caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Anbiyaa الأنبياء

112 verses · Mecca · revelation order 73

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱقْتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمْ وَهُمْ فِى غَفْلَةٍ مُّعْرِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo).

See all translations of this verse →

مَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّن رَّبِّهِم مُّحْدَثٍ إِلَّا ٱسْتَمَعُوهُ وَهُمْ يَلْعَبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ lẹ́ni tí yóò máa (fi) ṣeré.

See all translations of this verse →

لَاهِيَةً قُلُوبُهُمْ وَأَسَرُّوا۟ ٱلنَّجْوَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ هَلْ هَٰذَآ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ أَفَتَأْتُونَ ٱلسِّحْرَ وَأَنتُمْ تُبْصِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn tó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: “Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran?”

See all translations of this verse →

قَالَ رَبِّى يَعْلَمُ ٱلْقَوْلَ فِى ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ tó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

See all translations of this verse →

بَلْ قَالُوٓا۟ أَضْغَٰثُ أَحْلَٰمٍۭ بَلِ ٱفْتَرَىٰهُ بَلْ هُوَ شَاعِرٌ فَلْيَأْتِنَا بِـَٔايَةٍ كَمَآ أُرْسِلَ ٱلْأَوَّلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, wọ́n tún wí pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ ni (al-Ƙur’ān.” Wọ́n tún wí pé): “Rárá, ó hun ún ni.” (Wọ́n tún wí pé): “Rárá, eléwì ni. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

See all translations of this verse →

مَآ ءَامَنَتْ قَبْلَهُم مِّن قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَٰهَآ أَفَهُمْ يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí àwọn tó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)?

See all translations of this verse →

وَمَآ أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِىٓ إِلَيْهِمْ فَسْـَٔلُوٓا۟ أَهْلَ ٱلذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.[1]

See all translations of this verse →

وَمَا جَعَلْنَٰهُمْ جَسَدًا لَّا يَأْكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَمَا كَانُوا۟ خَٰلِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kì í jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).[1]

See all translations of this verse →

ثُمَّ صَدَقْنَٰهُمُ ٱلْوَعْدَ فَأَنجَيْنَٰهُمْ وَمَن نَّشَآءُ وَأَهْلَكْنَا ٱلْمُسْرِفِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà run.

See all translations of this verse →

لَقَدْ أَنزَلْنَآ إِلَيْكُمْ كِتَٰبًا فِيهِ ذِكْرُكُمْ أَفَلَا تَعْقِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fún yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

See all translations of this verse →

وَكَمْ قَصَمْنَا مِن قَرْيَةٍ كَانَتْ ظَالِمَةً وَأَنشَأْنَا بَعْدَهَا قَوْمًا ءَاخَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn.

See all translations of this verse →

فَلَمَّآ أَحَسُّوا۟ بَأْسَنَآ إِذَا هُم مِّنْهَا يَرْكُضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (tó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un.

See all translations of this verse →

لَا تَرْكُضُوا۟ وَٱرْجِعُوٓا۟ إِلَىٰ مَآ أُتْرِفْتُمْ فِيهِ وَمَسَٰكِنِكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْـَٔلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ يَٰوَيْلَنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

See all translations of this verse →

فَمَا زَالَت تِّلْكَ دَعْوَىٰهُمْ حَتَّىٰ جَعَلْنَٰهُمْ حَصِيدًا خَٰمِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIgbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَا خَلَقْنَا ٱلسَّمَآءَ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَٰعِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.

See all translations of this verse →

لَوْ أَرَدْنَآ أَن نَّتَّخِذَ لَهْوًا لَّٱتَّخَذْنَٰهُ مِن لَّدُنَّآ إِن كُنَّا فَٰعِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré).

See all translations of this verse →

بَلْ نَقْذِفُ بِٱلْحَقِّ عَلَى ٱلْبَٰطِلِ فَيَدْمَغُهُۥ فَإِذَا هُوَ زَاهِقٌ وَلَكُمُ ٱلْوَيْلُ مِمَّا تَصِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fún yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́).

See all translations of this verse →

وَلَهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَنْ عِندَهُۥ لَا يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِهِۦ وَلَا يَسْتَحْسِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn tó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Kò sì rẹ̀ wọ́n.

See all translations of this verse →

يُسَبِّحُونَ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ لَا يَفْتُرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; wọn kò sì sinmi.

See all translations of this verse →

أَمِ ٱتَّخَذُوٓا۟ ءَالِهَةً مِّنَ ٱلْأَرْضِ هُمْ يُنشِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni?

See all translations of this verse →

لَوْ كَانَ فِيهِمَآ ءَالِهَةٌ إِلَّا ٱللَّهُ لَفَسَدَتَا فَسُبْحَٰنَ ٱللَّهِ رَبِّ ٱلْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

See all translations of this verse →

لَا يُسْـَٔلُ عَمَّا يَفْعَلُ وَهُمْ يُسْـَٔلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn).

See all translations of this verse →

أَمِ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً قُلْ هَاتُوا۟ بُرْهَٰنَكُمْ هَٰذَا ذِكْرُ مَن مَّعِىَ وَذِكْرُ مَن قَبْلِى بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ ٱلْحَقَّ فَهُم مُّعْرِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa.” (Al-Ƙur’ān) yìí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà pẹ̀lú mi àti ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣíwájú mi.[1] Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِىٓ إِلَيْهِ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعْبُدُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”[1]

See all translations of this verse →

وَقَالُوا۟ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحْمَٰنُ وَلَدًا سُبْحَٰنَهُۥ بَلْ عِبَادٌ مُّكْرَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ (nínú àwọn mọlāikah Rẹ̀).” Mímọ́ ni fún Un - Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.

See all translations of this verse →

لَا يَسْبِقُونَهُۥ بِٱلْقَوْلِ وَهُم بِأَمْرِهِۦ يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ ọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يَشْفَعُونَ إِلَّا لِمَنِ ٱرْتَضَىٰ وَهُم مِّنْ خَشْيَتِهِۦ مُشْفِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) mọ ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَمَن يَقُلْ مِنْهُمْ إِنِّىٓ إِلَٰهٌ مِّن دُونِهِۦ فَذَٰلِكَ نَجْزِيهِ جَهَنَّمَ كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.

See all translations of this verse →

أَوَلَمْ يَرَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَنَّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ كَانَتَا رَتْقًا فَفَتَقْنَٰهُمَا وَجَعَلْنَا مِنَ ٱلْمَآءِ كُلَّ شَىْءٍ حَىٍّ أَفَلَا يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò wòye pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?[1]

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا فِى ٱلْأَرْضِ رَوَٰسِىَ أَن تَمِيدَ بِهِمْ وَجَعَلْنَا فِيهَا فِجَاجًا سُبُلًا لَّعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَا ٱلسَّمَآءَ سَقْفًا مَّحْفُوظًا وَهُمْ عَنْ ءَايَٰتِهَا مُعْرِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَهُوَ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ كُلٌّ فِى فَلَكٍ يَسْبَحُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto tó ń tọ̀.

See all translations of this verse →

وَمَا جَعَلْنَا لِبَشَرٍ مِّن قَبْلِكَ ٱلْخُلْدَ أَفَإِي۟ن مِّتَّ فَهُمُ ٱلْخَٰلِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?[1]

See all translations of this verse →

كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ ٱلْمَوْتِ وَنَبْلُوكُم بِٱلشَّرِّ وَٱلْخَيْرِ فِتْنَةً وَإِلَيْنَا تُرْجَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fún yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

See all translations of this verse →

وَإِذَا رَءَاكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا ٱلَّذِى يَذْكُرُ ءَالِهَتَكُمْ وَهُم بِذِكْرِ ٱلرَّحْمَٰنِ هُمْ كَٰفِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: “Ṣé èyí ni ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?” Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé.

See all translations of this verse →

خُلِقَ ٱلْإِنسَٰنُ مِنْ عَجَلٍ سَأُو۟رِيكُمْ ءَايَٰتِى فَلَا تَسْتَعْجِلُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n fi ìkánjú sínú àdámọ́ ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú.

See all translations of this verse →

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

See all translations of this verse →

لَوْ يَعْلَمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ حِينَ لَا يَكُفُّونَ عَن وُجُوهِهِمُ ٱلنَّارَ وَلَا عَن ظُهُورِهِمْ وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú).

See all translations of this verse →

بَلْ تَأْتِيهِم بَغْتَةً فَتَبْهَتُهُمْ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ رَدَّهَا وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A kò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn.

See all translations of this verse →

وَلَقَدِ ٱسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِّن قَبْلِكَ فَحَاقَ بِٱلَّذِينَ سَخِرُوا۟ مِنْهُم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.

See all translations of this verse →

قُلْ مَن يَكْلَؤُكُم بِٱلَّيْلِ وَٱلنَّهَارِ مِنَ ٱلرَّحْمَٰنِ بَلْ هُمْ عَن ذِكْرِ رَبِّهِم مُّعْرِضُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?” Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa wọn.

See all translations of this verse →

أَمْ لَهُمْ ءَالِهَةٌ تَمْنَعُهُم مِّن دُونِنَا لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَ أَنفُسِهِمْ وَلَا هُم مِّنَّا يُصْحَبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

بَلْ مَتَّعْنَا هَٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمْ حَتَّىٰ طَالَ عَلَيْهِمُ ٱلْعُمُرُ أَفَلَا يَرَوْنَ أَنَّا نَأْتِى ٱلْأَرْضَ نَنقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَآ أَفَهُمُ ٱلْغَٰلِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSíbẹ̀síbẹ̀ A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni wọ́n máa borí ni?

See all translations of this verse →

قُلْ إِنَّمَآ أُنذِرُكُم بِٱلْوَحْىِ وَلَا يَسْمَعُ ٱلصُّمُّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا مَا يُنذَرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fún yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.”

See all translations of this verse →

وَلَئِن مَّسَّتْهُمْ نَفْحَةٌ مِّنْ عَذَابِ رَبِّكَ لَيَقُولُنَّ يَٰوَيْلَنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

See all translations of this verse →

وَنَضَعُ ٱلْمَوَٰزِينَ ٱلْقِسْطَ لِيَوْمِ ٱلْقِيَٰمَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْـًٔا وَإِن كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِّنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا وَكَفَىٰ بِنَا حَٰسِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ٱلْفُرْقَانَ وَضِيَآءً وَذِكْرًا لِّلْمُتَّقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).[1]

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِٱلْغَيْبِ وَهُم مِّنَ ٱلسَّاعَةِ مُشْفِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn ni) àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà.

See all translations of this verse →

وَهَٰذَا ذِكْرٌ مُّبَارَكٌ أَنزَلْنَٰهُ أَفَأَنتُمْ لَهُۥ مُنكِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni?

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَآ إِبْرَٰهِيمَ رُشْدَهُۥ مِن قَبْلُ وَكُنَّا بِهِۦ عَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.

See all translations of this verse →

إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِۦ مَا هَٰذِهِ ٱلتَّمَاثِيلُ ٱلَّتِىٓ أَنتُمْ لَهَا عَٰكِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì, tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ṣe jẹ́ ná?”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ وَجَدْنَآ ءَابَآءَنَا لَهَا عَٰبِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.”

See all translations of this verse →

قَالَ لَقَدْ كُنتُمْ أَنتُمْ وَءَابَآؤُكُمْ فِى ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ أَجِئْتَنَا بِٱلْحَقِّ أَمْ أَنتَ مِنَ ٱللَّٰعِبِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà nínú àwọn ẹlẹ́fẹ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ بَل رَّبُّكُمْ رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ٱلَّذِى فَطَرَهُنَّ وَأَنَا۠ عَلَىٰ ذَٰلِكُم مِّنَ ٱلشَّٰهِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

See all translations of this verse →

وَتَٱللَّهِ لَأَكِيدَنَّ أَصْنَٰمَكُم بَعْدَ أَن تُوَلُّوا۟ مُدْبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ.”

See all translations of this verse →

فَجَعَلَهُمْ جُذَٰذًا إِلَّا كَبِيرًا لَّهُمْ لَعَلَّهُمْ إِلَيْهِ يَرْجِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a.

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ مَن فَعَلَ هَٰذَا بِـَٔالِهَتِنَآ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ سَمِعْنَا فَتًى يَذْكُرُهُمْ يُقَالُ لَهُۥٓ إِبْرَٰهِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní ’Ibrọ̄hīm.”

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ فَأْتُوا۟ بِهِۦ عَلَىٰٓ أَعْيُنِ ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَشْهَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí.”

See all translations of this verse →

قَالُوٓا۟ ءَأَنتَ فَعَلْتَ هَٰذَا بِـَٔالِهَتِنَا يَٰٓإِبْرَٰهِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ lo ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?”

See all translations of this verse →

قَالَ بَلْ فَعَلَهُۥ كَبِيرُهُمْ هَٰذَا فَسْـَٔلُوهُمْ إِن كَانُوا۟ يَنطِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí ló ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.”[1]

See all translations of this verse →

فَرَجَعُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَنفُسِهِمْ فَقَالُوٓا۟ إِنَّكُمْ أَنتُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí.”

See all translations of this verse →

ثُمَّ نُكِسُوا۟ عَلَىٰ رُءُوسِهِمْ لَقَدْ عَلِمْتَ مَا هَٰٓؤُلَآءِ يَنطِقُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelLẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): “Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀.”

See all translations of this verse →

قَالَ أَفَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكُمْ شَيْـًٔا وَلَا يَضُرُّكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní kiní kan, tí kò sì lè kó ìnira kan bá yín lẹ́yìn Allāhu?

See all translations of this verse →

أُفٍّ لَّكُمْ وَلِمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَفَلَا تَعْقِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"

See all translations of this verse →

قَالُوا۟ حَرِّقُوهُ وَٱنصُرُوٓا۟ ءَالِهَتَكُمْ إِن كُنتُمْ فَٰعِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n wí pé: “Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe.”

See all translations of this verse →

قُلْنَا يَٰنَارُ كُونِى بَرْدًا وَسَلَٰمًا عَلَىٰٓ إِبْرَٰهِيمَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sọ pé: “Iná, di tútù àti àlàáfíà lára ’Ibrọ̄hīm.”

See all translations of this verse →

وَأَرَادُوا۟ بِهِۦ كَيْدًا فَجَعَلْنَٰهُمُ ٱلْأَخْسَرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ.

See all translations of this verse →

وَنَجَّيْنَٰهُ وَلُوطًا إِلَى ٱلْأَرْضِ ٱلَّتِى بَٰرَكْنَا فِيهَا لِلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

وَوَهَبْنَا لَهُۥٓ إِسْحَٰقَ وَيَعْقُوبَ نَافِلَةً وَكُلًّا جَعَلْنَا صَٰلِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ta á ní ọrẹ ọmọ, ’Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere.

See all translations of this verse →

وَجَعَلْنَٰهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا وَأَوْحَيْنَآ إِلَيْهِمْ فِعْلَ ٱلْخَيْرَٰتِ وَإِقَامَ ٱلصَّلَوٰةِ وَإِيتَآءَ ٱلزَّكَوٰةِ وَكَانُوا۟ لَنَا عَٰبِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa.

See all translations of this verse →

وَلُوطًا ءَاتَيْنَٰهُ حُكْمًا وَعِلْمًا وَنَجَّيْنَٰهُ مِنَ ٱلْقَرْيَةِ ٱلَّتِى كَانَت تَّعْمَلُ ٱلْخَبَٰٓئِثَ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَوْمَ سَوْءٍ فَٰسِقِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́.

See all translations of this verse →

وَأَدْخَلْنَٰهُ فِى رَحْمَتِنَآ إِنَّهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere.

See all translations of this verse →

وَنُوحًا إِذْ نَادَىٰ مِن قَبْلُ فَٱسْتَجَبْنَا لَهُۥ فَنَجَّيْنَٰهُ وَأَهْلَهُۥ مِنَ ٱلْكَرْبِ ٱلْعَظِيمِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú. A sì jẹ́pè rẹ̀. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá.

See all translations of this verse →

وَنَصَرْنَٰهُ مِنَ ٱلْقَوْمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَآ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَوْمَ سَوْءٍ فَأَغْرَقْنَٰهُمْ أَجْمَعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá.

See all translations of this verse →

وَدَاوُۥدَ وَسُلَيْمَٰنَ إِذْ يَحْكُمَانِ فِى ٱلْحَرْثِ إِذْ نَفَشَتْ فِيهِ غَنَمُ ٱلْقَوْمِ وَكُنَّا لِحُكْمِهِمْ شَٰهِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, (rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn.

See all translations of this verse →

فَفَهَّمْنَٰهَا سُلَيْمَٰنَ وَكُلًّا ءَاتَيْنَا حُكْمًا وَعِلْمًا وَسَخَّرْنَا مَعَ دَاوُۥدَ ٱلْجِبَالَ يُسَبِّحْنَ وَٱلطَّيْرَ وَكُنَّا فَٰعِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀.

See all translations of this verse →

وَعَلَّمْنَٰهُ صَنْعَةَ لَبُوسٍ لَّكُمْ لِتُحْصِنَكُم مِّنۢ بَأْسِكُمْ فَهَلْ أَنتُمْ شَٰكِرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fún yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí?

See all translations of this verse →

وَلِسُلَيْمَٰنَ ٱلرِّيحَ عَاصِفَةً تَجْرِى بِأَمْرِهِۦٓ إِلَى ٱلْأَرْضِ ٱلَّتِى بَٰرَكْنَا فِيهَا وَكُنَّا بِكُلِّ شَىْءٍ عَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

وَمِنَ ٱلشَّيَٰطِينِ مَن يَغُوصُونَ لَهُۥ وَيَعْمَلُونَ عَمَلًا دُونَ ذَٰلِكَ وَكُنَّا لَهُمْ حَٰفِظِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNínú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, àwọn tó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.

See all translations of this verse →

وَأَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُۥٓ أَنِّى مَسَّنِىَ ٱلضُّرُّ وَأَنتَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

See all translations of this verse →

فَٱسْتَجَبْنَا لَهُۥ فَكَشَفْنَا مَا بِهِۦ مِن ضُرٍّ وَءَاتَيْنَٰهُ أَهْلَهُۥ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنْ عِندِنَا وَذِكْرَىٰ لِلْعَٰبِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì jẹ́pè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).

See all translations of this verse →

وَإِسْمَٰعِيلَ وَإِدْرِيسَ وَذَا ٱلْكِفْلِ كُلٌّ مِّنَ ٱلصَّٰبِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.

See all translations of this verse →

وَأَدْخَلْنَٰهُمْ فِى رَحْمَتِنَآ إِنَّهُم مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.

See all translations of this verse →

وَذَا ٱلنُّونِ إِذ ذَّهَبَ مُغَٰضِبًا فَظَنَّ أَن لَّن نَّقْدِرَ عَلَيْهِ فَنَادَىٰ فِى ٱلظُّلُمَٰتِ أَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنتَ سُبْحَٰنَكَ إِنِّى كُنتُ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí.”[1]

See all translations of this verse →

فَٱسْتَجَبْنَا لَهُۥ وَنَجَّيْنَٰهُ مِنَ ٱلْغَمِّ وَكَذَٰلِكَ نُـۨجِى ٱلْمُؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA jẹ́pè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.

See all translations of this verse →

وَزَكَرِيَّآ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُۥ رَبِّ لَا تَذَرْنِى فَرْدًا وَأَنتَ خَيْرُ ٱلْوَٰرِثِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.”[1]

See all translations of this verse →

فَٱسْتَجَبْنَا لَهُۥ وَوَهَبْنَا لَهُۥ يَحْيَىٰ وَأَصْلَحْنَا لَهُۥ زَوْجَهُۥٓ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ يُسَٰرِعُونَ فِى ٱلْخَيْرَٰتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا وَكَانُوا۟ لَنَا خَٰشِعِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA jẹ́pè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.

See all translations of this verse →

وَٱلَّتِىٓ أَحْصَنَتْ فَرْجَهَا فَنَفَخْنَا فِيهَا مِن رُّوحِنَا وَجَعَلْنَٰهَا وَٱبْنَهَآ ءَايَةً لِّلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.[1]

See all translations of this verse →

إِنَّ هَٰذِهِۦٓ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَٰحِدَةً وَأَنَا۠ رَبُّكُمْ فَٱعْبُدُونِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.

See all translations of this verse →

وَتَقَطَّعُوٓا۟ أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ كُلٌّ إِلَيْنَا رَٰجِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn ènìyàn) sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

فَمَن يَعْمَلْ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا كُفْرَانَ لِسَعْيِهِۦ وَإِنَّا لَهُۥ كَٰتِبُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un.

See all translations of this verse →

وَحَرَٰمٌ عَلَىٰ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَٰهَآ أَنَّهُمْ لَا يَرْجِعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé).

See all translations of this verse →

حَتَّىٰٓ إِذَا فُتِحَتْ يَأْجُوجُ وَمَأْجُوجُ وَهُم مِّن كُلِّ حَدَبٍ يَنسِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya’jūj àti Ma’jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga.

See all translations of this verse →

وَٱقْتَرَبَ ٱلْوَعْدُ ٱلْحَقُّ فَإِذَا هِىَ شَٰخِصَةٌ أَبْصَٰرُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يَٰوَيْلَنَا قَدْ كُنَّا فِى غَفْلَةٍ مِّنْ هَٰذَا بَلْ كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): “Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni.”

See all translations of this verse →

إِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمْ لَهَا وَٰرِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀.

See all translations of this verse →

لَوْ كَانَ هَٰٓؤُلَآءِ ءَالِهَةً مَّا وَرَدُوهَا وَكُلٌّ فِيهَا خَٰلِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَهُمْ فِيهَا لَا يَسْمَعُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn).

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ سَبَقَتْ لَهُم مِّنَّا ٱلْحُسْنَىٰٓ أُو۟لَٰٓئِكَ عَنْهَا مُبْعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná.

See all translations of this verse →

لَا يَسْمَعُونَ حَسِيسَهَا وَهُمْ فِى مَا ٱشْتَهَتْ أَنفُسُهُمْ خَٰلِدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́.

See all translations of this verse →

لَا يَحْزُنُهُمُ ٱلْفَزَعُ ٱلْأَكْبَرُ وَتَتَلَقَّىٰهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ هَٰذَا يَوْمُكُمُ ٱلَّذِى كُنتُمْ تُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌpáyà tó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): “Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.”

See all translations of this verse →

يَوْمَ نَطْوِى ٱلسَّمَآءَ كَطَىِّ ٱلسِّجِلِّ لِلْكُتُبِ كَمَا بَدَأْنَآ أَوَّلَ خَلْقٍ نُّعِيدُهُۥ وَعْدًا عَلَيْنَآ إِنَّا كُنَّا فَٰعِلِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bíi kíká ewé tírà.[1] Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.

See all translations of this verse →

وَلَقَدْ كَتَبْنَا فِى ٱلزَّبُورِ مِنۢ بَعْدِ ٱلذِّكْرِ أَنَّ ٱلْأَرْضَ يَرِثُهَا عِبَادِىَ ٱلصَّٰلِحُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul- Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (ìyẹn ilẹ̀ Ọgbà Ìdẹ̀ra),[1] àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀.

See all translations of this verse →

إِنَّ فِى هَٰذَا لَبَلَٰغًا لِّقَوْمٍ عَٰبِدِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ohun tí ó máa tó ẹ̀dá (nípa ọ̀rọ̀ ayé àti ọ̀rọ̀ ọ̀run)[1] wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ tó ń jọ́sìn (fún Allāhu ní ọ̀nà òdodo).

See all translations of this verse →

وَمَآ أَرْسَلْنَٰكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.

See all translations of this verse →

قُلْ إِنَّمَا يُوحَىٰٓ إِلَىَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَٰحِدٌ فَهَلْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?”

See all translations of this verse →

فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَقُلْ ءَاذَنتُكُمْ عَلَىٰ سَوَآءٍ وَإِنْ أَدْرِىٓ أَقَرِيبٌ أَم بَعِيدٌ مَّا تُوعَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: “Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dìjọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà.

See all translations of this verse →

إِنَّهُۥ يَعْلَمُ ٱلْجَهْرَ مِنَ ٱلْقَوْلِ وَيَعْلَمُ مَا تَكْتُمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.

See all translations of this verse →

وَإِنْ أَدْرِى لَعَلَّهُۥ فِتْنَةٌ لَّكُمْ وَمَتَٰعٌ إِلَىٰ حِينٍ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÈmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fún yín títí di ìgbà díẹ̀.”

See all translations of this verse →

قَٰلَ رَبِّ ٱحْكُم بِٱلْحَقِّ وَرَبُّنَا ٱلرَّحْمَٰنُ ٱلْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀).”[1]

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70