لَهُۥ دَعْوَةُ ٱلْحَقِّ وَٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُم بِشَىْءٍ إِلَّا كَبَٰسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى ٱلْمَآءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَٰلِغِهِۦ وَمَا دُعَآءُ ٱلْكَٰفِرِينَ إِلَّا فِى ضَلَٰلٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.[1]