرَ ٱللَّهُ عَنْهُمْ أَسْوَأَ ٱلَّذِى عَمِلُوا۟ وَيَجْزِيَهُمْ أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ ٱلَّذِى كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelnítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe níṣẹ́ rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.

See all translations of this verse →

أَلَيْسَ ٱللَّهُ بِكَافٍ عَبْدَهُۥ وَيُخَوِّفُونَكَ بِٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنْ هَادٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.

See all translations of this verse →

وَمَن يَهْدِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّضِلٍّ أَلَيْسَ ٱللَّهُ بِعَزِيزٍ ذِى ٱنتِقَامٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san?

See all translations of this verse →

وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ قُلْ أَفَرَءَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ إِنْ أَرَادَنِىَ ٱللَّهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَٰشِفَٰتُ ضُرِّهِۦٓ أَوْ أَرَادَنِى بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَٰتُ رَحْمَتِهِۦ قُلْ حَسْبِىَ ٱللَّهُ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ ٱلْمُتَوَكِّلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?” Sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé.”

See all translations of this verse →

قُلْ يَٰقَوْمِ ٱعْمَلُوا۟ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّى عَٰمِلٌ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ

See all translations of this verse →

مَن يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُّقِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí.”

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَنزَلْنَا عَلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ لِلنَّاسِ بِٱلْحَقِّ فَمَنِ ٱهْتَدَىٰ فَلِنَفْسِهِۦ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا وَمَآ أَنتَ عَلَيْهِم بِوَكِيلٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ يَتَوَفَّى ٱلْأَنفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَٱلَّتِى لَمْ تَمُتْ فِى مَنَامِهَا فَيُمْسِكُ ٱلَّتِى قَضَىٰ عَلَيْهَا ٱلْمَوْتَ وَيُرْسِلُ ٱلْأُخْرَىٰٓ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.

See all translations of this verse →

أَمِ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُفَعَآءَ قُلْ أَوَلَوْ كَانُوا۟ لَا يَمْلِكُونَ شَيْـًٔا وَلَا يَعْقِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) tó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè!”

See all translations of this verse →

قُل لِّلَّهِ ٱلشَّفَٰعَةُ جَمِيعًا لَّهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.”

See all translations of this verse →

وَإِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَحْدَهُ ٱشْمَأَزَّتْ قُلُوبُ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱلْـَٔاخِرَةِ وَإِذَا ذُكِرَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦٓ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú.

See all translations of this verse →

قُلِ ٱللَّهُمَّ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ عَٰلِمَ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ أَنتَ تَحْكُمُ بَيْنَ عِبَادِكَ فِى مَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l’O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.”

See all translations of this verse →

وَلَوْ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مَا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفْتَدَوْا۟ بِهِۦ مِن سُوٓءِ ٱلْعَذَابِ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ وَبَدَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مَا لَمْ يَكُونُوا۟ يَحْتَسِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu;

See all translations of this verse →

وَبَدَا لَهُمْ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُوا۟ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà tó máa yí wọn po.

See all translations of this verse →

فَإِذَا مَسَّ ٱلْإِنسَٰنَ ضُرٌّ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلْنَٰهُ نِعْمَةً مِّنَّا قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلْمٍۭ بَلْ هِىَ فِتْنَةٌ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: “Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni.”[1] Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

See all translations of this verse →

قَدْ قَالَهَا ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَمَآ أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

See all translations of this verse →

فَأَصَابَهُمْ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُوا۟ وَٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مِنْ هَٰٓؤُلَآءِ سَيُصِيبُهُمْ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُوا۟ وَمَا هُم بِمُعْجِزِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́.

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقْدِرُ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

قُلْ يَٰعِبَادِىَ ٱلَّذِينَ أَسْرَفُوا۟ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا۟ مِن رَّحْمَةِ ٱللَّهِ إِنَّ ٱللَّهَ يَغْفِرُ ٱلذُّنُوبَ جَمِيعًا إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَأَنِيبُوٓا۟ إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَأَسْلِمُوا۟ لَهُۥ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَكُمُ ٱلْعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A kò níí ràn yín lọ́wọ́.

See all translations of this verse →

وَٱتَّبِعُوٓا۟ أَحْسَنَ مَآ أُنزِلَ إِلَيْكُم مِّن رَّبِّكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَكُمُ ٱلْعَذَابُ بَغْتَةً وَأَنتُمْ لَا تَشْعُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura.”

See all translations of this verse →

أَن تَقُولَ نَفْسٌ يَٰحَسْرَتَىٰ عَلَىٰ مَا فَرَّطتُ فِى جَنۢبِ ٱللَّهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ ٱلسَّٰخِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: “Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn tó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́.”

See all translations of this verse →

أَوْ تَقُولَ لَوْ أَنَّ ٱللَّهَ هَدَىٰنِى لَكُنتُ مِنَ ٱلْمُتَّقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí kí ó má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).”

See all translations of this verse →

أَوْ تَقُولَ حِينَ تَرَى ٱلْعَذَابَ لَوْ أَنَّ لِى كَرَّةً فَأَكُونَ مِنَ ٱلْمُحْسِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere.”

See all translations of this verse →

بَلَىٰ قَدْ جَآءَتْكَ ءَايَٰتِى فَكَذَّبْتَ بِهَا وَٱسْتَكْبَرْتَ وَكُنتَ مِنَ ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBẹ́ẹ̀ ni! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é ní irọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́. [1]

See all translations of this verse →

وَيَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ تَرَى ٱلَّذِينَ كَذَبُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ وُجُوهُهُم مُّسْوَدَّةٌ أَلَيْسَ فِى جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْمُتَكَبِّرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn tó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni?

See all translations of this verse →

وَيُنَجِّى ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ بِمَفَازَتِهِمْ لَا يَمَسُّهُمُ ٱلسُّوٓءُ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu yóò gba àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú náà kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́.

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَىْءٍ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ وَكِيلٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

لَّهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ أُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَٰسِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

See all translations of this verse →

قُلْ أَفَغَيْرَ ٱللَّهِ تَأْمُرُوٓنِّىٓ أَعْبُدُ أَيُّهَا ٱلْجَٰهِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l’ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan?”

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ أُوحِىَ إِلَيْكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِكَ لَئِنْ أَشْرَكْتَ لَيَحْبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلْخَٰسِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ (pé) “Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.”

See all translations of this verse →

بَلِ ٱللَّهَ فَٱعْبُدْ وَكُن مِّنَ ٱلشَّٰكِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un).

See all translations of this verse →

وَمَا قَدَرُوا۟ ٱللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِۦ وَٱلْأَرْضُ جَمِيعًا قَبْضَتُهُۥ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُ مَطْوِيَّٰتٌۢ بِيَمِينِهِۦ سُبْحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká àwọn sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

See all translations of this verse →

وَنُفِخَ فِى ٱلصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِى ٱلْأَرْضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَىٰ فَإِذَا هُمْ قِيَامٌ يَنظُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n á fọn fèrè oníwo (fún ikú). Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.

See all translations of this verse →

وَأَشْرَقَتِ ٱلْأَرْضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ ٱلْكِتَٰبُ وَجِا۟ىٓءَ بِٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَقُضِىَ بَيْنَهُم بِٱلْحَقِّ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wọn. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

See all translations of this verse →

وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

وَسِيقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًا حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا فُتِحَتْ أَبْوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَآ أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِّنكُمْ يَتْلُونَ عَلَيْكُمْ ءَايَٰتِ رَبِّكُمْ وَيُنذِرُونَكُمْ لِقَآءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا قَالُوا۟ بَلَىٰ وَلَٰكِنْ حَقَّتْ كَلِمَةُ ٱلْعَذَابِ عَلَى ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn yó sì da àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahanamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fún yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fún yín?” Wọ́n wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (wọ́n wá bá wa).” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.

See all translations of this verse →

قِيلَ ٱدْخُلُوٓا۟ أَبْوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَا فَبِئْسَ مَثْوَى ٱلْمُتَكَبِّرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA óò sọ pé: “Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.

See all translations of this verse →

وَسِيقَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ رَبَّهُمْ إِلَى ٱلْجَنَّةِ زُمَرًا حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا وَفُتِحَتْ أَبْوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا سَلَٰمٌ عَلَيْكُمْ طِبْتُمْ فَٱدْخُلُوهَا خَٰلِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A óò kó àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Kí àlàáfíà máa bá yín. Ẹ̀yin dára (nítorí iṣẹ́ yín tó dára). Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére(nínú rẹ̀).”[1]

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ٱلَّذِى صَدَقَنَا وَعْدَهُۥ وَأَوْرَثَنَا ٱلْأَرْضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ ٱلْجَنَّةِ حَيْثُ نَشَآءُ فَنِعْمَ أَجْرُ ٱلْعَٰمِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n á sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára.

See all translations of this verse →

وَتَرَى ٱلْمَلَٰٓئِكَةَ حَآفِّينَ مِنْ حَوْلِ ٱلْعَرْشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَقُضِىَ بَيْنَهُم بِٱلْحَقِّ وَقِيلَ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelO sì máa rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní àyíká Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70