وَإِن تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبًا أَءِنَّا لَفِى خَلْقٍ جَدِيدٍ أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ وَأُو۟لَٰٓئِكَ ٱلْأَغْلَٰلُ فِىٓ أَعْنَاقِهِمْ وَأُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلنَّارِ هُمْ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.