caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Aadiyaat العاديات

11 verses · Mecca · revelation order 14

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلْعَٰدِيَٰتِ ضَبْحًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْمُورِيَٰتِ قَدْحًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.

See all translations of this verse →

فَٱلْمُغِيرَٰتِ صُبْحًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.

See all translations of this verse →

فَأَثَرْنَ بِهِۦ نَقْعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.

See all translations of this verse →

فَوَسَطْنَ بِهِۦ جَمْعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

See all translations of this verse →

وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلْخَيْرِ لَشَدِيدٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.

See all translations of this verse →

أَفَلَا يَعْلَمُ إِذَا بُعْثِرَ مَا فِى ٱلْقُبُورِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),

See all translations of this verse →

وَحُصِّلَ مَا فِى ٱلصُّدُورِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeltí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,

See all translations of this verse →

إِنَّ رَبَّهُم بِهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّخَبِيرٌۢ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaeldájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70