caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà As-Sajda السجدة

30 verses · Mecca · revelation order 75

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ الٓمٓ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]

See all translations of this verse →

تَنزِيلُ ٱلْكِتَٰبِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

أَمْ يَقُولُونَ ٱفْتَرَىٰهُ بَلْ هُوَ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٍ مِّن قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.[1]

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ مَا لَكُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِىٍّ وَلَا شَفِيعٍ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fún yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?

See all translations of this verse →

يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ إِلَى ٱلْأَرْضِ ثُمَّ يَعْرُجُ إِلَيْهِ فِى يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُۥٓ أَلْفَ سَنَةٍ مِّمَّا تَعُدُّونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà.[1]

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ عَٰلِمُ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run,

See all translations of this verse →

ٱلَّذِىٓ أَحْسَنَ كُلَّ شَىْءٍ خَلَقَهُۥ وَبَدَأَ خَلْقَ ٱلْإِنسَٰنِ مِن طِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú ẹrẹ̀.

See all translations of this verse →

ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُۥ مِن سُلَٰلَةٍ مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ.

See all translations of this verse →

ثُمَّ سَوَّىٰهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِۦ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá).[1] Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá!

See all translations of this verse →

وَقَالُوٓا۟ أَءِذَا ضَلَلْنَا فِى ٱلْأَرْضِ أَءِنَّا لَفِى خَلْقٍ جَدِيدٍۭ بَلْ هُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمْ كَٰفِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

See all translations of this verse →

قُلْ يَتَوَفَّىٰكُم مَّلَكُ ٱلْمَوْتِ ٱلَّذِى وُكِّلَ بِكُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A yàn fún yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”[1]

See all translations of this verse →

وَلَوْ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلْمُجْرِمُونَ نَاكِسُوا۟ رُءُوسِهِمْ عِندَ رَبِّهِمْ رَبَّنَآ أَبْصَرْنَا وَسَمِعْنَا فَٱرْجِعْنَا نَعْمَلْ صَٰلِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”

See all translations of this verse →

وَلَوْ شِئْنَا لَـَٔاتَيْنَا كُلَّ نَفْسٍ هُدَىٰهَا وَلَٰكِنْ حَقَّ ٱلْقَوْلُ مِنِّى لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلْجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”

See all translations of this verse →

فَذُوقُوا۟ بِمَا نَسِيتُمْ لِقَآءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَآ إِنَّا نَسِينَٰكُمْ وَذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْخُلْدِ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín (sínú Iná). Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]

See all translations of this verse →

إِنَّمَا يُؤْمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا۟ بِهَا خَرُّوا۟ سُجَّدًا وَسَبَّحُوا۟ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga.

See all translations of this verse →

تَتَجَافَىٰ جُنُوبُهُمْ عَنِ ٱلْمَضَاجِعِ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ خَوْفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقْنَٰهُمْ يُنفِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn jìnnà sí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

See all translations of this verse →

فَلَا تَعْلَمُ نَفْسٌ مَّآ أُخْفِىَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

See all translations of this verse →

أَفَمَن كَانَ مُؤْمِنًا كَمَن كَانَ فَاسِقًا لَّا يَسْتَوُۥنَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni tó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba.

See all translations of this verse →

أَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمْ جَنَّٰتُ ٱلْمَأْوَىٰ نُزُلًۢا بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

See all translations of this verse →

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فَسَقُوا۟ فَمَأْوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ كُلَّمَآ أَرَادُوٓا۟ أَن يَخْرُجُوا۟ مِنْهَآ أُعِيدُوا۟ فِيهَا وَقِيلَ لَهُمْ ذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”[1]

See all translations of this verse →

وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ ٱلْعَذَابِ ٱلْأَدْنَىٰ دُونَ ٱلْعَذَابِ ٱلْأَكْبَرِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà tó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà tó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn).

See all translations of this verse →

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعْرَضَ عَنْهَآ إِنَّا مِنَ ٱلْمُجْرِمِينَ مُنتَقِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ta l’ó ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا مُوسَى ٱلْكِتَٰبَ فَلَا تَكُن فِى مِرْيَةٍ مِّن لِّقَآئِهِۦ وَجَعَلْنَٰهُ هُدًى لِّبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí o ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀).[1] A sì ṣe Tírà A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا۟ وَكَانُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا يُوقِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A ṣe àwọn kan nínú wọn ní Imām (aṣíwájú) tí wọ́n ń fi àṣẹ Wa (ohun tí A pa wọ́n ní àṣẹ rẹ̀ nínú at-Taorāh) tọ́ àwọn ènìyàn wọn sí ọ̀nà òdodo. (A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.

See all translations of this verse →

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّنَ ٱلْقُرُونِ يَمْشُونَ فِى مَسَٰكِنِهِمْ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ أَفَلَا يَسْمَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)?

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا نَسُوقُ ٱلْمَآءَ إِلَى ٱلْأَرْضِ ٱلْجُرُزِ فَنُخْرِجُ بِهِۦ زَرْعًا تَأْكُلُ مِنْهُ أَنْعَٰمُهُمْ وَأَنفُسُهُمْ أَفَلَا يُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni?

See all translations of this verse →

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلْفَتْحُ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

See all translations of this verse →

قُلْ يَوْمَ ٱلْفَتْحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِيمَٰنُهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí lọ́ wọn lára láti ronúpìwàdà.”.”[1]

See all translations of this verse →

فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَٱنتَظِرْ إِنَّهُم مُّنتَظِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀).

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70