Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Ar-Ra'd
Súrà Ar-Ra'd الرعد
43 verses · Medina · revelation order 96
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ الٓمٓر تِلْكَ ءَايَٰتُ ٱلْكِتَٰبِ وَٱلَّذِىٓ أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ٱلْحَقُّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael ’Alif lām mīm rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́.
See all translations of this verse →
ٱللَّهُ ٱلَّذِى رَفَعَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِى لِأَجَلٍ مُّسَمًّى يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ يُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَٰتِ لَعَلَّكُم بِلِقَآءِ رَبِّكُمْ تُوقِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan.[1] Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín.
See all translations of this verse →
وَهُوَ ٱلَّذِى مَدَّ ٱلْأَرْضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِىَ وَأَنْهَٰرًا وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ جَعَلَ فِيهَا زَوْجَيْنِ ٱثْنَيْنِ يُغْشِى ٱلَّيْلَ ٱلنَّهَارَ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi àti àwọn odò tó ń ṣàn sínú ilẹ̀. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì.[1] Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
See all translations of this verse →
وَفِى ٱلْأَرْضِ قِطَعٌ مُّتَجَٰوِرَٰتٌ وَجَنَّٰتٌ مِّنْ أَعْنَٰبٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَىٰ بِمَآءٍ وَٰحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَىٰ بَعْضٍ فِى ٱلْأُكُلِ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَٰتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọn[1] àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
See all translations of this verse →
وَإِن تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبًا أَءِنَّا لَفِى خَلْقٍ جَدِيدٍ أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ وَأُو۟لَٰٓئِكَ ٱلْأَغْلَٰلُ فِىٓ أَعْنَاقِهِمْ وَأُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلنَّارِ هُمْ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِٱلسَّيِّئَةِ قَبْلَ ٱلْحَسَنَةِ وَقَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِمُ ٱلْمَثُلَٰتُ وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِّلنَّاسِ عَلَىٰ ظُلْمِهِمْ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn ìyà (tó jẹ irú wọn) kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà.
See all translations of this verse →
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦٓ إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرٌ وَلِكُلِّ قَوْمٍ هَادٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.[1]
See all translations of this verse →
ٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنثَىٰ وَمَا تَغِيضُ ٱلْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ وَكُلُّ شَىْءٍ عِندَهُۥ بِمِقْدَارٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan ló sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀.
See all translations of this verse →
عَٰلِمُ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلْكَبِيرُ ٱلْمُتَعَالِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga jùlọ.
See all translations of this verse →
سَوَآءٌ مِّنكُم مَّنْ أَسَرَّ ٱلْقَوْلَ وَمَن جَهَرَ بِهِۦ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍۭ بِٱلَّيْلِ وَسَارِبٌۢ بِٱلنَّهَارِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán.
See all translations of this verse →
لَهُۥ مُعَقِّبَٰتٌ مِّنۢ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِۦ يَحْفَظُونَهُۥ مِنْ أَمْرِ ٱللَّهِ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا۟ مَا بِأَنفُسِهِمْ وَإِذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِقَوْمٍ سُوٓءًا فَلَا مَرَدَّ لَهُۥ وَمَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَالٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan tó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan tó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni tó lè dá a padà. Kò sì sí aláààbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.
See all translations of this verse →
هُوَ ٱلَّذِى يُرِيكُمُ ٱلْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنشِئُ ٱلسَّحَابَ ٱلثِّقَالَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òun ni Ẹni tó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fún yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò tó ṣú dẹ̀dẹ̀.
See all translations of this verse →
وَيُسَبِّحُ ٱلرَّعْدُ بِحَمْدِهِۦ وَٱلْمَلَٰٓئِكَةُ مِنْ خِيفَتِهِۦ وَيُرْسِلُ ٱلصَّوَٰعِقَ فَيُصِيبُ بِهَا مَن يَشَآءُ وَهُمْ يُجَٰدِلُونَ فِى ٱللَّهِ وَهُوَ شَدِيدُ ٱلْمِحَالِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un, àwọn mọlāika náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná láti ojú sánmọ̀ níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. (Allāhu) sì lágbára gan-an.
See all translations of this verse →
لَهُۥ دَعْوَةُ ٱلْحَقِّ وَٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُم بِشَىْءٍ إِلَّا كَبَٰسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى ٱلْمَآءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَٰلِغِهِۦ وَمَا دُعَآءُ ٱلْكَٰفِرِينَ إِلَّا فِى ضَلَٰلٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.[1]
See all translations of this verse →
وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَظِلَٰلُهُم بِٱلْغُدُوِّ وَٱلْـَٔاصَالِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.[1]
See all translations of this verse →
قُلْ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ قُلِ ٱللَّهُ قُلْ أَفَٱتَّخَذْتُم مِّن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءَ لَا يَمْلِكُونَ لِأَنفُسِهِمْ نَفْعًا وَلَا ضَرًّا قُلْ هَلْ يَسْتَوِى ٱلْأَعْمَىٰ وَٱلْبَصِيرُ أَمْ هَلْ تَسْتَوِى ٱلظُّلُمَٰتُ وَٱلنُّورُ أَمْ جَعَلُوا۟ لِلَّهِ شُرَكَآءَ خَلَقُوا۟ كَخَلْقِهِۦ فَتَشَٰبَهَ ٱلْخَلْقُ عَلَيْهِمْ قُلِ ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَىْءٍ وَهُوَ ٱلْوَٰحِدُ ٱلْقَهَّٰرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
See all translations of this verse →
أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَسَالَتْ أَوْدِيَةٌۢ بِقَدَرِهَا فَٱحْتَمَلَ ٱلسَّيْلُ زَبَدًا رَّابِيًا وَمِمَّا يُوقِدُونَ عَلَيْهِ فِى ٱلنَّارِ ٱبْتِغَآءَ حِلْيَةٍ أَوْ مَتَٰعٍ زَبَدٌ مِّثْلُهُۥ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ ٱللَّهُ ٱلْحَقَّ وَٱلْبَٰطِلَ فَأَمَّا ٱلزَّبَدُ فَيَذْهَبُ جُفَآءً وَأَمَّا مَا يَنفَعُ ٱلنَّاسَ فَيَمْكُثُ فِى ٱلْأَرْضِ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ ٱللَّهُ ٱلْأَمْثَالَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi tó ga lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àkàwé wá fún òdodo àti irọ́. Ní ti ìfòfó, ó máa lọ ní ìlọ pàǹtí. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àwọn àkàwé wá.[1]
See all translations of this verse →
لِلَّذِينَ ٱسْتَجَابُوا۟ لِرَبِّهِمُ ٱلْحُسْنَىٰ وَٱلَّذِينَ لَمْ يَسْتَجِيبُوا۟ لَهُۥ لَوْ أَنَّ لَهُم مَّا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفْتَدَوْا۟ بِهِۦٓ أُو۟لَٰٓئِكَ لَهُمْ سُوٓءُ ٱلْحِسَابِ وَمَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ وَبِئْسَ ٱلْمِهَادُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohun rere (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) wà fún àwọn tó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan tó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún.[1] Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú.
See all translations of this verse →
أَفَمَن يَعْلَمُ أَنَّمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ٱلْحَقُّ كَمَنْ هُوَ أَعْمَىٰٓ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَٰبِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ó wa dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀ bí)? Àwọn onílàákàyè ló ń lo ìrántí.
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهْدِ ٱللَّهِ وَلَا يَنقُضُونَ ٱلْمِيثَٰقَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ni) àwọn tó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ يَصِلُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوٓءَ ٱلْحِسَابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ni) àwọn tó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ صَبَرُوا۟ ٱبْتِغَآءَ وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُوا۟ مِمَّا رَزَقْنَٰهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً وَيَدْرَءُونَ بِٱلْحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ أُو۟لَٰٓئِكَ لَهُمْ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere dènà aburú.[1] Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún.
See all translations of this verse →
جَنَّٰتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا وَمَن صَلَحَ مِنْ ءَابَآئِهِمْ وَأَزْوَٰجِهِمْ وَذُرِّيَّٰتِهِمْ وَٱلْمَلَٰٓئِكَةُ يَدْخُلُونَ عَلَيْهِم مِّن كُلِّ بَابٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọ́n máa wọ̀, (àwọn) àti ẹni tó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
See all translations of this verse →
سَلَٰمٌ عَلَيْكُم بِمَا صَبَرْتُمْ فَنِعْمَ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fún yín nítorí sùúrù yín.” Àtubọ̀tán Ilé rere náà sì dára.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهْدَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعْدِ مِيثَٰقِهِۦ وَيَقْطَعُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِى ٱلْأَرْضِ أُو۟لَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوٓءُ ٱلدَّارِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn.
See all translations of this verse →
ٱللَّهُ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقْدِرُ وَفَرِحُوا۟ بِٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ إِلَّا مَتَٰعٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín.
See all translations of this verse →
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ قُلْ إِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِىٓ إِلَيْهِ مَنْ أَنَابَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀.”
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ ٱللَّهِ أَلَا بِذِكْرِ ٱللَّهِ تَطْمَئِنُّ ٱلْقُلُوبُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀.[1]
See all translations of this verse →
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ طُوبَىٰ لَهُمْ وَحُسْنُ مَـَٔابٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn.
See all translations of this verse →
كَذَٰلِكَ أَرْسَلْنَٰكَ فِىٓ أُمَّةٍ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهَآ أُمَمٌ لِّتَتْلُوَا۟ عَلَيْهِمُ ٱلَّذِىٓ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ وَهُمْ يَكْفُرُونَ بِٱلرَّحْمَٰنِ قُلْ هُوَ رَبِّى لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ مَتَابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, - àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn -, nítorí kí o lè máa ka n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí fún wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
See all translations of this verse →
وَلَوْ أَنَّ قُرْءَانًا سُيِّرَتْ بِهِ ٱلْجِبَالُ أَوْ قُطِّعَتْ بِهِ ٱلْأَرْضُ أَوْ كُلِّمَ بِهِ ٱلْمَوْتَىٰ بَل لِّلَّهِ ٱلْأَمْرُ جَمِيعًا أَفَلَمْ يَا۟يْـَٔسِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَن لَّوْ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَهَدَى ٱلنَّاسَ جَمِيعًا وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ تُصِيبُهُم بِمَا صَنَعُوا۟ قَارِعَةٌ أَوْ تَحُلُّ قَرِيبًا مِّن دَارِهِمْ حَتَّىٰ يَأْتِىَ وَعْدُ ٱللَّهِ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخْلِفُ ٱلْمِيعَادَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n ké e láti fi mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn), tàbí wọ́n fi gé ilẹ̀ (kélekèle, kí ó yanu fún àwọn àlùmọ́nì), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (kí wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn tó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn.
See all translations of this verse →
وَلَقَدِ ٱسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِّن قَبْلِكَ فَأَمْلَيْتُ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
See all translations of this verse →
أَفَمَنْ هُوَ قَآئِمٌ عَلَىٰ كُلِّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ وَجَعَلُوا۟ لِلَّهِ شُرَكَآءَ قُلْ سَمُّوهُمْ أَمْ تُنَبِّـُٔونَهُۥ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِى ٱلْأَرْضِ أَم بِظَٰهِرٍ مِّنَ ٱلْقَوْلِ بَلْ زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مَكْرُهُمْ وَصُدُّوا۟ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنْ هَادٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) wọ́n tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ fẹ́ mú) irọ́ àti àbá dídá wá? Rárá, wọ́n ti ṣe ète àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un.
See all translations of this verse →
لَّهُمْ عَذَابٌ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَشَقُّ وَمَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.
See all translations of this verse →
مَّثَلُ ٱلْجَنَّةِ ٱلَّتِى وُعِدَ ٱلْمُتَّقُونَ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ أُكُلُهَا دَآئِمٌ وَظِلُّهَا تِلْكَ عُقْبَى ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوا۟ وَّعُقْبَى ٱلْكَٰفِرِينَ ٱلنَّارُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ ءَاتَيْنَٰهُمُ ٱلْكِتَٰبَ يَفْرَحُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ وَمِنَ ٱلْأَحْزَابِ مَن يُنكِرُ بَعْضَهُۥ قُلْ إِنَّمَآ أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ ٱللَّهَ وَلَآ أُشْرِكَ بِهِۦٓ إِلَيْهِ أَدْعُوا۟ وَإِلَيْهِ مَـَٔابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ tó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
See all translations of this verse →
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَٰهُ حُكْمًا عَرَبِيًّا وَلَئِنِ ٱتَّبَعْتَ أَهْوَآءَهُم بَعْدَ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلْعِلْمِ مَا لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن وَلِىٍّ وَلَا وَاقٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
See all translations of this verse →
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ وَجَعَلْنَا لَهُمْ أَزْوَٰجًا وَذُرِّيَّةً وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِىَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ لِكُلِّ أَجَلٍ كِتَابٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.[1] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.² Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ló ní àkọsílẹ̀.
See all translations of this verse →
يَمْحُوا۟ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ وَيُثْبِتُ وَعِندَهُۥٓ أُمُّ ٱلْكِتَٰبِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà.[1]
See all translations of this verse →
وَإِن مَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ ٱلَّذِى نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِنَّمَا عَلَيْكَ ٱلْبَلَٰغُ وَعَلَيْنَا ٱلْحِسَابُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa.
See all translations of this verse →
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا نَأْتِى ٱلْأَرْضَ نَنقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَا وَٱللَّهُ يَحْكُمُ لَا مُعَقِّبَ لِحُكْمِهِۦ وَهُوَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú À ń dé sórí ilẹ̀, À ń dín in kù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn eteetí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
See all translations of this verse →
وَقَدْ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَلِلَّهِ ٱلْمَكْرُ جَمِيعًا يَعْلَمُ مَا تَكْسِبُ كُلُّ نَفْسٍ وَسَيَعْلَمُ ٱلْكُفَّٰرُ لِمَنْ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Dájúdájú àwọn tó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá.[1] Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún.
See all translations of this verse →
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَسْتَ مُرْسَلًا قُلْ كَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًۢا بَيْنِى وَبَيْنَكُمْ وَمَنْ عِندَهُۥ عِلْمُ ٱلْكِتَٰبِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ (wọ́n tó ní ẹlẹ́rìí ) .[1]”
See all translations of this verse →
← Súrà Yusuf
Súrà Ibrahim →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.