caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ar-Ra'd, ẹsẹ 31

Medina · revelation order 96 · 13:31

وَلَوْ أَنَّ قُرْءَانًا سُيِّرَتْ بِهِ ٱلْجِبَالُ أَوْ قُطِّعَتْ بِهِ ٱلْأَرْضُ أَوْ كُلِّمَ بِهِ ٱلْمَوْتَىٰ بَل لِّلَّهِ ٱلْأَمْرُ جَمِيعًا أَفَلَمْ يَا۟يْـَٔسِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَن لَّوْ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَهَدَى ٱلنَّاسَ جَمِيعًا وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ تُصِيبُهُم بِمَا صَنَعُوا۟ قَارِعَةٌ أَوْ تَحُلُّ قَرِيبًا مِّن دَارِهِمْ حَتَّىٰ يَأْتِىَ وَعْدُ ٱللَّهِ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخْلِفُ ٱلْمِيعَادَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n ké e láti fi mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn), tàbí wọ́n fi gé ilẹ̀ (kélekèle, kí ó yanu fún àwọn àlùmọ́nì), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (kí wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn tó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70