caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Az-Zalzala الزلزلة

8 verses · Medina · revelation order 93

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا زُلْزِلَتِ ٱلْأَرْضُ زِلْزَالَهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,

See all translations of this verse →

وَأَخْرَجَتِ ٱلْأَرْضُ أَثْقَالَهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù tó wúwo nínú rẹ̀ jáde,

See all translations of this verse →

وَقَالَ ٱلْإِنسَٰنُ مَا لَهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelènìyàn yó sì wí pé: “Kí l’ó mú un?”

See all translations of this verse →

يَوْمَئِذٍ تُحَدِّثُ أَخْبَارَهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).

See all translations of this verse →

بِأَنَّ رَبَّكَ أَوْحَىٰ لَهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).

See all translations of this verse →

يَوْمَئِذٍ يَصْدُرُ ٱلنَّاسُ أَشْتَاتًا لِّيُرَوْا۟ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.

See all translations of this verse →

فَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُۥ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.

See all translations of this verse →

وَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُۥ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.[1]

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70